Natasha lulẹ̀ níwájú ìgbìmọ́ aṣòfin, wọ́n da ẹ̀sùn ìyọlẹ́nu fún ìbálòpọ̀ tó fi kan Akpabio nù

Natasha Akpoti-Uduaghan àti Godswill Akpabio

Oríṣun àwòrán, Natasha Akpoti-Uduaghan/Godswill Akpabio/Facebook

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 6

Níṣe ni ìfaǹfà tó ń wáyé láàárín Sẹ́nétọ̀ Natasha Akpoti-Uduaghan tó ń ṣojú ẹkùn ààrin gbùngbùn ìpínlẹ̀ Kogi ní ilé aṣòfin àgbà, Abuja àti olórí ilé náà, Godswill Akpabio tún gba ọ̀nà mìíràn yọ lọ́jọ́rú.

Ìgbìmọ̀ tó ń rí sí ìwà ọmọlúàbí ní ilé aṣòfin náà, da ẹjọ́ ti Natasha pè tako Akpabio, níwájú ìgbìmọ̀ ilé náà nù lọ́jọ́rú bí wọ́n ṣe ní ẹ̀sùn tó pè tako Akpabio kò lẹ́sẹ̀ nílẹ̀.

Alága ìgbìmọ̀ tó ń gbọ́ ẹjọ́ náà, Sẹ́nétọ̀ Neda Imasuen sọ pé Natasha lòdì sí abala ogójì òfin tó de ilé aṣòfin náà bí ó ṣe buwọ́lu ìwé ẹ̀sùn tó fi pé Akpabio lẹ́jọ́.

Imasuen níbi ìjókòó tó wáy['e nílé ìgbìmọ̀ aṣòfin náà lọ́jọ́rú sọ pé kò yẹ kí Natasha buwọ́lu ìwé ẹ̀sùn náà fúnra rẹ̀, ó ní ó yẹ kó gbe fún ẹlòmíràn láti bá a buwọ́lù ú ni.

Bákan náà ló ní àwọn ẹ̀sùn tó wà nínú ìwé ìpẹ́jọ́ tí Natasha gbé síwájú ilé ẹjọ́ ló ti wà nílé ẹjọ́, tí àwọn kò sì lè máa sọ̀rọ̀ lórí rẹ̀ mọ́.

Ìjókòó ìgbìmọ̀ tó gbọ́ ẹ̀sùn náà ló wáyé lọ́sàn-án ọjọ́rú àmọ́ Natasha kọ̀ láti yọjú síbi ìjòkòó ọ̀hún.

Natasha gbé ìwé ẹ̀sùn síwájú ilé aṣòfin tako Akpabio

Ṣáájú ni Natasha ti ṣàgbékalẹ̀ ìwé ẹ̀sùn níwájú ìjókòó ilé níbi tó ti kọ ọ́ síbẹ̀ pé olórí ilé aṣòfin náà, Godswill Akpabio gbìyànjú láti ṣe aṣemáṣe pẹ̀lú òun.

Natasha gbé ìwé ẹ̀sùn náà síwájú ilé ṣòfi kí wọ́n ba à le ṣe ìwádìí nípa àwọn ẹ̀sùn tó fi kan Akpabio.

Lára àwọn ẹ̀sùn tó fi kan Akpabio ni àṣìlò agbára àti pé kò jẹ́ kí òun ṣe iṣẹ́ òun gẹ́gẹ́ bí aṣòfin bó ṣe tọ́.

Ó ní òun ti ṣetán láti fa ara òun kalẹ̀ fún ìwádìí lórí àwọn ẹ̀sùn náà,k tó sì lọ gbé ìwé ẹ̀sùn rẹ̀ kalẹ̀ níwájú ilé.

Lẹ́yìn náà ni ààrẹ ilé aṣòfin, Godswill Akpabio darí rẹ̀ pé kí wọ́n fi ìwé ẹ̀sùn náà ránṣẹ́ sí ìgbìmọ̀ tó ń rí sí ọ̀rọ̀ náà.

Mi ò ṣe aṣemáṣe pẹ̀lú obìnrin kankan rí - Akpabio

Àmọ́ níbi ìjòkòó àpapọ̀ ilé náà ni Akpabio ti jìyàn ẹ̀sùn náà pé òu kò ṣe ohun tí Natasha ń fi ẹ̀sùn rẹ̀ kan òun.

Ó ní òun kò fi ìgbà kankan nawọ́ ìbálòpọ̀ sí obìnrin kankan rí lọ́nà àìtọ́ nítorí ìyá òun, tó dá àwọn tọ́, tọ́ àwọn láti máa bọ̀wọ̀ fún obìnrin.

Akpabio ní bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀rọ̀ náà ti wà nílé ẹjọ́, tí òun kò sì fẹ́ sọ̀rọ̀ púpọ̀ lórí rẹ̀, ó ní ó pọn dandan fún òun láti wẹ ara òun mọ́ lórí ẹ̀sùn náà.

Ó fi kun ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé ọmọbìnrin mẹ́rin ni òun bí, tí òun kò sì ní fi ọwọ́ yẹpẹrẹ mu ẹnikẹ́ni tó bá ṣe aṣemáṣe pẹ̀lú wọn.

Bákan náà ló rọ àwọn ọmọ Nàìjíríà láti ṣe sùúrù tí ilé ẹjọ́ máa fi gbé ìdájọ́ kalẹ̀ lórí ẹ̀sùn náà, kí wọ́n yé ṣe ìdájọ́ lọ́wọ́ ara wọn.

Àwọn olùwọ́de Natasha àti Akpabio kọjú oro síra l‘Abuja, Ọlọ́pàá di Olùlàjà pẹ̀lú afẹ́fẹ́ tajútajú

Awọn oluwọde ni Abuja

Se ni ariwo sọ nile asofin apapọilẹ wa to wa nilu Abuja ni owurọ Ọjọru, bi awọn oluwọde kan se ya bo ile asofin naa.

Awọn olufẹhonuhan naa lo pin si igun meji, ti igun kan si n se atilẹyin fun asofin Natasha Akpoti-Uduaghan, ti wọn si n beere pe ki aarẹ ile asofin agba kọwe fipo rẹ silẹ.

Igun keji si lo n satilẹyin fun aarẹ ile asofin agba, Godswill Akpabio, ti wọn si ni ko ni kuro lori aga to wa tabi nile asofin agba naa.

Isẹlẹ yii si lo mu ki ile igbimọ asofin agba naa lọ fun isinmi ranpẹ tori iwọde naa.

Awọn oluwọde

"Akpabio, ki ni Natasha fi se ọ, ti ile asofin agba fi n dọdẹ rẹ, tete fi asofin naa silẹ tabi ki iwọ gan kọwe fi ipo silẹ"

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Awọn olufẹhonuhan ọhun lo duro si ile igbimọ asofin to wa niluu Abuja, ti wọn si n kọ orin ọkan-o jọkan lati fi da ara wọn laraya.

Bakan naa ni wọn n pariwo pe ki Godswill Akpabio fi ipo rẹ silẹ gẹgẹ bi adari ile igbimọ asofin.

Awọn olufẹhonuhan ti wọn n se atilẹyin fun aṣofin Natasha Akpoti-Uduaghan naa lo wa lati aarin gbungbun ipinlẹ (Kogi Central Senatorial District).

Arakunrin Tosin Adekanbi, tii se ọkan lara awọn oluwọde ọhun ni awọn wa lati wa fẹhonuhan nipa bi ile igbimọ asofin agba se da Natasha duro o ni.

"Gbogbo awọn eniyan to wa nibi yii wa lati ipinlẹ Kogi, lati wa satilẹyin fun asofin Natasha , ki ile igbimo asofin agba si da Natasha pada si ipo rẹ".

Bakan naa, iyaafin Adebọla, to je ẹya Ebira lati ipinlẹ Kogi naa ni "ki ni Natasha fi se Akpabio ati pe ki Akpabio fi Natasha silẹ tabi ko fi ipo rẹ silẹ,.

A wa ko fẹ Akpabio mọ, ẹya Ebira kii fa wahala, ki i se dandan ki ọkunrin fẹ obinrin.

Laisi obinrin , ko si okunrin".

Awọn oluwọde

"Irọ lasanlasan ni Natasha n pa mọ Akpabio, aarẹ ile asofin agba ko ni kọwe fi ipo rẹ silẹ"

Ko pẹ pupọ ti awọn ẹya Ebira lati ipinlẹ Kogi de fun iwọde wọn, ni awọn ikọ miran tun wa lati wa se atilẹyin fun adari ile igbimọ asofin agba, Godswill Akpabio.

Igun oluwọde keji yii ni pe irọ patapata ni ẹsun ti asofin Natasha Akpoti-Uduaghan fi kan Akpabio eyi to da lori iyọnilẹnu fun ibalopọ.

Lara awọn to n se atilẹyin fun asofin Akpabio naa sọ pe irọ lasanlasan ni Natasha n pa mọ Akpabio, aarẹ ile asofin agba naa ko si ni kọwe fi ipo rẹ silẹ.

Ariyanjiyan yii lo da wahala silẹ laarin ikọ mejeeji, ti wọn si gboju agan si ara wọn, ko to di pe ikọ awọn ọlọpaa fi afẹfẹ gaasi taju-taju tu wọn ka.

Bẹẹ ba gbagbe, ni ọjọ Jimọ to kọja, aṣofin Natasha Akpoti lati ipinlẹ Kogi, lo fẹsun kan aarẹ ile asofin agba, Godswill Akpabio pe o n yọ oun lẹnu fun ibalopọ.

Bakan naa lo ni Akpabio n tabuku oun ni gbogbo igba nitori pe oun kọ awọn ọwọ ibalopọ to n na si oun.