Razak Omotoyossi, akọni ọmọ Yorùbá tó jẹ́ agbábọ́ọ̀lù fún ilẹ̀ Benin àti ọkọ òṣèré tíátà, kú lẹ́ni ọdún 39

Oríṣun àwòrán, Bose Alao
Ọmọ Naijiria to n gba bọọlu fun orilẹede Benin, Razak Omotoyossi, ti jade laye.
Oun ni ọkọ gbajumọ oṣere titata Yoruba, Bose Alao, nigba kan ri.
Ẹgbẹ agbabọọlu to n gba bọọlu fun tẹlẹ nilẹ Sweden, Helsingborgs IF, lo fidi iroyin iku rẹ mulẹ.
Ninu atẹjada kan loju opo X rẹ, ikọ agbababọọlu naa ni ""Helsingborgs IF n ṣọfọ.
"Wọn ti fi to wa leti pe agbabọọlu wa atijoọ, Razak Omotoyossi ti papoda lẹni ọdun mọkandinlogoji."
Ninu ifẹsẹwọnsẹ marunlelaadọta to ti gba bọọlu fun ilẹ Benin, igba mọkanlelogun ni Razak Omotoyossi sọ bọọlu sinu awọn
Liigi bọọlu Naijiria ni Omotoyossi ti bẹrẹ gbọọlu gbọọlu gbigba ko to pa orilẹede rẹ da si ti Benin lati maa gba bọọlu fun wọn, to si di ilumọọka nibẹ.
Ninu igba marunlelaadọta to gba bọọlu fun Benin, igba mọkanlelogun lo sọ bọọlu sinu awọn, eyii to mu ko di ọkan lara awọn agbabọọlu to sọ bọọlu sinu awọn julọ fun orilẹede naa.
Irawọ rẹ tan kalẹ lẹyin igbiyanju rẹ ninu awọn ifẹwọnsẹ igbaradi fun idije Africa Cup of Nations ti ọdun 2008 nibi to ti sọ bọọlu mẹrin sinu awọn orilẹede Togo.
O tun wọ inu itan gẹgẹ bii agbabọọlu akọkọ to sọ bọọlu sinu awọn ninu idije Africa Cup of Nations.
Oloogbe naa ti gba bọọlu ni Afrika, ilẹ Europe ati Middle East.
Lara awọn orilẹede to ti gba bọolu ri ni South Africa, Libya, Egypt, Syria, Moldova, Sweden, ati France.
A ko tii le sọ ohun to ṣokunfa iku oloogbe naa lasiko ti a n ko iroyin yii jọ.
Bose Alao n ṣedaro ọkọ ọkọ rẹ, Razak Omotoyossi to jade laye
Ọpọ awọn ololufẹ gbajumọ oṣere tiata, Bose Alao lo ti bẹrẹ si n ba a kẹdun ologbe naa bayii.
Bo tilẹ jẹ pe oun funra rẹ ko tii sọ nnkankan nipa oloogbe naa lẹyin iku rẹ, ọpọ awọn ololufẹ rẹ lo ti bẹrẹ si n fi ọrọ ibanikẹdun ranṣẹ si.
Ti ẹ ko ba gbagbe, Alao lo ṣe alaga iduro nibi ayẹyẹ igbeyawo Priscilla Ojo ati ọkọ rẹ, Juma Jux to milẹ titi lọdun yii.
Ṣaaju iku oloogbe ọhun ni Alao ti kọkọ kede pe igbeyawo oun ati Omotoyossi ti wa sopin lẹyin ọdun mẹwaa ti wọn ti wa papọ.
Iyalẹnu ni iroyin naa jẹ fun ọpọ awọn ololufẹ rẹ nigba ti wọn gbọ pe igbeyawo ọhun ti fori ṣanpọn.
Idi ni pe ikede ituka naa ko jinna si asiko to ṣajọyọ ọdun mẹwaa awọn mejeji papọ gẹgẹ bii tọkọ-taya.
Koko nipa itan igbe aye Razak Omotoyossi
Ọjọ kẹjọ osu Kẹwa ọdun 1985 ni wọn bi Razak Omotoyossi, to si jẹ akọsẹmọsẹ agbaabọọlu ati atamatase lori papa.
Ilu Eko ni wọn bi si, to si bẹrẹ ere bọọlu naa nilẹ Naijiria.
Saaju lo ti gba bọọlu fun awọn ẹgbẹ agbabọọlu nilẹ Naijiria, Egypt, Sweden, Saudi Arabia ati France.
Ijọba Naijiria fofin de Razak lati mase kopa ninu ere bọọlu fun ọdun marun eyi to fẹ se akoba fun isẹ to yan laayo naa.
Ẹsun ti wọn fi kan ni pe o yaju si obinrin adari ayo kan lasiko idije Premier League laarin Sunshine Stars ati Eyimba.
Eyi si lo mu ko morile orilẹede Benin lati lọ maa gba bọọlu nibẹ, to si di ọmọ orilẹede Benin laarin ọdun kan.
Razak soju orilẹede Benin lasiko ifẹsẹwọnsẹ laarin ilẹ Naijiria ati Benin bi o tilẹ jẹ pe ọmọ orilẹede Naijiria ni.















