Ìṣesí wọn nílé aṣòfin àgbà dà bí tilé ẹgbẹ́ awo - Natasha Akpoti

Àkọlé fídíò, Ìṣesí wọn nílé aṣòfin àgbà dà bí ilé ẹgbẹ́ awo - Natasha Akpoti
Ìṣesí wọn nílé aṣòfin àgbà dà bí tilé ẹgbẹ́ awo - Natasha Akpoti

Senator Natasha Akpoti-Uduaghan to n soju ẹkun idibo aarin gbungbun Kogi ti sapejuwe ile asofin agba ilẹ wa, gẹgẹ bii ile ẹgbẹ okunkun.

Natasha sapejuwe ile asofin agba bẹẹ lasiko to n ba BBC sọrọ lori awọn idojukọ rẹ nile asofin agba.

Asofin agba naa ni looto ni oun ni iriri iwa ifibalopọ lọ ni lati ọdọ aarẹ ile asofin agba, Godswill Akpabio amọ to n sẹ lori awọn ẹsun naa.

Natasha Akpoti-Uduaghan

O salaye pe ẹru lo n ba ọpọ asofin, ti wọn fi le sọ ero ọkan wọn to ba tako ti awọn asofin kan nitori ki wọn ma ba gbẹsan lara wọn.

Bi ẹ ko ba gbagbe, ile asofin agba ti ni ki Asofin Natasha lọ rọọkun nile na fun osu mẹfa lẹyin to gbe iwe ẹsun kalẹ pe aarẹ ile n fi ibalopọ lọ oun.