Ó ṣeéṣe kí ìdajì àwọn èèyàn tó wà láyé sanra àsanjù tó bá fi máa di ọdún 2050

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ó ṣeéṣe kí ìdajì àwọn èèyàn tó ti dàgbà sanra àsanjù nígbà tí yóò fi di ọdún 2050.
Bẹ́ẹ̀ náà ni ìdá kan nínú ìdá mẹ́ta àwọn ọmọdé yóò tún sanra àsanjù lásìkò náà.
Èyí ló ń jẹyọ nínú ìjábọ̀ kan tí àjọ The Lancet ṣẹ̀ṣẹ̀ gbé jáde lórí ìwádìí tí wọ́n ṣe ní àwọn orílẹ̀ èdè tó lé ní igba.
Àwọn olùwádìí ti ṣèkìlọ̀ pé bí àwọn àwọn èèyàn yóò ṣe máa sanra yóò lékún láàárín ọdún mẹ́wàá sí àsìkò pàápàá ní àwọn orílẹ̀ èdè tí kò ì tíì gòkè àgbà.
Àmọ́ àwọn onímọ̀ sọ pé tí ìjọba bá tètè gbé ìgbésẹ̀ tó yẹ láti dènà rẹ̀.
Ní ọdún 2021, ìdajì àwọn ènìyàn tó wà ní àgbáyé, bílíọ̀nù kan àwọn ọkùnrin àti bílíọ̀nù kan lé díẹ̀ àwọn obìnrin tó ti lé ní ọdún márùndínlọ́gbọ̀n ló tóbi ju bó ṣe yẹ lọ.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Iye àwọn èèyàn tó ní àìsàn ara àsanjù ní ọdún 1990 ló ti lékún ní ìlọ́po méjì.
Tí èyí bá ń tẹ̀síwájú, ó túmọ̀ sí pé iye èèyàn tó ní àìsàn ìtọ̀ ṣúgà máa lékún di 57.4% fáwọn ọkùnrin àti ìdá 60.3% fáwọn obìnrin nígbà tó bá máa fi di ọdún 2050.
Ìwádìí náà sọ pé China, India àti orílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà ni àwọn èèyàn tó sanra àsanjù máa pọ̀ sí jùlọ lọ́dún 2050.
Ẹ̀wẹ̀, àwọn olùwádìí náà sọ pé àwọn èèyàn tó lé ní mílíọ̀nù 522 yóò sanra àsanjù ní ẹkùn Sub-Saharan Africa.
Wọ́n ní èèyàn tó máa sanra àsanjù ní Nàìjíríà máa lékún ní ìlọpo mẹ́ta láti mílíọ̀nù 36.6 tó wà lọ́dún 2021 di mílíọ̀nù 141 lọ́dún 2050.
Nàìjíríà ló máa wà ní ipò kẹrin àwọn orílẹ̀ èdè tó ní èèyàn tó sanra àsanjù ní àgbáyé.
Ìwádìí náà ṣàlàyé pé àwọn kò ṣe ìwádìí lórí àwọn okùnfà táwọn oògùn tó lè mú àdínkù bá ara sísan àsanjù le fà, tó lè ní ipa lọ́jọ́ iwájú.
Àwọn onímọ̀ sọ pé tí ìjọba bá tètè gbé ìgbésẹ̀ tó yẹ, àwọn tó ṣeéṣe kó sanra àsanjù le rí ààbò tó péye.
Ọ̀jọ̀gbọ́n Emmanuela Gakidou tí ẹ̀ka Institute for Health Metrics and Evaluation (IHME) ní ilé ẹ̀kọ́ gíga fásitì University of Washington ní America ló ṣáájú ìwádìí náà.
Emmanuela Gakidou ní àwọn ìjọba ní orílẹ̀ èdè kọ̀ọ̀kan le ṣàmúlò ìwádìí tó wà fún orílẹ̀ èdè wọn láti dènà rẹ̀ kíákíá.
Bí àwọn èèyàn ṣe ń sanra àsanjù ni ó ń lékún pàápàá láàárín àwọn ọmọdé.
Tó bá máa fi di ọdún 2050, ọ̀kan nínú àwọn ọmọdé mẹ́ta ni yóò sanra àsanjù.
Àwọn olùwádìí náà ní ìjọba nílò láti tètè bẹ̀rẹ̀ ìgbésẹ̀ tó yẹ láti mú àdínkù bá àwọn àìlera tó lè tara ara sísan àsanjù jáde.















