Alaafin ni olórí ọba ní ìpínlẹ̀ Oyo, kìí ṣe ohun tó rújú rárá, òun náà ni yóò máà jẹ Alága ìgbìmọ̀ lọ́balọ́ba lọ - Ọba Owoade

Àkọlé fídíò, Alaafin ni olórí ọba ní ìpínlẹ̀ Oyo, kìí ṣe ohun tó rújú rárá, òun náà ni yóò máà jẹ Alága ìgbìmọ̀ lọ́balọ́ba lọ - Ọba Owoade
Alaafin ni olórí ọba ní ìpínlẹ̀ Oyo, kìí ṣe ohun tó rújú rárá, òun náà ni yóò máà jẹ Alága ìgbìmọ̀ lọ́balọ́ba lọ - Ọba Owoade

Lati igba ti Kabiyesi, Iku Baba Yeye, Alaafin tilu Oyo, Ọba Abimbola Akeem Owoade ti gori aleefa ni awọn ọrọ kan ti n waye eyi to n fa awuyewuye nipa rẹ.

Lara awọn awuyewuye naa ni bi ẹnu se n kun oun ati Ọọni tilu Ile Ife, Ọba Adeyeye Enitan Ogunwusi pe ko si irẹpọ laarin wọn.

Bakan naa, ni awuyewuye tun sọ lasiko ti Minisita fun ohun amusagbara nilẹ wa, Oloye Adebayo Adelabu na ọwọ lati bọ Alaafin lọwọ.

Igbesẹ naa si ni ọpọ eeyan ka si arifin nla nilẹ Yoruba.

BBC News Yoruba wa tọ Iku Baba yeye lọ nilu Oyo lati lọ se ago laafin, ki a si gbọ tẹnu wọn lori awọn awuyewuye yii ati lati mọ bi ori itẹ se ri.

Alaafin Abimbola Akeem Owoade joko lori itẹ, wọn de fila abetiaja, wọn wọ asọ funfun, fi ilẹkẹ pupa sọrun
Àkọlé àwòrán, Ọba Abimbola Akeem Owoade, Alaafin tilu Oyo

"N ko ba ẹnikan ja, ibi ti emi ati Kabiyesi Ọọnirisa ti dijọ rira ni Eko, a ki ara wa, ko si wahala kankan, awọn eeyan ni wọn maa n fẹ da rugudu silẹ"

Nigba to n ba BBC News Yoruba sọrọ lori aawọ tawọn eeyan n sọ pe o n waye laarin Alaafin ati Ọọnirisa, Ọba Owoade ni oun ko ba ẹnikẹni ja niti oun.

"Awọn akọroyin ori ayelujara yii, bi wọn yoo se pawo wọle ni wọn n wa.

Bi ẹ ba wo daadaa, awọn awuyewuye naa ko yọ awọn olorin silẹ, bi wọn se maa n ni Barrister ati Kollington n ja, ti ko si ri bẹẹ.

Iru awọn ọrọ yii ti wa tipẹ, kii se boya nnkan to sẹsẹ bẹrẹ ni, lati ọjọ to ti pẹ ni awọn eeyan ti maa n sọ.

Idi ti mo si ro pe o mu kawọn eeyan maa sọ̀rọ̀ yii ni pe wọn ri Alaafin ati Ọọni gẹgẹ bii agba ọba nilẹ Yoruba.

Tori bẹẹ ni wọn se n ro pe ija wa, awọn agbọyisọyi lo maa n wa nnkan ti wọn yoo gbe sori atẹgun.

Wọn ti gba pe ti wọn ba ti gbe iroyin naa sori atẹgun, wọn yoo fi pa owo.

Ni ti emi o, n ko ba ẹnikan lodi, n ko si ba ẹnikan ja. Gbogbo eeyan ni mo ba se ni temi.

Bi ẹ ko ba gbagbe, ibi ti emi ati Kabiyesi Ọọnirisa ti dijọ rira ni Eko, a ki ara wa, ko si wahala kankan.

Sugbọn awọn eeyan ni wọn maa n fẹ da rugudu silẹ lori boya eeyan kan lo ju ẹnikan lọ ati bẹẹ bẹẹ lọ"

Alaafin Oyo joko lori itẹ, o de ade sori, wọ asọ oke funfun ati alawọ ofeefee, o n bọ minisita fun ohun amusagbara, Oloye Bayo Adelabu lọwọ, ẹni to wọn asọ agbada ati sokoto alawọ buluu, to si de fila alawọ elese aluko.
Àkọlé àwòrán, Alaafin n bọ Bayo Adelabu lọwọ

"Emi ati Bayo Adelabu ko ni ija kankan, nigba ti mo n se ayẹyẹ iwuye, ti mo joko, ti wọn wa ki mi, emi ko tete mọ pe wọn n na ọwọ si mi lati bọ mi lọwọ nigba yẹn ni"

Nigba to n sọrọ lori awuyewuye to waye lori bi Oloye Adebayo Adelabu se na ọwọ lati bọ ọ lọwọ, Alaafin ni oun ko ni ija kankan pẹlu Minisita naa.

"Emi ati Adelabu ko ni ija kankan, mo si pe wọn ni ọsẹ bii meji sẹyin bayii nipa ọrọ ina ilu Oyo pe bawo ni wọn se fẹ ran wa lọwọ.

Wọn si seleri fun mi pe awọn yoo ba wa wa nnkan se si, ko to di pe asiko ti wọn yoo lo lori ipo Minisita yoo pe.

A ko ni ija kankan, amọ ni asiko ti mo n se ayẹyẹ iwuye, ti mo joko, ti wọn wa ki mi, emi ko tete mọ pe wọn n na ọwọ si mi lati bọ mi lọwọ nigba yẹn ni.

N ko ba ẹnikankan ja, mo fẹran wọn, awọn naa si fẹran mi, eeyan daadaa ni wọn, ko si igba ti mo ba pe wọn, ti wọn kii gbe ipe mi gẹgẹ bii ọba.

Eeyan daadaa ni Minisita, igba miran wa, ti awọn eeyan ko ba sunmọ eeyan, wọn ko le mọ bii eeyan se ri."

"Ki i se pe ki eeyan maa leju kiri lori ipo yii, amọ aimọye nnkan lo n lọ ti ko fi aaye gba ki eeyan maa boyin kiri ni gbogbo igba, ibi to ba yẹ ki a rẹrin, a rẹrin"

Ọpọ eeyan lo ti woye pe se ni oju Alaafin Owoade maa n le lọpọ igba, ti kii si rẹrin rara.

Nigba ti BBC News Yoruba wa beere pe ki lo de ti Kabiyesi se maa n leju kiri lọpọ igba, ọba Owode ni:

"Ipo yii naa, kii se pe ki eeyan maa leju kiri, aimọye nnkan lo n lọ ti ko fi aaye gba ki eeyan maa boyin kiri ni gbogbo igba.

Amọ ibi to ba yẹ ki a rẹrin, a rẹrin, ibi to ba ti yẹ ka joko, a joko, akoko to ba yẹ ka se nnkan, la maa se e tori gbogbo nnkan lo ni akoko tiẹ.

Ẹ ba mi sọ fawọn eeyan pe Alaafin o, eeyan daada ni wọn, ọtọ ni bi awọn eeyan se n ro, ọtọ ni bi mo se ri gẹgẹ bi ẹyin naa se ri.

Gbogbo ẹni to ba fẹ ri Alaafin, aaye wa, a si gba wọn tọwọ tẹsẹ.

Alaafin Abimbola Akeem Owoade joko lori itẹ, wọn de fila abetiaja, wọn wọ asọ funfun, fi ilẹkẹ pupa sọrun.
Àkọlé àwòrán, Ọba Abimbola Akeem Owoade, Alaafin tilu Oyo

"Alaafin lo yẹ ko maa jẹ olori nipinlẹ Oyo, kii se nnkan to ruju fun gbogbo mutumuwa"

Alaafin Abimbola Owoade tun sọrọ lori ọrọ igbimọ lọbalọba ipinlẹ Oyo ti aawọ wa lori rẹ, ti wọn ko si se ipade lati bii ọdun mẹwa sẹyin.

Bi ẹ ko ba gbagbe, aawọ iwọ ko ju mi, emi ko ju ọ lo waye laarin Alaafin ana, Ọba Lamidi Adeyemi ati awọn oriade miran nipinlẹ Oyo, lori pe wọn gbọdọ maa yi ipo alaga igbimọ lọbalọba naa laarin Alaafin, Olubadan ati Soun.

O si ti le ni ọdun mẹwa ti aawọ naa ni ti wa nilẹ lai ni ojutu rara titi di akoko yii.

Lero tiẹ, Alaafin Owoade ni:

"Lootọ ni ipenija n waye lati ọdun 2011 ninu igbimọ lọbalọba ipinlẹ Oyo, eyi to da lori pe ki Alaafin, Soun ati Olubadan maa gba ipo naa mọ ara wọn lọwọ fun saa kọọkan.

Ohun ti mo mọ ni pe Alaafin ana, Ọba Lamidi Adeyemi to ti di Oloogbe, ko fara mọ igbesẹ naa, eyi si wa lara awọn nnkan ti igbimọ naa ko fi gun rege di ọjọ oni.

Pẹlu gbogbo nnkan ti mo ti ri ati eyi ti mo ti gbọ lọtun-losi, Alaafin ko se ri fin tori agba ọba ni.

Alaafin lo yẹ ko maa jẹ olori nipinlẹ Oyo, ti mo si mọ pe kii se nnkan to ruju fun gbogbo mutumuwa.

Sugbọn awọn nnkan le maa sẹlẹ, ti awa ko mọ amọ mo lero, ti mo si gba a ni adura pe Alaafin naa ni yoo maa jẹ Alaga igbimọ lọbalọba lọ."