Mọ̀ síi nípa ọdún Udiroko, àjọ̀dún tó ń sàmì ọdún tuntun nílùú Ado Ekiti?

Arabinrin kan n gbe ilu iṣẹmbaye kan fun kabiyesi Ewi ti ilu Ado Ekiti
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Ayẹyẹ Ọdun Udiroko jẹ ọdun pataki ti gbogbo awọn Ọmọ bibi ilu Ado-Ekiti maa n ṣe ni Ọdọọdun ti o si tun jẹ ayajọ ti wọn ṣe iṣẹdalẹ ilu naa.

Ọjọ meji ni Ewi ti ilu Ado-Ekiti maa n lo lati jade si gbogbo ilu lasiko ọdun.

Ọdun Udiroko jẹ ọdun pataki ti Ado maa n ṣe ni ọdọọdun,

Ọdun Itado ati Udiroko. Akoko ni 'itado' ti Olori gbogbo Ọlọpaa Ado yio jo wọ aafin Ewi Ado-Ekiti pẹlu awọn ẹmẹwa rẹ pẹlu ẹgba lọwọ lati fi naa Ọba ni ẹsẹ ti Kabiyesi naa yio si ma gbiyanju lati majẹ ki ẹgba naa ba ohun sugbọn ti yio pada jọwọ ara rẹ fun wọn lati naa tori Ado ni igbagbo pe ohun ti wọn fi le naa ẹni akọkọ loju gbogbo ilu, ko si ẹni ti o kọja ibawi.

Ọpọ ero nibi ayẹyẹ ajọdun Udiroko nilu Ado Ekiti

Lọjọ ti wọn ba ti ṣe ọdun itado ni wọn ma n mọ ọjọ ti wọn ma ṣe ayẹyẹ Ọdun Udiroko tori ise ọkan lara awọn oloye laafin Ologunsunja ni lati maa fi obi gbadura fun ilu ni gbogbo ọjọ marun-un marun-un titi yoo fi pe ọdun, lo fi je pe ayẹyẹ Ọdun Udiroko ko ni osu kan tabi ọjọ kan ti wọn ma nṣe ni ọdọọdun. Bi oju ọjọ ba seri ni wọn ṣe maa n kaa.

Nigbati Ọba Alayeluwa Rufus Adeyemo Adejugbe Aladesanmi kẹta(111) Ewi ti ilu Ado-Ekiti ba akọroyin BBC News Yoruba sọrọ ni aafin rẹ sọ nipa pataki ayẹyẹ Ọdun Udiroko.

Ọba Alayeluwa Rufus Adeyemo Adejugbe Aladesanmi kẹta(111) Ewi ti ilu Ado-Ekiti tesiwaju lori bi wọn se ma ṣe afihan awọn ade isenbaye pẹlu orisirisi ohun ti wọn ko wo ilu Ado fun awọn ọmọ ilu lati ri ni gbogbo ọdun ayẹyẹ Udiroko ni ọdọọdun.

Kabiyesi Ewi ilu Ado Ekiti laarin ọpọ ero n ki awọn ọmọ ilu Ado lasiko ọdun Udiroko.
Àkọlé àwòrán, Lasiko ọdun naa ni Kabiyesi, Ewi ilu Ado Ekiti ti maa n sure fun gbogbo ọmọ bibi ilu Ado Ekiti.

Ọpọlọpọ eniyan ni wọn fẹ ma wa wo iran awọn orisirisi ohun isenbaye ti wọn ma n ṣe afihan rẹ nibi ayẹyẹ Ọdun Udiroko ni ọdọọdun ti o si tu je ọjọ ti Kabiyesi ma fẹ iyawo pupọ wo aafin lati jọ nitori awọn ọmọge to rẹwa gan-an ma wa woran ti Ọba o si ma naa irukere ọwọ rẹ si wọn, ni eyi ti o tunmo sipe Ọba ti gbese le ti wọn o si mu iru awọn ọmọge naa wo aafin lọ.

Ọba Rufus Adeyemo Adejugbe tun salaye fun ikọ BBC News Yoruba pe Elewi jẹ ọkan lara ọmọ lẹyin Oduduwa, paapaa Elewi jẹ ogbufọ fun Oduduwa lati Ile-ife.

Ewi ati Oranmiyan bẹrẹ irinajo lati Ile-ife lọ si Iluu Benin ni Ìpínlẹ̀ Edo. Wọn tun gbera kuro ni bẹ wa si Ita Amodi.

Awọn obinrin ti wọn ro dẹdẹ kan dudu kunlẹ niwaju Ewi ilu Ado Ekiti.

Ita Amodi ni wọn wa titi di akoko kan. Nibẹ ni Ewi ti bi ọpọlọpọ ọmọ rẹ. Nibẹ ni ati ri Ewi Olowuro ati Ewi Awamaro. Ita Amodi ni Ewi wa titi to fi waja gẹgẹ bi ọba. Eyin iku Ewi ni ọkan ninu ọmọ rẹ jẹ ọba ti orukọ rẹ n jẹ Ewi Olowuro.

Ni akoko naa Ewi Olowuro jẹ ẹni to gbọ Ifa daada o si tun jẹ ẹni to ni ọgbọn. Akoko yi ni wọn difa, ti Ifa si sọ fun wọn pe, wọn ko ti de ibi ti wọn n lọ. Nitori Ita Amodi ko le gba awọn mejeji lati mọ jọ gbe ni iluu Benin.

Eleyi lo mu Ewi Olowuro to fi kuro ni iluu Benin wa si Ido-ani titi de iluu Agbaduo.

Aworan awọn araalu to n ki Kabiyesi
Àkọlé àwòrán, Asiko yii lawọn ọmọ bibi ilu Ado Ekiti maa n wa ṣe ajọyọ orikadun

Iluu Agbaduo ni Ewi Olowuro ati awọn to tẹ le ti duro díẹ, ti Ewi Olowuro si ti mura lati fi iluu Agbaduo ṣe ibudo. Sugbọn ifa tun sọ fun wọn pe, wọn ko ti de ibi isinmi wọn rara.

Nigba naa ni awọn agbalagba to wa laarin wọn ni awọn ko lọ mọ ni ti awọn. Idi ni yi ti wọn fi pe iluu Agbaduro ni Agbaduo. Ko si ẹni ti ẹ ma bere itan yi lọwọ rẹ loni yoo sọ fun yín pe, Iluu Agbaduo ni Ewi Olowuro ti kọkọ duro tẹdo si.

Awọn ẹgbẹ kan ninu aṣọ ofi pupa n kẹyẹ wa ki Ewi ado Ekiti.
Àkọlé àwòrán, Lẹgbẹlẹgbẹ, lọgbalọgba lawọn ọmọ ilu Ado Ekiti yoo maa kẹyẹ wa ki Ọba wọn lasiko ajọdun naa.

Irinajo naa lo gbe de iluu Ade-Ekiti. Nigba ti wọn de iluu Ado-Ekiti, ipade àkọ́kọ́ ti wọn kọkọ mọ ṣe ni wọn ṣe ni abẹ igi Iroko. Igba yi ni Ifa sọ fun wọn pe, iluu Ado-Ekiti ni ki wọn tẹdo si. Idi ni yi ti wọn n fi pe, iluu Ado ni Ado titi di oni oloni yii.

Awọn babanla wa fi ohun si ni akoko naa pe, ọjọ oni wọn gbọdọ mọ yaa sọ tọ lati mọ fi dupẹ lọwọ Ọlọhun.

Eleyi lo mu ọdun Udiroko waye lati mọ fí dupẹ lọwọ Ọlọrun. Ati igba naa ni gbogbo ọmọ bibi iluu Ado-Ekiti wọn gbọdọ wa si ile fun ọdun Udiroko lati fi dupẹ lọwọ Ọlọ́run ati lati mọ riri oore ti Ewi Olowuro ṣe.

Awọn ẹgbẹ obinrin kan n ki kabiyesi ilu Ado Ekiti lori ikunlẹ ninu aṣọ ẹgbẹjọda wọn.