Aláàfin Owoade kéde kókó ohun tí yóò ṣe lórí ìtẹ́

Oríṣun àwòrán, Akeem Owoade
Alaafin Ọyọ tuntun, Oba Akeem Abimbola Owoade ti fi ọrọ lede nipa awọn afojusun rẹ lori aleefa.
Atẹjade kan ti Bode Durojaiye, tii se adari ikede ati ipolongo fun Ọba Owoade, fisita fawọn akọroyin lo sisọ loju ọrọ yii.
Ọba Owoade ni ọkan pataki lara awọn akanṣe iṣẹ ti oun yoo ṣe lori itẹ ni lati ri daju pe awọn ọdọ to n fi ẹsẹ gbalẹ kiri, lẹyin ti wọn ti kẹkọọ jade lai ri iṣẹ, yoo kuro ni ẹgbẹ alaini iṣẹ.
Bakan naa ni Kabiyesi fi kun ọrọ rẹ wi pe, oun yoo ṣe agbekalẹ idanilẹkọ nipa iṣẹ ọwọ fun awọn ọdọ.
"Ma ri pe awọn nnkan iṣẹmbaye ilu Ọyọ ti wọn ti ko lọ si ilẹ Gẹẹsi lọdun 1895, ni yoo pada pẹlu owo gọbọi"
Alaafin fi idi rẹ mulẹ wi pe, awọn akẹkọọjade kan ti wọn ti kẹkọọ gboye 'Bsc tabi HND' yoo ri iranlọwọ gba lati kọ nipa aabo ori itakun ayelujara, 'Cyber Security', ki wọn le ni anfani lati lọ ṣiṣẹ ni oke okun.
Alaafin Owoade fi kun ọrọ rẹ wi pe, oun yoo tẹsiwaju ni ibi ti Alaafin ana, Oba Adeyemi ti ṣiwọ iṣẹ, fun idagbasoke ọdun Ṣango ati Ọranmiyan.
Bakan naa ni atẹjade naa tọka si pe awọn opo yoo ri iranlọwọ gba fun igbeaye irọrun.
Idagbasoke eto ilera ilu Ọyọ naa ko gbẹyin gẹgẹ bi Ọba alade naa ṣe n gbero lati ke si awọn ẹlẹyinju aanu lati oke okun lati ṣe atilẹyin fun ijọba rẹ.
Ọba Owoade yoo tun riidaju wi pe gbogbo awọn nnkan iṣẹmbaye ilu Ọyọ ti wọn ti ko lọ si ilẹ Gẹẹsi lati ọdun 1895 ni yoo di dida pada.
O fikun pe awọn ohun isembaye naa yoo pada pẹlu ere owo gẹgẹ bi o ṣe n ṣe ileri lati bẹ awọn agbekalẹ ohun atijọ wo.















