Ìjọba ìpínlẹ̀ Oyo kéde Ọmọọba Abimbọla Akeem Owoade gẹ́gẹ́bi Alaafin Oyo tuntun

Oríṣun àwòrán, Prince Abimbola Akeem Owoade/ facebook
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 1
Gomina ipinlẹ Ọyọ, Seyi Makinde ti buwọlu orukọ Ọmọọba Abimbọla Akeem Owoade gẹgẹbi Alaafin tuntun fun ilu Ọyọ.
Atẹjade kan ti Kọmiṣọna fun eto iroyin ni ipinlẹ Ọyọ buwọlu ṣalaye pe , ijọba buwọlu orukọ Ọmọọba Owoade lẹyin ti awọn Ọyọmesi fa orukọ rẹ kalẹ lẹyin igbesẹ iwadii gbogbo lọna iṣẹmbaye.
Ijọba ipinlẹ Ọyọ ni ikede yii ti fopin gbogbo gulegule to n waye to fi mọ ọrọ ofin nihin-lọhun to n kaakiri lati igba ti Alaafin Ọyọ Ọba Lamidi Ọlayiwọla Adeyẹmi kẹta ti waja.
Ọjọ kejilelogun oṣu kẹrin ọdun 2022 ni Alaafin ana, Ọba Lamidi Ọlayiwọla Adeyẹmi kẹta waja lẹyin ọdun mejilelaadọta lori itẹ








