Adigunjalè kọlu Lil Kesh, akọrin takasúfèé, wọ́n gún un lọ́bẹ lọ́rùn, gba ẹ̀ṣọ́ ara olówó iyebíye lọ́wọ́ rẹ̀

Oríṣun àwòrán, Lilkesh/Instagram
Akọrin takasufe, Kenshinro Ololade, ẹni ti ọpọ mọ si Lil Kesh ni ori ti ko yọ lọwọ ikọlu awọn adigunjale nipinlẹ Eko.
Ohun to tẹ wa lọwọ fidi rẹ mulẹ pe awọn adigunjale yii gun Lil Kesh lọbẹ lọrun lasiko ikọlu naa.
Bakan naa ni awon adigunjale yii tun ji ọpọ ẹsọ ara to wa lọrun olorin naa.
Iṣẹlẹ yii waye lọjọru, Ogunjọ oṣu kẹjọ ọdun 2025 nipinlẹ Eko.
Kete ti iṣẹlẹ naa waye ni wọn gbe Lil Kesh lọ si ile iwosan, awon dokita ti ran oju ọgbẹ ọrun rẹ
Kete ti iṣẹlẹ naa waye ni wọn sare gbe Lil Kesh lọ si ile iwosan, ti awon dokita si ti ran apa ibi ti wọn ti fi ọbẹ gun ni ọrun rẹ.
Idi ti ikọlu yii waye ni ko to ti han si ẹnikẹni bayii.
Lil Kesh ati ileeṣẹ orin rẹ ko sọ ohunkohun nipa iṣẹlẹ naa.
Ọpọ aworan Lil Kesh bo ṣe farapa lo ti wa lori ayelujara
Ẹni ọdun mẹrindinlọgbọn, ti o di olokiki pẹlu orin rẹ 'Shoki' ni ọpọ awọn ololufẹ rẹ ti bọ sori ayelujara lati gba adura fun lori iṣẹlẹ naa.
Eyi ko yọ awọn akẹgbẹ rẹ silẹ, ti awọn naa si ti bẹrẹ lati ma kan si olorin takasufe naa lati bere alaafia rẹ.
Ki ni Ileeṣẹ ọlọpaa sọ
BBC kan si agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Eko, Benjamin Hundeyin lori iṣẹlẹ,
O ni Ileeṣẹ ọlọpaa ti gbọ si iṣẹlẹ naa, ti iwadii si ti bẹrẹ lati ṣawari awọn adigunjale ọhun.
Hundeyin wa fi da awọn araalu loju pe ileeṣẹ ọlọpaa yoo fi atẹjade sita laipẹ lori ikọlu to waye si Lil Kesh lati ọwọ awọn adigunjale.
Ta ni Lil Kesh?
Keshinro Ololade ni wọn bi ọjọ keje oṣu kẹta ọdun 1999.
O jẹ olorin to di ilumọka lẹyin to gbe orin 'Shoki' sita lọdun 2014.
Agbegbe Bariga ni wọn ti bi Lil Kesh nipinlẹ Eko. O lọ si ile ẹkọ Stockbridge College fun ẹkọ alakọbẹrẹ ati girama, ko to morile Fasiti Eko.
O kẹkọ gboye ninu Linguistics, ko to tun ka iwe si ni Mass Communications ni National Open University.
Ọdun 2012 ni Lil Kesh bẹrẹ orin kikọ, to si kọ ọpọ orin pẹlu awọn ilumọka mii bi Davido, Olamide ati Burna Boy.
Ọpọ ami ẹyẹ ni Lil Kesh ti gba pẹlu awọn orin rẹ.















