Wo èèwọ̀ kékèké tí o kò mọ̀ pé ó le ba Ramadan jẹ́

Awọn musulumi
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Awọn nnkan kan wa tawọn eeyan ko ro pe o le ba aawẹ jẹ ṣugbọn to jẹ eewọ ni wọn, ti wọn si le jẹ ki aawẹ eeyan mase jẹ itẹwọgba lọdọ Oluwa.

Bakan naa ni awọn nnkan miran wa tawọn eeyan ro pe o le ba aawẹ jẹ, ṣugbọn to jẹ wọn ko ṣe akoba kankan fun aawẹ.

Lati mọ awọn nnkan wọnyi yatọ yekeyeke ni BBC ṣe ba Sheikh Aminu Ibrahim Daurawa, sọrọ.

Aafaa onimọ nipa ẹsin Islam ni ọkunrin naa nipinlẹ Kano.

Gẹgẹ bi Sheikh Daurawa ṣe ṣalaye, ohun ti a n pe ni aawẹ Ramadan ni ki eeyan ma jẹun, mu, ki eeyan yago fun ibalopọ ati bẹẹ bẹẹ lọ, ki oorun to yọ laaarọ titi digba ti oorun ba wọ lọwọ aṣalẹ.

Ohun méje tó lè ba ààwẹ̀ jẹ́:

  • Bi o ba mọ ọ mọ jẹun ninu aawẹ, aawẹ rẹ ti já
  • Bi obinrin ti kii se aya rẹ ba se ounjẹ saari tabi isinu fun ọ
  • Bi o ba mọ ọ mọ mu omi
  • Bi o ba ni ibalopọ
  • Bi obinrin ba ri nnkan alejo rẹ
  • Bi o ko ba ni aniyan lati gba aawẹ
  • Bi ọkunrin ba da omira si ara

Sheikh Aminu Daurawa ṣalaye nipa dida nnkan sara.

O ni awọn nnkan mẹrin lo le fa ki eeyan da nnkan sara bẹẹ.

Awọn nnkan naa ni:

Ohun to le mu ki ọkunrin da omira:

  • Bi o ba fi ẹnu ko ololufẹ rẹ lẹnu
  • Bi o ba di mọ ọ papakoko nilana ifẹ
  • Bi o ba gbiyanju lati jẹ ki nnkan jade laraa rẹ
  • Bi o ba n ro ero naa laroju lai mu ọkan kuro, titi ri ara rẹ fi dide ti nnkan si jade.

Ǹjẹ́ ìjìya tàbí ìtanràn wà fún ààwẹ̀ tó já?

Bi aawẹ rẹ ba ja funra rẹ latari awọn idi ti o ko lagbara le lori, o ko ni ijiya kankan gẹgẹ bi Sheikh Daurawa ṣe ṣalaye.

O ni ohun ti eeyan yoo kan ṣe ni lati gba aawẹ naa pada lẹyin ti idiwọ naa ba lọ.

Apẹẹrẹ eyi ni bi nnkan alejo obinrin ba de lojiji lasiko to n gba aawẹ lọwọ.

To ba jẹ pe o gbagbe pe o n gba aawẹ ti o si mu omi tabi jẹun, dawọ ounjẹ abi mimu naa duro bi o ba ṣe ranti ki o si maa ba aawẹ rẹ lọ.

Iru aawẹ bayii ko nilo pe eeyan n san an pada.

O ni ẹni to ba mọ ọ mọ jẹun tabi ṣe ohun ti yoo ba aawẹ rẹ jẹ ni yoo tanran rẹ pada.