Ó dùn mí pé Olubadan Olakuleyin wàjà, mo rò pé yóò lò tó ọdún márùn-ún ni, mo ń sọ fúnrá mi pé ń kò tíì ṣetán láti jẹ́ Olubadan - Ladoja

Àkọlé fídíò, Oba Ladoja
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 7

Olubadan tuntun fun ilẹ Ibadan, Ọba Rashidi Adewolu Ladoja ti ni o dun oun pupọ pe Olubadan Owolabi Olakuleyin ku tori oun ro pe yo lo to ọdun marun si mẹwa lori itẹ ni.

Ladoja woye ọrọ yii lasiko to n ba akọroyin BBC News Yoruba sọrọ nile rẹ to wa ni adugbo Bodija ni Ibadan ni kete to gunlẹ silu Ibadan.

Ọba Ladoja ni oun n sọ fun ara oun pe oun ko tii setan lati jẹ Olubadan amọ kii de ba ni ka yẹri, gbọngbọn ni kan ọlọrọ.

"Koda, mo n bi Ọlọrun pe ki lo de to da emi si nigba ti mo ro awọn eeyan nla nla to wa nibi ayẹyẹ iwuye mi amọ ti wọn ko si laye mọ.

Mo dupẹ lọwọ Ọlọrun pe o da ẹmi mi si, o si foju han pe isẹ si ku to fẹ fun mi se ni, mo wa n bẹbẹ fun ọgbọn ati oye lati sisẹ naa."

Ọba Rashidi Adewolu Ladoja

"Ifa kọ lo n yan Ọba Ibadan, owo si kọ lo n yan Ọba Ibadan, Ọlọrun ni"

Ọba Rashidi Adewolu Ladoja wa ṣapejuwe irin-ajo rẹ si itẹ Olubadan gẹgẹ eyi ti o kun fun idanwo ati ilakọja to lagbara.

Ọba Rashidi Adewolu Ladoja ṣalaye pe ọdun 1944 ni wọn bi oun, ti oun yoo si di Olubadan 44th laipẹ yii.

Ladoja ni Ifa kọ lo n yan Ọba Ibadan, owo si kọ lo n yan Ọba Ibadan, Ọlọrun ni.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

"Ọjọ kinni osu kẹwa ọdun 1993 ti mo gba oye gẹgẹ bi jagun Olubadan, ọpọ eeyan lo peju sibẹ.

Awọn bii Basorun Moshood Kashimawo Abiola, Oloye Lamidi Adedibu, Gomina tẹlẹ Kolapo Olawuti Ishola ati Adebayo Alao Akala.

Bakan naa, Dokita Dejo Raimi, baba ati iya mi ati awọn eeyan jankan jankan miran bii Jimoh Aliu, Orisabunmi atawọn osere tiata miran, lo peju sibi ayẹyẹ iwuye naa.

Amọ ọpọ awọn eeyan nla yii lo ti di oloogbe, sugbọn Ọlọrun da ẹmi mi si, ti maa si gba Ade Olubadan laipẹ.

Irin ajo mi si ipo Olubadan kun fun suuru, iforiti ati oju rere Ọlọrun, mo si n fi ẹmi imoore mi han si igbimọ awọn lọba lọba fun Olubadan nitori wọn fọwọsi yiyan mi gẹgẹ bii Olubadan titun."

Bakan naa, Ọba Ladoja tun ṣalaye wi pe ijiroro yoo bẹrẹ pẹlu awọn ti ọrọ ifinijoye oun kan julọ, paapaa ni pàtàkì julọ Gomina ipinlẹ Ọyọ, Seyi Makinde, Oluwo, Araba ti Ibadan, ati awọn alaṣẹ ninu ẹsin ibilẹ miiran fun igbaradi fun eto jijẹ Olubadan.

Ni ipari, Ọba Ladoja pe fun adura lati ọdọ awọn ọmọ bibi ilẹ Ibadan ati awọn olugbe rẹ

Ọba Ladoja wa gbadura fun ọgbọn ati òye lati dari ilu Ibadan pẹlu ododo, alafia.

Ọba Rashidi Adewolu Ladoja wọ ankara alawọ ewe, o de fila sanyan, to si fi ilẹke alawọ buluu si ọrun, o joko sori aga dudu kan.
Àkọlé àwòrán, Rashidi Adewolu Ladoja

Ladoja morile agboole baba rẹ ni kete to de silu Ibadan

Ni kete to de ẹnu iloro masọsẹ Eko si ilu Ibadan, ni ọpọ ero ti duro lati ki Adewolu kaabọ silu baba rẹ, ti wọn si to lọwọọwọ tẹle mọto rẹ lẹyin.

Agboole Baba rẹ to wa ni adugbo Born Photo ni Isalẹ Osi ni Ladoja morile, lati ki gbogbo ẹbi rẹ ku ile o.

Bo si se n wọ adugbo naa ni awọn eeyan n tu jade lati se ayẹsi rẹ, wọn n jo, wọn n yọ pe oye Olubadan naa ko sile awọn koro.

Awọn onilu gan fi gọngọ dabira si ara ilu pẹlu oniruuru orin ọpẹ.

Lẹyin isẹju diẹ, ni Ladoja kuro ni agboole baba rẹ naa, to si morile ile tiẹ gan to n gbe ni adugbo Bodija atijọ nilu Ibadan.

Koda, awọn ero to n duro de Ladoja nile rẹ naa kọ sisọ, ti isọri orin ọpẹ miran si tun gba ẹnu wọn kan bi wọn se foju ganni Olubadan tuntun naa.

Lẹyin ti Ladoja joko sinu ile tan, lo ba awọn akọroyin to wa nikalẹ sọrọ ninu eyi ti ileesẹ iroyin BBC News Yoruba wa.

Ọba Rashidi Adewolu Ladoja lo gunlẹ silu Ibadan lati wa bẹrẹ eto ayẹyẹ ifinijoye rẹ.

Ladoja ni oye Olubadan kan, lẹyin ti ọba Owolabi Olakuleyin waja.

Ọjọ Mọkalelogun si ni wọn kede lati fi kẹdun iku Olubadan to gbesẹ naa, laarin awọn ọjọ yii naa si ni wọn sinku rẹ nile ijọsin Peteru Mimọ, Aremọ nilu Ibadan.

Ni gbogbo asiko ikẹdun iku ọba to waja naa, ẹni ti ipo ọba kan, tii se Ọtun Olubadan, ko si nile, to si wa nilu Eko.

Amọ ni ana ọjọ Aje ni Olubadan tuntun naa fi tilu tifọn wọle silẹ Ibadan, tawn araalu si fi tilu tifọn ki kaabọ.

Ọba Ladoja atawọn ẹbi rẹ joko papọ, ti oun ati awọn iyawo rẹ si fi ilẹkẹ sọrun

Koko pataki nipa igbe aye Olubadan tuntun, Rashidi Adewolu Ladoja?

Ọjọ kẹrinlelogun, oṣu Kẹsan-an ọdun 1944 ni wọn bi Rasheed Adewolu Ladoja si agbegbe Gambari, lẹba ilu Ibadan.

O lọ sileewe Ibadan Boys High School laarin ọdun 1958 si 1963 ati Olivet Baptist High School laarin ọdun 1964 si1965.

Adewolu tẹsiwaju ninu ẹkọ rẹ, o lọ si University of Liège, lorilẹede Belgium, iyẹn laarin ọdun 1966 si 1972, nileewe naa lo ti gboye nipa imọ ẹrọ (Chemical engineering).

Ọdun 1993 ni wọn dibo yan Rasheed sile igbimọ aṣofin apapọ, nigba to jẹ ọmọ ẹgbẹ oṣelu United Nigeria Congress Party (UNCP).

Ni ọdun 2000, Rasheed Ladoja di ọga agba nile ifowopamọ Standard Trust Bank Limited.

Oṣu Kẹrin ọdun 2003 ni wọn dibo yan an sipo gomina ipinlẹ Oyo, ẹgbẹ PDP lo si gbe e wọle sipo naa, oṣu Karun-un ọdun naa lo di gomina.

Ṣaaju iyansipo yii, Oloogbe Lamidi Adedibu, agba oṣelu ninu PDP nilẹ Ibadan nigba naa, duro bii igi lẹyin ọgba fun Ladoja.

Asiko yii si ni Oloye Olusegun Obasan wa nipo aarẹ ni Naijiria, ti Adebayo Alao Akala si jẹ igbakeji Ladoja.

Loṣu Kẹjọ ọdun 2004, ija de laaarin Ladoja ati Adedibu lori ọrọ iyansipo ati iṣuna owo.

Ọba Lamidi Ladoja wọ asọ oke Sanyan, o fi ilẹkẹ sọrun, o si de fila pẹlu.
Àkọlé àwòrán, Ọba Rashidi Ladoja

Ki lo de ti Ladoja se kọ lati gba 'ade paali' lọwọ gomina Abiola Ajimobi ati Seyi MAkinde?

Nigba ti gomina Abiola Ajimobi wa nipo gomina, o kede atunse si ilana oye jijẹ nilẹ Ibadan eyi ti ọpọ eeyan tako, to si mu awuyewuye lọwọ nigba naa.

Asiko naa si ni Ajimobi kede pe ki awọn agba oye Olubadan wa tẹri gba ade gẹgẹ bi ọba ni adugbo ti koowa wọn ti wa, eyi ti ọpọ eeyan se apejuwe bii 'ade paali'

Bi o tilẹ jẹ pe awọn agba oye kan gba ade naa, amọ agba oye Rasheed Ladoja nikan soso lo fi aake kọri lati gba ade naa, eyi to se apejuwe bii 'ade paali', laarin awọn agba oye yoku nilẹ Ibadan.

Nigba ti Abiola Ajimobi kuro nipo, ti Seyi Makinde si di gomina, sibẹ oun naa taku pe Ladoja gbọdọ gba ade paali yii, to ba fẹ di Olubadan.

Ṣugbọn lẹyin awuyewuye lori ilana eto oye jijẹ ilẹ Ibadan, ijọba sọ igbesẹ gbigba ade paali naa di ofin, eyi to pọn ni dandan fun Ladoja lati gba ade naa bi yoo ba de ipo Olubadan.

Lẹyin o rẹyin, Adewolu mu suuru, o si gba ade naa, se suuru ni baba iwa.

Bẹẹ lo si ṣe to gba ade naa lọjọ kejila, oṣu Kẹjọ ọdun 2024. Kabiyesi Owolabi Olakulẹyin to waja yii lo gbe ade ọhun le Ladoja lori.

Lati igba naa lo si ti han pe gbogbo eto lo ti to fun Rasheed Adewolu Ladoja lati bọ sori aleefa Olubadan ilẹ Ibadan bi ọjọ ba pe.

Ki ẹṣin ọba o jẹko pẹ pẹlu alaafia ara ladura ti araalu n gba, bi Adewolu yoo ṣe gun ori itẹ awọn baba to bi i lọmọ gẹgẹ bii Olubadan kẹrinlelogoji nilẹ Ibadan.

Kabiyesi o.