Òjò àrọ̀ọ̀rọ̀dá fá ẹ̀kún omi l'Ondo, ọ̀pọ̀ dúkìá bàjẹ́, àwọn kan di aláìnílélórí

Aworan ọkan lara awọn agbegbe ti omiyale naa kan

Oríṣun àwòrán, Timilehin Ojueromi

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ojo arọọda kan to rọ fun ọjọ meji leralera, ti fa omiyale, to si tun se ọsẹ to lagbara niluu Okitipupa, ipinlẹ Ondo.

Awọn olugbe ilu Okitipupa to ba BBC Yoruba sọrọ lorii isẹlẹ naa salaye pe ojo naa bẹrẹ lọjọ Ẹti to kọja, ti ko si da titi di ọjọ Abamẹta.

Lara awọn opopona ti omiyale bajẹ ni Erinje, Ogungbo, Ode Etikan, Ereke, Ayetitun ati agbegbe Temidire.

Bakan naa ni omi gba agbegbe ile Alaga ijọba ibilẹ naa, Ọgbẹni Andrew Ogunsakin.

Wọn ṣalaye pe ojo naa ṣe akoba fun ọrọ aje awọn olugbe ilu naa, bẹẹ lo tun ba ọpọlọpọ dukia jẹ, ti ọpọlọpọ eeyan ko si ri ile wọ mọ.

Ọpọlọpọ opopona ti ko ni oju agbara ni omi naa wọ si, ti ko si fun awọn awakọ lanfaani lati kọja.

Kí ló fa omíyalé ni ilu Okitipupa?

Aworan ọkan lara awọn agbegbe ti omiyale naa kan

Oríṣun àwòrán, Timilehin Ojueromi

Gẹgẹ bi alaye awọn olugbe agbegbe ti iṣoro omi yii ba, wọn ni omi ṣọṣẹ latari awọn panti to ti di oju ọna to yẹ ki agbara ojo gba.

Wọn fi kun un pe ikuna ijọba lati se oju agbara si awọn opopona miran tun jẹ idi kan ti omi fi gba ile mọ awọn eeyan lọwọ.

Ọkan lara awọn eeyan ti ọrọ naa kan, Tolu Eshọ, salaye fun BBC pe omi ti gba gbogbo ile oun.

O ni oun ko ni anfaani lati lati wọ inu ile bayii.

Esho di ẹbi iṣẹlẹ naa ru ijọba Ondo, o ni bijọba Ipinlẹ Ondo ṣe kọ lati se ojuṣe wọn nipa ṣiṣẹ awọn oju agbara sawọn opopona lo fa wahala.

Bakan naa ni akẹkọọ kan toun naa koju iṣoro yii, Ayomiposi Isijola, banujẹ gidigidi bi omiyale ṣe sakoba fun ọpọ dukia rẹ.

O ni panti to di oju agbara lo fa a ti omi fi yale.

Ninu arọwa wọn, awọn tọrọ naa kan rọ Gomina Lucky Aiyedatiwa, lati ji giri.

Wọn rọ Aiyedatiwa lati bẹrẹ atunse si awọn oriko to fara gba ninu iṣẹlẹ omiyale yii.

Bẹẹ ni wọn pe fun iranlọwọ fun awọn to padanu dukia wọn.