Ṣé lóòótọ́ ni Gomina Ademola Adeleke ti kúrò nínú ẹgbẹ́ PDP?

Gomina ipinlẹ Osun, Ademola Adeleke

Oríṣun àwòrán, Gov.Ademola Adeleke/ X

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Ní báyìí tí omi agbo oselu Naijiria ń rú gbudu-gbudu, ọ̀pọ̀ àwọn oloselu kan lo n bọ sínú ẹgbẹ́ oselu miran.

Pẹlu bi awọn oloṣelu Naijiria ṣe n kuro ninu ẹgbẹ kan bọ si ikeji bayii, àwọn ọmọ Nàìjíríà tí wá ń fi ẹnu kún Gomina ipinlẹ Osun, Ademola Adeleke, pé òun náà ti là ìtàn láti kúrò nínú ẹgbẹ́ oselu PDP lọ sí APC.

Kódà, àwọn kan ni imọlẹ tí fẹ́ wọ inú òkùnkùn lọ ní ìpínlẹ̀ Osun èyí tó túmọ̀ sí pé gomina Adeleke, tí ọ̀pọ̀ mọ si Imọlẹ fẹ lọ sí ibòmíràn.

Pẹlu bi awọn ọmọ Naijiria ṣe wa mú ariwo rẹ bọnu pe o fẹ kúrò ninu ẹgbẹ kan bọ si ikeji bayii, Gomina ipinlẹ Osun, Ademola Adeleke, ti sọ bo ṣe n lọ ni iha tirẹ.

Ninu alaye to ṣe si oju opo X rẹ lọjọ Satide, ọjọ karun-un, oṣu Keje ọdun 2025, Adeleke tawọn eeyan tun mọ si Imọlẹ, kede pe oun ṣi n ṣe olootọ si PDP nipinlẹ Osun ni toun.

Gomina ipinlẹ Osun naa sọ pe ọmọ ẹgbẹ PDP ṣi loun tọkan-tọkan

'' Ipe ọlọkan-o-jọkan ni mo ti n gba lati nnkan bii wakati diẹ sẹyin, ti wọn n beere lọwọ mi pe ṣe mo ti kuro ninu PDP loootọ.

''Mo fẹẹ fi da ẹyin eeyan daadaa ipinlẹ Osun loju, pe olootọ ọmọ ẹgbẹ PDP ṣi ni mi. Ko si giri kankan''

Gomina Adeleke lo kede bẹẹ.

O ni afojusun oun ko yipada, bi oun yoo ṣe mu awọn koko marun-un toun ṣe ileri rẹ fun awọn eeyan Osun ṣẹ lo jẹ oun logun.

Adeleke fi kun un pe ki ẹnikẹni ma ṣe gba aheṣo to n lọ laaarin ilu pe oun ti kuro ni PDP gbọ.

O ni ki wọn maa ṣatilẹyin funjọba oun lọ.

Kí ló ń wáyé lọ́wọ́ ní agbo òṣèlú Nàìjíríà?

Ayipada oriṣiiriṣii lo n waye lagbo oṣelu Naijiria bayii, pẹlu bi awọn ẹgbẹ oṣelu tuntun ṣe n dide ni igbaradi fun idibo ọdun 2027.

Eyi n mu awọn kan fi ẹgbẹ to gbe wọn depo silẹ, ti wọn si n darapọ mọ ẹgbẹ miran kiri.

Awijare awọn ẹgbẹ alatako naa ni pe Naijiria ko gbọdọ di orilẹede ẹlẹgbẹ oṣelu kan. Wọn fi kun un pe ohun ti ẹgbẹ APC ati Aarẹ Bola Tinubu n fẹ niyẹn, ṣugbọn awọn ko ni i jẹ ko ri bẹẹ.

Bẹẹ si ni APC naa ko yee sọ pe ofo ọjọ keji ọja ni awọn alatako yoo ba de ninu idibo 2027.