Iye àwọn tó kú nínú ìkọlù àwọn agbébọn tó ya bo Mọ́ṣálásí lásìkò ìrun Àsùbáà ní Katsina dí 30

Oríṣun àwòrán, ISSOUF SANOGO/AFP VIA GETTY IMAGES
Iye awọn eeyan to ti ku ninu ikọlu awọn agbebọn si mọṣalaṣi kan ni ipinlẹ Katsina ti di ọgbọn.
Awọn alaṣẹ ni ipinlẹ Katsina lo sọ eyi lẹyin ti iroyin ti kọkọ gbe e pe eeyan marundinlọgbọn lo ti kọkọ jade laye ṣaaju.
Awọn agbebọn naa kọlu mọṣalaṣi ọ̀hun lasiko irun ni afẹrẹmọjumọ ọjọ Iṣẹgun.
Awọn ti ikọlu naa ṣoju wọn sọ pe awọn agbebọn naa tun kọlu awọn ileto ati ilu miran ti wọn si tun ji awọn eeyan gbe salọ.
Awọn kan n woye pe o ṣeeṣe ki ikọlu naa jẹ eyiti awọn agbebọn naa fi gba ẹsan lara awọn ileto ti wọn kọlu ni, lẹyin ti awọn olugbe awọn ileto naa kọlu awọn agbebọn naa ti wọn si pa pupọ lara wọn. Lasiko ti wọn kọlu awọn agbebọn ọhun ni ibuba wọn, wọn tu ọpọlọpọ awọn ti wọn gbe si inu igbeskun silẹ, wọn si ko awọn nnkan ijagun wọn.
Ni deede ago mẹfa aarọ ku isẹju mẹẹdogun, lawọn agbebọn naa ya wọ Mọsalasi kan to wa ni agbegbe ileto kan ti wọn n pe ni Unguwan Mantau , ni ijọba ibilẹ Malumfashi , nipinlẹ Katsina.
Ọpọlọpọ awọn eeyan to wa kirun ninu Mọsalasi naa ni wọn yinbọn pa, ti aimọye eeyan miran si fara gbọgbẹ ọta bọn.
"Lasiko isẹlẹ naa, a ko ri osisẹ alaabo kankan, gbogbo mọlẹbi mi lo ti sa kuro ni abule yii, awa eeyan perete si ni a si ku sẹyin ni gbogbo abule yii"
Ẹnikan ti isẹlẹ naa soju rẹ amọ ti ori ko yọ sọ fun BBC pe eeyan mẹẹdọgbọn lawọn agbebọn naa pa ninu Mọsalasi ọhun.
Amọ o ni eeyan marun lo fara pa ninu isẹlẹ naa.
Osojumikoro naa, ti ko fẹ ka darukọ oun salaye siwaju si pe aago mẹfa ku diẹ ko lu ni isẹlẹ naa waye ni aarọ ana nigba tawọn eeyan kirun aarọ tan.
" Ni idaji ana ọjọ Isẹgun, ni deede ago mẹfa aarọ ku isẹju mẹẹdogun, lawọn agbebọn tun ya wọ Mọsalasi, ti wọn si sina ibọn bolẹ lojiji.
Lẹsẹkẹsẹ ni eeyan mẹẹdọgbọn jade laye tawọn marun miran si farapa, amọ awọn to farapa naa lo ti n gba itọju nile iwosan kan ni ilu Katsina bayii."
Bakan naa, Osojumikoro naa fikun pe awọn ko ri osisẹ alaabo kankan nitosi lati wa doola ẹmi awọn lọwọ awọn agbegbọn ọhun.
"Igba ti isẹlẹ naa waye tan, ti awọn agbebọn si ti lọ lẹyin ti wọn pa ọpọ eeyan tan lawọn agbpfinro to de.
Wọn bẹrẹ si ni ya awọn aworan nipa isẹlẹ naa amọ laarin wakati meji, wọn ti kuro nibi isẹlẹ naa.
Bi mo se n ba yin sọrọ yii, gbogbo mọlẹbi mi lo ti sa kuro ni abule yii, awa eeyan perete si ni a si ku sẹyin ni gbogbo abule yii"
Awọn eeyan agbegbe naa wa n rawọ ẹbẹ si ijọba ipinlẹ Katsina atawọn agbofinro pe ki wọn dide lati da alaafia pada si agbegbe naa.
Eeyan mẹtala lo ku lasiko ikọlu naa, awọn agbebọn wa gbẹsan ikọlu tawọn ara abule Unguwan Mantau se si wọn lọjọ meji sẹyin ni – Ijọba ipinlẹ Katsina fọhun
Wayi o, Ijọba ipinlẹ Katsina ti gbe igbesẹ nipa isẹlẹ isekupani ọhun, to si kede awọn ipese eto aabo ti yoo gbe lati da alaafia pada si abule Unguwan Mantau.
Kmisana feto aabo labẹle ati ọrọ to kan ipinlẹ naa, Ọmọwe Nasir Mu'azu, lo kede bẹẹ lorukọ ijọba ipinlẹ naa.
Amọ o ni 'eeyan mẹtala lo padanu ẹmi wọn lasiko ti wọn n kirun owurọ', ti awọn agbebọn si yinbọn mọ wọn.
"Isẹlẹ naa lo waye nigba ti awọn ọdaran kan lọ se ikọlu lati gbẹsan ni abule yii.
Awọn Musulumi n lọ kirun aarọ ni Mọsalasi nigba tawọn agbebọn naa ya wọle, ti wọn si n yinbọn laibikita sawọn eeyan inu Msalasi naa"
O ni awọn agbegbọn naa wa gbẹsan "aayan eto aabo to pegede" tawọn eeyan abule naa se lọjọ meji sẹyin.
Awọn eeyan abule Unguwan Mantau yii si lo pinnu lati sapamọ de awọn agbebọn to n bọ, ti wọn si pa pipọ lara wọn."
Kọmisana naa ni awọn eeyan abule naa lo doola ẹmi awọn olugbe abule Ruwan Sanyi tawọn agbebọn ọhun ti ji gbe, ti wọn si tun gba awọn ọkada wọn pada lọwọ awọn agbegbọn naa.
"Awọn agbofinro ti w ani abule Unguwan Muntau lati da alaafia pada si agbegbe naa.
Awọn Ologun ati ọlọpaa si ti setan lati ko awọn osisẹ wọn lọ doola ẹmi awọn ara abule ọhun lọwọ awọn ọdaran naa.
Idi ni pe lasiko ojo yii, awọn agbebọn maa n fi ara soko, ti wọn yoo si sa sabẹ ohun ọgbin lati sisẹ ibi wọn."
Ijọba ipinlẹ Katsina ni oun n sisẹ kara lati ri daju pe awọn ri awọn agbebọn naa mu lati wa foju fina ofin, ki wọn le jiya ẹsẹ wọn.
Mọ̀ nípa àwọn olórí ẹgbẹ́ agbésùnmọ̀mí, Ansaru, tí àwọn ẹ̀ṣọ́ aláàbò Naijiria ṣẹ̀ṣẹ̀ mú
Mallam Nuhu Ribadu to di ipo olugbani-nimọran fun ijọba apapọ Naijiria lori eto aabo mu, ti kede pe awọn ẹṣọ alaabo ilẹ yii ti nawọ gan awọn olori ẹgbẹ agbesunmọmi meji ti a mọ si ẹgbẹ Ansaru.
Mahmud Muhammad Usman (Abu Baraa) ni Ribadu pe orukọ olori ẹgbẹ Ansaru tọwọ ba, Igbakeji rẹ si ni Mahmuda.
Awọn olori ẹgbẹ meji yii ni Ribadu kede pe wọn wa nidii ijinigbe ọlọkan-o-jọkan ni Naijiria, paapaa ijinigbe awọn eeyan nla.
Nibi ipade awọn akọroyin to waye ni ọfiisi rẹ ni olugbani-nimọran lori eto aabo Naijiria naa ti kede eyi.
Gẹgẹ bo ṣe wi nipa Mahmuda ni tiẹ, Ribadu sọ pe:
"Orilẹede Libya ni Mahmuda ti kọṣẹ laaarin 2013 si 2015, awọn alakatakiti lati ilẹ okeere bii Egypt, Tunisia ati Algeria lo kọṣẹ lọwọ wọn.
''O fi ẹka lilo nnkan ija ṣe akọkọ ninu iṣẹ to kọ, ati ti wọn ṣe n ṣe atọwọde ado oloro."
'Ìjọba ti ń wá wọn fún ọdún pípẹ́ sẹ́yìn''
Nigba to n tẹsiwaju nipa awọn olori ẹgbẹ agbesunmọmi naa, Nuhu Ribadu sọ pe o pẹ ti orukọ wọn ti wa lori atẹ awọn eeyan ti ijọba n wa.
Ribadu ṣalaye pe lẹyin ti wọn pawọpọ kọju ija si araalu, awọn ẹṣo alaabo, ti wọn si tun ba awọn nnkan amayedẹrun ilu jẹ ni ijọba kede wọn bii ẹni ti wọn n wa.
Lara awọn iṣẹ buruku ti wọn ti ṣe gẹgẹ bi Ribadu ṣe la a kalẹ ni:
Ọgba ẹwọn Kuje ti awọn ẹlẹwọn ti sa lọ ni 2022.
Ikọlu to ba ileeṣẹ Niger ti wọn ti n ri si eroja Uranium.
Jiji onimọ ẹrọ ọmọ ilẹ Faranse kan, Francis Collomp, gbe ni Katsina.
Jiji Alhaji Musa Umar Uba (Magajin Garin Daura) gbe lọjọ kin-in-ni, oṣu Karun-un ọdun 2019.
O fi kun un pe awọn olori ẹgbẹ Ansaru meji yii naa lo ji Emir ilu Wawa, gbe.
O ni ẹgbẹ yii tun ni ajọṣepọ pẹlu awon agbesunmọmi lati Mali, Niger ati Burkina Faso.
Ṣaa, awọn meji ti wọn n wa kiri agbaye yii ti di ẹni igbekun ijọba bi Ribadu ṣe sọ.
''Àṣeyọrí aláìlẹ́gbẹ́ ni mímú tí a rí wọn mú''

Oríṣun àwòrán, Getty Images
" Mimu ti a mu Abu Baraa ati Mallam Mamuda, ti wọn jẹ Olori ati Igbakeji yii jẹ aṣeyọri alailẹgbẹ fun wa ninu igbiyanju lati ṣẹgun awọn ẹgbẹ to n da Naijiria laamu.''
Olugbani-nimọran lori eto aabo ni Naijiria, Nuhu Ribadu lo
ṣalaye bẹe.
O ni ikọlu gidi lo ba ẹgbẹ Ansaru bayii, iru eyi ti ko ṣẹlẹ si wọn ri latigba ti wọn ti da a silẹ.
Ribadu fi kun un pe opin ti n de ba ẹgbẹ Ansaru bayii, pẹlu awọn olori wọn to ti wa nigbekun ijọba.
Iroyin sọ pe oṣu Kin-in-ni ọdun 2012 ni ẹgbẹ Ansaru kọkọ yọju sita nipinlẹ Kano.
Wọn kede nigba naa pe ẹka Boko Haram ni awọn, ṣugbọn awọn ṣe 'ọmọluabi.'
Ṣugbọn ko pẹ ti wọn fi bẹrẹ si i doju ija kọ awọn ẹṣọ alaabo Naijiria, awọn araalu ati dukia ijọba.
Gẹgẹ bi Ribadu ṣe wi, ẹgbẹ Ansaru fi ara pamọ fun ọpọlọpọ ọdun ni ibuba wọn ati ni awọn inu igbo lapa Ariwa Naijiria.
O ni paapaa julọ ni awọm agbegbe to wa nitosi Kainji National Park, won n ṣoṣẹ ni Niger ati Kwara pẹlu ilẹ Olominira Benin.














