Baba Mohbad sọ̀rọ̀ lórí fídíò tí Naira Marley ṣe nípa ikú ọmọ rẹ̀, ó sọ ìgbésẹ̀ tó kàn

Baba Mohbad àti Naira Marley duro papọ, baba Mohbad wọ aṣọ aláwọ̀ búlúù nigbati Naira Marley wọ aṣọ dúdú, tó sì di irun rẹ.

Oríṣun àwòrán, Collage

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 8

Gbajúmọ̀ akọrin takasufe nni, Azeez Fashola, tí ọ̀pọ̀ èèyàn mọ̀ sí Naira Marley, ti ṣàlàyé pé àpò àsùnwọ̀n owó ni banki, tó jẹ́ ní ìyá ìyàwó Mohbad, ní olóògbé náà fi ń kọkọ gba owó isẹ rẹ lọwọ òun.

Naira Marley tun sísọ lójú ọrọ yii nínú fídíò kan tó ṣe sórí ayélujára èyí tó fi ń wẹ ara rẹ mọ nípa ikú Ilerioluwa Aloba, tí ọ̀pọ̀ èèyàn mọ̀ sí Mohbad, tó di olóògbé lọ́dún méjì sẹ́yìn.

Naira Marley ni "Mohbad sọ fún mi pé òun ni òun ni àpò àsùnwọ̀n owó náà àmọ́ àṣírí tú nígbà tó yá pé akanti náà kii ṣe tí Mohbad.

A ṣàwárí rẹ pé ìyá Wunmi, tii ṣe ìyàwó Mohbad lo ni akanti tí a ń sanwó si náà, mo sì yari pé ń ko ni sanwó sìnu àpò àsùnwọ̀n owó náà mọ."

Naira Marley tẹsiwaju pe oun sọ fún Mohbad pe ko lọ sí akanti tiẹ̀ nílé ifowopamọ, inú rẹ sì ni òun yóò máa san owó orin tó bá kọ lábẹ́ ileeṣẹ òun sì.

Baba Mohbad fèsì fún BBC News Yorùbá lórí fídíò tí Naira Marley ṣe

Ní báyìí, Joseph Aloba, ẹni ti ọpọ eeyan mọ si Baba Mohbad, ti sọrọ sita lori fídíò tí Naira Marley gbe síta, lati ti wẹ ara mọ lori iku Mohbad.

Baba Mohbad, lásìkò tó ń bá BBC News Yorùbá sọrọ, ní Naira Marley ti ṣàlàyé fún òun ṣáájú lori apo asunwọn owó ni banki, ti Mohbad fi n gba owo to ajẹmọnu rẹ náà.

O tẹsiwaju pe ọpọ ohun ti Naira Marley sọ sita lo jẹ pe oun ti sọ sita ṣaaju lasiko ti Mohbad di oloogbe lọdun 2023.

Aworan gbajugbaja olorin takasufe, Azeez Fashola ti ọpọ mọ si Naira Marley ati Baba Mohbad, Joseph Aloba

Oríṣun àwòrán, Naira Marley/BBC

"Gbigba owó Mohbad lọ́wọ́ Naira Marley kọ ló jẹ́ mi lógún, irú ikú tó pa ọmọ mi ni mo fẹ́ mọ"

Joseph Aloba nigba to n sọrọ lori owo Mohbad ti Naira Marley ni oun setan lati fun awọn mọlẹbi, o ni eyi ko ki n ṣe ohun to jẹ oun logun lasiko yii

O ni owo gbigba kọ lo wa ni ọkan oun bayii nitori oun si duro lori pe oun fẹ mọ ohun to ṣekupa ọmọ oun.

"Owo kọ lo kan bayii, abala ikeji niyẹn, ohun to pa Mohbad lo ba mi.

Eyi ni mo n beere lọwọ gbogbo èèyàn.

"O san ki máa n ṣe iṣẹ mi lọ, ju ki n lọ gba owo lasiko yii.

Ki se ọrọ owo lo ba mi nitori owo ma tan."

"O di igba ti mo ba mọ ohun to pa ọmọ yii ati boya ni loootọ ni pe ọmọ to fi silẹ jẹ temi ni a to le sọrọ owo."

Baba Mohbad ni idi ti oun fi ke si Aarẹ Bola Tinubu pe ki wọn gba oun nìyí, nitori ko si idajọ ododo mọ lorilẹede Naijiria.

Baba Mohbad sọrọ lori ohun ti Naira Marley sọ nipa ki wọn mu awọn eeyan to wa pẹlu Mohbad ni wakati mejidinlaadọta si ikú rẹ̀

Baba Mohbad tún fèsì lórí àbá tí Naira Marley dá pé kí wọ́n kó àwọn èèyàn tó wà pẹ̀lú Mohbad ni aarin wákàtí mejidinlaadọta sí ikú rẹ̀.

Aloba ni o le fun oun lati gbe igbesẹ yii nitori ọpọ nnkan si sokunkun si oun lasiko ti Mohbad jade laye.

"Ki n to de si ile iwosan ti wọn gbe oku Mohbad si, wọn ti tún gbe oku rẹ si ile igbokusi.

Bawo ni wọn yoo ṣe gbé oku wọle si ile igbokusi laarin wakati meji to jade laye.

"Awọn ọlọpaa ko ṣe nnkan si, ki ni mo wa fẹ se?

Nnkan ti emi n sọ ni pe, nnkan to kan oun bayii ni pe ki lo pa Mohbad, awọn wo lo wa ninu ile pẹlu?

"A ko le fi owo ṣáájú, ti a ko ba dahun ibeere ki lo pa Mohbad.

Ko si nnkan to kan mi bayii pẹlu owo"

Aloba wa rawọ ẹbẹ si ẹnikẹni to ba le ran òun lọwọ láti ṣe awari ikú Mohbad torí idile òun ati awọn ọmọ Naijiria si n duro de iwadii ileeṣẹ ọlọpaa lati mọ ohun pato to ṣekupa Mohbad.

Naira Marley àti Mohbad

Oríṣun àwòrán, Collage

Gbẹgẹdẹ gbiná! Naira Marley lahùn lórí ikú Mohbad, ọ̀pọ̀ àṣírí tú

Gbajumọ akọrin takasufe, Naira Marley, ti ke si awọn èèyàn to wa nidi iwadii iku gbajumọ akọrin takasufe nni, Ilerioluwa Aloba, ti ọpọ eeyan n pe ni Mohbad, pe ki wọn gbé Igbesẹ ọtun lori iwadii wọn.

Naira Marley ní gbogbo awọn eniyan to sun mọ Mohbad, to jade laye ni ọdun meji sẹyin, ṣugbọn ti ọrọ iku rẹ ṣi n ja ranyinranyin lẹyin to kú, ní ki wọn pada lọ ko.

Naira Marley kéde ọrọ naa ninu fidio kan to fi sita lori ohun to pe ni alaye tirẹ lori ajọṣepọ to wa laarin oun ati Mohbad nigba aye rẹ.

Naira Marley ni bi wọn ba fi da toun o, nṣe ni ki awọn ọlọpaa tun gbogbo awọn eeyan to wa layika oloogbe naa ko si atimọle, ki wọn tun ìwádìí iku rẹ bẹrẹ pada, ki wọn si fi ọlọpaa to ṣe e fi ọkan tan si akoso iwadii naa.

Aworan Naira Marley.

Oríṣun àwòrán, instagram/naira marley

Naira Marley fi awọn itakurọsọ loju opo WhatsApp rẹ han nípa bi oun ati Mohbad ṣe n sọrọ bi ọmọ iya

Naira Marley ṣe alaye ajọṣepọ to dan mọran to wa laarin oun ati Mohbad nigba aye rẹ.

O fi awọn itakurọsọ wọn lori oju opo WhatsApp han bi oun ati oloogbe akọrin takasufe naa ṣe n sọrọ bi ọmọ iya kan naa loju opo ọhun.

Bi ẹ ko ba gbagbe, ni ọjọ kejila oṣu kẹsan an ọdun 2023, ni iku mu gbajumọ akọrin naa lọ.

Okiki iku rẹ ko ti lọ nilẹ pẹlu bi oniruuru awuyewuye ṣe gbode nipa ohun to ṣe okunfa iku rẹ.

Naira Marley, to jẹ oludasilẹ ileeṣẹ orin to n gbe awo orin Mohbad jade nigba aye rẹ, wa lara awọn afurasi ti ọpọ eeyan n na ika si pe wọn lọwọ ninu iku rẹ, eleyi to mu ki o lo saa diẹ ni ahamọ ôlọpaa ki ile ẹjọ to daa silẹ.

Naira Marley ninu fidio to fi sita.

Oríṣun àwòrán, screenshot/instagram/naira marley

Bi mo ṣe mọ pe Mohbad n lo ogun kan ti wọn n pe ni ICE – Naira MArley

Ninu fidio to fi sita naa, Naira Marley se atupalẹ bi o ṣe kọkọ mọ pe Mohbad ti n lo awọn egboogi oloro kan nigba aye rẹ, ti wọn pe ni ICE.

O ni nigba ti oun gbọ, oun pe e nija pe ko ṣọra pupọ, o si tuuba pe oun ko ni lo egboogi naa mọ.

O ni oun ko mọ oun ti egboogi naa jẹ nigba naa, ki oun to gbọ pe Mohbad n lo ogun oloro naa.

O fi kun un pé, lẹyin ti oun ṣe ìwádìí, ni oun to wa rii pe egboogi oloro ni.

"Mo mọ ohun ti egboogi yii n ṣe si awon eeyan nigboro, paapaa nigba ti mo wa lorilẹede UK.

"Amọ ṣa mi o binu, nitori pe mo mọ pe mo le fun un ni amọran ni ṣugbọn o ku si ọwọ oun funrarẹ lati mu amọran naa lo"

Marley ni Mohbad sọ fun oun nigba naa pe nitori wahala iṣẹ loun fi n lo egboogi oloro naa, ati pe awọn ọrẹ oun kan lo fa oun sii.

Naira Marley

Oríṣun àwòrán, Instagram/naira marley

Ohun to fa ti Mohbad fi pariwo pe " Marlian Music ni ki ẹ mu bi mo ba ku"

Ninu fidio to fi sita naa, Naira Marley salaye pe lara awọn ẹ̀sùn ti awọn eeyan n lọ mọ oun lẹsẹ nipa iku ati igbe aye Mohbad, lo da lori fidio kan to fi sita ninu eyi to ti n pariwo pe "bi mo ba ku, ileeṣe orin Marlian Music ati Naira Marley lo ṣekú pa mi".

Naira Marley ni ohun to ṣẹlẹ ni pe awọn oṣiṣẹ ajọ NDLEA lo wa ko awọn kan ni ile oun, lara wọn si ni Zinoleesky ati eeyan kan to n jẹ Subomi wa.

O ni orilẹede Sweden loun wa nigba ti iṣẹlẹ naa ṣẹlẹ ati pe bi Mohbad ṣe bá awọn agbofinro naa ja lo ṣokunfa bi wọn ṣe ko o pọ mọ wọn.

"Mohbad bọ sori ayelukara Instagram ni kete ti wọn fi wọn silẹ lasiko náà, lo si n pariwo pe, "'bi mo ba ku, gbogbo eeyan, Marlian Music, Naira Marley lo pa mi".

O ni lẹyìn ọpọ ọrọ, awọn obi Mohbad ati iyawo rẹ wa bẹ oun, oun si gb'ẹbẹ wọn nigba naa

'Mohbad fi igba kan gbìyànjú lati gb'ẹmi ara rẹ'

Bakan naa ni Naira Marley tun ṣalaye ninu fidio naa pe, Oloogbe Mohbad fi igbakan gbiyanju lati seku pa ara rẹ ni ọjọ kẹtadinl'ọgbọn oṣù kẹta ọdun 2022 nigba ti oun wa lorileede Peurto Rico.

O ni oun ba a sọrọ lori majele to kede lori ayelujara pe oun fẹ ra nigba naa.

Naira Marley ni oun tun ba awọn obi rẹ sọrọ, ti wọn si pinnu pe ki wọn kuku gbe e kuro nibẹ.

Naira Marley

Oríṣun àwòrán, Naira Marley

"Gbogbo owo to tọ si Mohbad nigba aye rẹ lori awo orin to ṣe pẹlu ileese orin Marlian Music wa ni ipamọ, awọn ẹbi ati agbẹjọro rẹ le gba a nigba to wu wọn"

Gẹgẹ bi alaye to ṣe ninu fidio naa, Naira Marley salaye pe, ilu Amsterdam lórílẹ̀ede Holland ni oun wa lọjọ ti akọrin naa jade laye.

O ni ireti oun bayii ni pe ki ileeṣẹ ọlọpaa ko gbogbo awọn eeyan to wa pẹlu Mohbad ni wakati mejidinlaadọta si mẹrinlelogun si asiko iku rẹ.

"Mi o fi igba kankan ran ẹnikẹni sii lati lọ dunkooko mọ Mohbad."

O fi kun un pe, gbogbo owo to tọ si Mohbad nigba aye rẹ lori awo orin rẹ to ṣe pẹlu ileese orin Marlian Music wa ni ipamọ, ti awọn ẹbi ati agbẹjọro rẹ si le wa gba a nigbakugba to ba wu wọn.