Kí ló dé táwọn Olubadan ń wàjà léraléra àti ìdí tí Ibadan ṣe ń jẹ́ Ọmọ Agbọ́tikúyọ̀?

Lẹyin ti Olubadan ti ilẹ Ibadan, Ọba Owolabi Olakulehin waja, ọpọ eeyan kaakiri ilẹ Yoruba lo ti n fi ọrọ ibanikẹdun ransẹ si aafin rẹ.
Amọ bi awọn eeyan ṣe n ba idile ori ade naa ati gbogbo awọn olugbe ilu Ibadan kẹdun, lawọn mii n woye pe ki lo de ti awọn Olubadan kii pẹ lori oye.
Koda, se ni awọn eeyan kan tun n kọminu pe ki lo de ti awọn eeyan kan ṣe maa n yọ lasiko ti Olubadan kan ba waja?
Idi ree ti BBC Yoruba fi kan si ọkan lara awọn Oloye ilẹ Ibadan, Agba oye Lekan Alabi, to tun jẹ Maye Olubadan, lati tan imọlẹ si ibeere mejeeji yii.
Nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ lori idi to fi jẹ pe arugbo lo n joye Olubadan, eyi to n mu ki wọn ma fi pẹ lori oye, Lekan Alabi ni bi wọn ṣe n joye nilẹ Ibadan yatọ si bi wọn ṣe n ṣe lawọn ibomii nilẹ Yoruba.
O ni "Koda nigba ti awọn oyinbo alawọ funfun ṣi wa nibi, wọn ri pe iyatọ wa ninu bi wọn ṣe n yan ọmọ oye nilẹ Ibadan, nitori eto naa ko ni magomago kankan ninu.
"Bẹẹ ni wọn ki n fi owo ṣe e tabi pe mo mọ eeyan kan, ti o ba ti gbesẹ lori akaba yẹn, ibi ti Ọlọrun ba ti sọ pe o maa pari rẹ si naa ni o maa pari rẹ si."
O fikun pe awọn akaba ti oloye Ibadan kan yoo gun fun ọpọlọpọ ọdun p pupọ, eyi to maa n jẹ ki wọn di arugbo, ki wọn to de ipo Olubadan.e
Ṣe ọmọde ko le role ni Ibadan ni, ti ko fi ni di arugbo, ko to de ipo Olubadan?
Nigba to n sọrọ lori boya ọmọde le role Olubadan, Oloye Lekan Alabi ṣalaye pe ipade kan ti waye ri ni gbagede ọgba ile ẹkọ fasiti Ibadan, nibi ti ọkan lara awọn to sọrọ nibẹ ti daba pe ki oloye Ibadan to ba ti le ni ọgọta ọdun, fa ọmọ bibi inu rẹ kalẹ lati role Olubadan.
Oloye Alabi ni se ni awọn eeyan to wa nibi ipade ọhun kọ jalẹ pe eyi ko le see se.
O ni "asiko naa ni wọn sọ pe, ẹni to ba fẹ role, ko lọ bẹrẹ ni ipele oye Mogaji gẹgẹ bo ṣe wa lati igba iwasẹ, ati pe, "ori yoo gbe de akasọ oye ti ori yoo gbe de."
Oloye Alabi mẹnuba pe Ọba Yunusa Bankole Oladoja Ogundipe, lo ọdun marundinlogun lori ipo Mogaji ko de ipo Olubadan.
Gẹgẹ bo ṣe sọ, igba naa ni gomina tẹlẹ, Abiola Ajimobi paṣẹ ki gbogbo awọn to wa lori ila lati joye Olubadan maa ṣe ayẹwo ilera ara wọn.
Ki ni yoo sẹlẹ bayii ti ẹni ti ipo Olubadan kan ti le lọgọta ọdun?
Oloye Lekan Alabi sọ pe ko si ohun aburu kankan ti yoo ṣẹlẹ si ẹni ti ipo naa kan bayii, iyẹn Oloye Rashidi Ladoja, to ti fi akoko igba kan jẹ gomina ipinlẹ Oyo.
Alabi ni kete ti eeyan ba ti role Olubadan ni awọn mọlẹbi rẹ yoo ti maa gbadura fun pe 'lagbara Ọlọhun, iwọ naa yoo kajọ Ibadan, oo k'ajọ Ibadan.'
"Iye ọdun ti onikaluku yoo lo wa lọwọ Ọlọrun."
Ki lo de ti wọn fi n pe Ibadan ni ọmọ agbọtikuyọ?
Nigba to n sọrọ lori idi ti wọn fi n pe Ibadan ni ọmọ agbọtikuyọ, Oloye Alabi ni ti oloye kan ba ti goke agba lati oye Mogaji si adele, wọn maa sọ fun ẹni naa pe madarikan ni oye naa jẹ.
Eyii to n tumọ si pe iru ẹni bẹẹ ko gbọdọ ro ibi si ẹni to wa niwaju rẹ, ẹni ti wọn jọ jẹ sawawu atawọn to wa lẹyin rẹ nitori irufẹ ero ibi bẹẹ le da le ẹni ọhun lori.
O ni "Ibadan, ti wọn ba n sọ pe Agbọtikuyọ, o tumọ si pe bi ẹnikan ko ba lọ, ẹlomiran ko ni le goke.
"Iyẹn ni pe o ko ni le lọ soke ti ẹnikan ko ba lọ gẹgẹ bo ṣe wa ninu oye ileeṣẹ ọmọ ogun."
Lekan Alabi pari ọrọ rẹ pe ilu, fere ati ṣẹkẹre ni wọn fi n mọ pe Olubadan waja laye atijọ.
O ni idi ree ti wọn se maa n lu ilu nile ẹni ti oye Olubadan ba kan, ni kete ti Olubadan to wa lori oye ba ti gbesẹ tan.















