Wo àwọn àkàsọ̀ tí Ọba Olakulehin gùn fún ọdún 41 kó tó di Olubadan

Ọba Owolabi Olakulẹhin
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Ọjọ kẹẹdogun oṣu Kẹta ọdun 2024 ni Olubadan tẹlẹ ri Oba Olalekan Balogun waje lẹyin ọdun meji to bọ sori aleefa.

Lẹyin naa ni Ọba Owolabi Olakulehin, ẹni ti ipo ọba naa kan gẹgẹ bi ilana ọba jijẹ nilẹ Ibadan ṣe gbe kalẹ lẹyin tawọn igbimọ lọbalọba ti kede rẹ.

Ọdun 1983 ni Oba Owolabi di Mogaji agboole Ige Olakulehin ni Ita Baale Olugbode niluu Ibadan.

Lẹyin naa lo bẹrẹ si ni sun gẹgẹ bi ilana ọba jijẹ ni Ibadan to si de ipo Jagun Balogun – Ajia – Bada – Aare Onibon – Gbonnka – Aare Egbe Omo-Oota – Lagunna – Aare Ago – Ayingun – Asaju – Ikolaba – Aare Alasa – Agba Akin – Ekefa – Maye – Abese – Ekaarun Balogun – Ekeerin Balogun – Ashipa Balogun – Osi Balogun – Otun Balogun, Balogun, ko to wa di Olubadan ti ilẹ Ibadan

Ọdun 1986 ni o di Jagun Balogun ilẹ Ibadan lasiko Ọba Asanike.

Ni ọdun 2016, Oba Owolabi di Balogun ti ilẹ Ibadan, to si wa nipo naa fun ọdun mẹjọ.

Ọpọ awọn eekan ilu lorilẹede Naijiria ati nipinlẹ Oyo lo peju si gbọngan Mapo nigba ti Oba Owolabi gba ade.

Lati le jẹ ki awọn araalu peju si ayẹyẹ ifiọbajẹ naa, Babalọja ti ilu Ibadan, Alhaji Yekeen Abass ti palaṣẹ fun gbogbo ọja lati wa ni titi pa, bẹrẹ lati ago meje aarọ wọ ago meji ọsan ọjọ iwuye naa.

Ọba Owolabi ni Ọba keji niluu Ibadan to paṣẹ lati ninu aafin tuntun ti ilu sẹsẹ kọ lẹyin Ọba Yesufu Oloyede Asanike, to jẹ Ọba akọkọ ti yoo gbe ni aafin to wa ni Ọja Ọba.

Ni ọjọ Kẹwaa, oṣu Keje ọdun 2024 ni Gomina Seyi Makinde ṣi aafin tuntun naa lẹyin tawọn atunṣe waye nibẹ.

Lonii. Ọba Owolabi yoo se bi awọn aṣaju rẹ se se nigba to ba lọ si agboole Oluwo Labosinde ni Ọja'ba niluu Ibadan, ni bi ti yoo ti se gbogbo etutu to yẹ ati lilọ si di Oosa Ọsẹ meji nibi ti wọn yoo ti gbe ade fun gẹgẹ bii Olubadan tuntun ko to di pe o gba ọpa aṣẹ lọwọ Gomina Seyi Makinde ni gbọngan Mapo.

Olubadan ilẹ̀ Ibadan, Ọba Owolabi Olakulehin wàjà lẹ́yìn ọdún kan gééré tó gorí ìtẹ́

Olubadan ti ilẹ Ibadan, Ọba Owolabi Olakulehin ti lọ darapọ mọ awọn babanla rẹ.

Ní òwúrọ̀ òní, ọjọ́ Keje, oṣù Keje ọdún 2025 ni Ọba Olakulehin darapọ̀ mọ́ àwọn babańlá rẹ̀.

Agbẹnusọ fun ẹbi Olubadan to waja naa lo sisọ loju isẹlẹ naa fun awọn akọroyin.

A gbọ pe ojojo ti n se Olubadan lati bii ọjọ melo kan, ko to tẹri gbasọ lẹni ọgọrin

Ọba Olakulehin dórí àpèrè àwọn babańlá láti igun Balogun Olubadan lẹ́yìn ìpapòdà Ọba Moshood Lekan Balogun, Alli Okunmade II, tó jáde láyé lọ́jọ́ Kẹrìnlá, oṣù Kẹta ọdún 2024 lẹ́ni ọdún mọ́kànlélọ́gọ́rin.

Tí ẹ bà gbàgbé, ọjọ́ Kejìlá, oṣù Keje, ọdún 2024 ni Ọba Olakulehin gba ọ̀pá àṣẹ tí gómìnà Seyi Makinde gbé fun ní gbọ̀gán Mapo ní Ibadan.

Ní ọjọ́ méjì sẹ́yìn ni Ọba Olakulehin ṣe ayẹyẹ ọjọ́ ìbí àádọ́rùn-ún ọdún lókè eèpẹ̀.

Ọba Owolabi Olakulehin

Oríṣun àwòrán, OYSG

Àkọlé àwòrán, Ọba Owolabi Olakulehin

Awọn ohun to yẹ ki o mọ nipa Oba Owolabi Olakuleyin to waja ree

Ọjọ karun un, oṣu Keje, ọdun ọdun 1935 ni wọn bi Kabiesi, orukọ abisọ rẹ si ni Akinloye Olalere Owolabi Olakulehin.

Baba rẹ ni Pa Ishola-Okin Owolabi, ti iya rẹ si jẹ Adunola Aweni Ope Ajilaran Omoyoade Owolabi.

Ibi ti wọn bi Ọba Olakulehin si ni abule Okugbaja, ni Ita Baale to wa ni agbegbe ijọba ibilẹ ariwa ila oorun Ibadan.

O bẹrẹ ẹkọ rẹ ni St James Primary School, ni Oke Akaran, ko to lọ si Islamic School, Odoiye, amọ ile ẹkọ St Peter Primary School, Aremo, niluu Ibadan lo ti pari.

Olubadan ṣiṣẹ gẹgẹ bii olukọ ile ẹkọ alakọbẹrẹ ni Wakajaiye, lagbegbe Akobo ko to tẹsiwaju ni Yaba Technical Institute.

Awọn ibi ti Olakulehin ti ṣiṣẹ

Lọdun 1959, Owolabi Olakulehin bẹrẹ iṣẹ nileeṣẹ to n ri si ọrọ iṣẹ, iyẹn Ministry of Works, Western Region Government niluu Ibadan gẹgẹ bii akọwe.

Lẹyin naa lo lọ kawe ni Yaba College of Technology nibi to ti gba oye OND ati HND nipa ile kikọ.

Lọdun 1970 lo darapọ mọ ileeṣẹ ọmọ ogun gẹgẹ bii 2nd Lieutenant.

Ileeṣẹ ọmọ ogun lo wa titi to fi gba oye Major, o ṣiṣẹ ni oniruru ẹka ileeṣẹ ọmọ ogun ko to fẹyinti lọjọ kinni, oṣu Kẹwaa, ọdun 1979.

Lẹyin to kuro nileeṣẹ ọmọ ogun, o da awọn ileeṣẹ aladani silẹ.

Lara awọn ileeṣẹ naa ni FAKOL Nigeria Ltd, Olakulehin Press, (ti wọn yipda si Solid Prints) ati FAKOL Bakery niluu Ibadan.

Owolabi Olakulehin darapọ mọ oṣelu, o si dije du ipo aṣojuṣofin, o si wọle labẹ asia ẹgbẹ oṣelu Social Democratic Party (SDP) lọdun 1992, nibi to ti ṣoju ẹkun idibo ila oorun Ibadan.

Irinajo Olakulehin si ipo Olubadan

Irinajo Ọba Olakulehin si itẹ Olubadan bẹrẹ lọdun 1983 lẹyin to jẹ oye Mogaji agbo ile rẹ.

Orukọ agbo ile naa ni idile Ige Olakulehin ni Ita-Baale Olugbode ti ilu Ibadan.

Ipo naa lo wa titi to fi de ipo Balogun ilẹ Ibadan, eyii to jẹ ọkan lara awọn oloye ti ipo wọn ga julọ nilẹ Ibadan.

Ọjọ kejila, oṣu Keje, ọdun 2024 lo gba ọpa aṣẹ Olubadan ilẹ Ibadan.

Ọjọ meji ṣeyin lo ṣe ayẹyẹ aadọrun ọdun rẹ loke eepẹ, o si n mura ayẹyẹ ọdun kan rẹ lori itẹ Olubadan ki ẹlẹmi to gba a.