Ọọ̀ni Okunade Sijuwade tó wàjà lọ́dún mẹ́wàá kò kú, ó wà láàrín wa - Ọba Ogunwusi

Àkọlé fídíò, Ọọ̀ni Okunade Sijuwade tó wàjà lọ́dún mẹ́wàá kò kú, ó wà láàrín wa - Ọba Ogunwusi
Ọọ̀ni Okunade Sijuwade tó wàjà lọ́dún mẹ́wàá kò kú, ó wà láàrín wa - Ọba Ogunwusi

Laipẹ yii ni ilu Eko mi titi fun ayẹyẹ iranti ọdun kẹwa ti Ọba Okunade Adele Sijuwade, Ọọni Olubuse Keji waja.

Awọn ọmọ, ẹbi ara, àwọn lookọ lookọ yika Naijiria, oloselu, oriade ati awọn akọroyin ninu eyi ti BBC News Yoruba wa si lo peju sibi ayẹyẹ iranti naa.

Lara wọn la ti ri Ọọni Enitan Adeyeye Ogunwusi, Ọjaja Kinni, Senator Gbenga Daniel ati Ọgbẹni Ọja ti Ijẹbu Ode, Dokita Sunny Folorunso Kuku.

Nibi ayẹyẹ naa si ni ọpọ awọn eeyanlu lawujọ, to ba BBC News Yoruba sọrọ, ti kọrin re ki ọba to gbesẹ ni ọdun mẹwa sẹyin naa.

Ọba Okunade Sijuwade Olubuse keji

Oríṣun àwòrán, Oodua Palace

Mo ṣeba Ọba Okunade Sijuade, isẹ ọwọ rẹ naa la n ri yii - Ọọni Ogunwusi

Nigba to n sọrọ nibi ayẹyẹ iranti ọdun kẹwa naa, Ọọni Adeyeye Ogunwusi Ọjaja Kinni salaye pe Ọba Okunade Sijuade ko ku rara tori o si wa ni aarin wa.

"Ọba Sijuwade ko ku, wọn si wa ni aarin wa tori Ọọni kii ku., titi laelae ni Ọọni maa wa.

Mo dupẹ lọwọ Ọlọrun Olodumare fun ọdun mẹwa to da bi ana yii.

Mo kọkọ fẹ se iba wọn nitori isẹ ọwọ wọn ti wọn se naa la n ri yii."

Ọọni Adeyeye Ogunwusi wọ asọ funfun, de ade sori, o si fi ilẹkẹ sọrun, awọn ọmọ ọba Ọọni Okunade Sijuwade duro tii, awọn naa wọ asọ funfun, wọn de fila olomi buluu sori.
Àkọlé àwòrán, Ọọni Adeyeye Ogunwusi ati awọn ọmọ ọba Ọọni Okunade Sijuwade duro tii.

Ẹni ti ko ba mọ Ọba Sijuwade amọ to gbọ nipa rẹ, oye yoo wu onitọun jẹ - Sunny Kuku

Nigba ti oun naa n sọrọ, Ọgbẹni Ọja ti Ijẹbu, Oloye Sunny Folorunso Kuku sọ pe ẹni ti ko ba mọ Ọba Sijuwade amọ to gbọ nipa rẹ, oye yoo wu onitọun jẹ.

"Ọba Okuade Sijuwade ni ọyaya, o lawọ, to ba si jẹ ọrẹ eeyan, ko si ohun ti ko ni fẹ mọ nipa onitọhun."

Jacob Oluponna tii se Ọjọgbọn nipa imọ ẹsin nilẹ Afirika naa sọ pe Ọba Okunade Sijuwade ba ọla nile ni, to si fi han gbogbo eeyan pe iyi wa ninu ki eeyan jẹ ọba.

Senatọ Gbenga Daniel ni tiẹ ni nigba aye Ọba Okunade Sijuwade, ilu n lọ siwaju ni.

"Gbogbo ohun to si n fa wahala lasiko naa lo kasẹ nilẹ.

Lẹyin ọdun kẹwa to ti papoda, awọn isẹ ti Kabiyesi naa fi lelẹ si duro sinsin."

Bakan naa ni Ọjọgbọn Ọladapọ Afolabi tii se Olori osisẹ ọba tẹlẹ nilẹ Naijiria sọ pe Ọba Sijuade jẹ baba daadaa si oun.

"Baba funra wọn lo jẹ ki n mọ a gbọdọ mu ọrọ Yoruba ni ọdunkundun lati ri pe Yoruba ko gbẹyin"

Ọọni Okunade Sijuade

Oríṣun àwòrán, Oodua Palace

Itan igbesi aye Ọọni Okunade Sijuwade, Olubuse keji

Alayeluwa Ọba Okunade Adele Sijuwade ni wọn bi ni ọjọ kinni osu kinni ọdun 1930.

Oun si ni Ọọnirisa aadọta tilu Ile Ife, to si jọba laarin ọdun ọjọ kẹfa osu kejila ọdun 1980 si 2015, tii se ọdun mẹẹdọgbọn gbako.

Oba Okunade Sijuwade wa lati idile Ọba Ogboru, Ilare nilu Ile Ife, ọba naa ni baba to bi baba rẹ, oun si ni Ooni Adelekan Sijuwade - Olubuse kiini.

oun si ni Ooni Ile Ife kẹrindinlaadọta to jọba laarin ọdun 1884 si 1910.

Orukọ baba to bi Sijuwade Ọmọọba Adereti Sijuade, ti iya rẹ si n jẹ Yeye olori Emilia Ifasesin Sijuwade (ọmọ idile Osukoti Adugbolu) lati iluAkure.

Niwọn igba ti wọn tii ki wo ọmọ oye ni aafin, Ọba Okunade Sijuwade bẹrẹ ile ẹkọ alakọbẹrẹ rẹ ni Igbeyin nilu Abeokuta.

Bakan naa, o ka ile ẹkọ girama rẹ ni Abeokuta Grammar School nigba ti Baba Fela Kuti, eyiun Ẹni ọwọ I O Ransome-Kuti jẹ ọga agba ile ẹkọ naa.

Oba Okunade Sijuwade tun lọ sile ẹkọ girama Oduduwa College ni Ile-Ife, ko to lọ silu Ọba lati kẹkọ nipa okoowo nile ẹkọ Northampton Technical College.

Ọọni Olubuse keji ku ni ọjọ kejidinlọgbọn osu keje ọdun 2015 nile iwosan kan nilu London.

Ẹni ọdun marundinlaadọrun ni nigba to dagbere faye.