Ariwo sọ bí ìpínlẹ̀ mẹ́rin lókè ọya ṣe ti ilé ẹ̀kọ́ pa f‘óṣù kan torí ààwẹ̀ Ramadan, CAN fọnmú

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ọpọ eeyan, awọn ẹlẹgbẹjẹgbẹ atawọn lajọlajọ nilẹ Naijiria lo ti n koro oju si bi awọn ijọba ipinlẹ mẹrin to n samulo ofin Sharia, se gbe awọn ilẹkun ile ẹkọ wọn ti pa fun osu kan gbako.
Atẹjade tawọn ipinlẹ ọhun fisita salaye pe asẹ naa ko yọ awọn ile ẹkọ aladani ati ti ijọba silẹ, gbogbo awọn akẹkọọ wọn ni ko lọ fidi mọle.
Alaye awọn ijọba ipinlẹ ti ọrọ yii kan ni isinmi olosu kan naa yoo fawọn akẹkọọ ọhun ni anfaani lati gba aawọ Ramadan.
Awọn ipinlẹ mẹrẹẹrin naa, ti wọn n lo ofin Sharia ni apa ẹkun ariwa Naijiria, ti ọrọ naa kan ni ipinlẹ Katsina, Kebbi, Kano ati Bauchi.
Ori ayelujara si lo ti n gbona lori bawọn eeyan se n gbarata lori isẹlẹ yii ati ipa ti yoo ni lori eto ẹkọ awọn akẹkọ ti ọrọ naa kan.

Oríṣun àwòrán, Katsina State Hisbah Board
Awọn orilẹede ẹlẹsin Islam lagbaye bii Saudi Arabia ati United Arab Emirates ki i ti ile ẹkọ pa titi ti wọn yoo fi gba aawẹ tan - CAN
Nigba ti wọn n fesi lori igbesẹ awọn ipinlẹ mẹrẹẹrin ọhun lati gbe ilẹkun ile ẹkọ ti pa fun odidi osu kan tori aawẹ Ramadan, ajọ agbarijọpọ ẹgbẹ awọn ọmọlẹyin Kristi, CAN koro oju si bi igbesẹ naa.
Ninu atẹjade kan ti wọn fi sita lọjọ Aiku ni Aarẹ CAN, Bisọbu agba Daniel Okoh ti ṣapejuwe igbesẹ naa bii iwa aitọ si awọn akẹkọọ ti ki i ṣe Musulumi.
Aarẹ CAN sọ pe o buru jai bi awọn kan ṣe deede gbe ipinnu yii kalẹ lai ro ti awọn akẹkọọ ti wọn ki i ṣe ẹlẹsin Islam.
"Ọrọ yii ka ẹgbẹ CAN laya gan-an bi ijọba ipinlẹ Bauchi, Katsina, Kano, ati Kebbi ṣe fi dandan le e pe ki wọn ti awọn ile ẹkọ ijọba ati ti aladaani pa fun ọsẹ marun-un gbako lati fi gba aawẹ Ramadan.
"Ẹtọ ni iwe kika jẹ, oun si ni àtẹ̀gùn ilọsiwaju. Bi wọn ṣe ti ileewe pa yii ti da eto ẹkọ duro, o si le ṣakoba fun ilọsiwaju ọpọlọpọ akẹkọọ.
"Kẹ ẹ si maa wo awọn ipinlẹ yii, awọn ọmọ ti ko ri ileewe lọ mọ nibẹ ti to ida mẹrinlelogoji (44%) tẹlẹ.
Wọn ko ba awọn aṣoju CAN sọrọ lawọn ipinlẹ yii ti wọn fi gbe igbesẹ titi ileewe pa.
"Awọn orilẹede ẹlẹsin Islam lagbaye bii Saudi Arabia ati United Arab Emirates ki i ti ileewe pa titi ti wọn yoo fi gba aawẹ tan.
Wọn maa n fi eto si ohun ti wọn fẹẹ ṣe ni lai fi ẹsin pa iwe kika lara.
"A n pe Gomina Bala Mohammed, Dikko Umar Radda, Abba Kabir Yusuf, ati Nasir Idris lati ba awọn alẹnulọrọ lori ọrọ yii sọrọ.
"A n pe awọn olori ẹlẹsin, awọn to kọ́ ileewe, awọn obi ati ẹgbẹ awujọ kiri lati dide si ọrọ yii, ki wọn si wa atunṣe to yẹ si i."
Bẹẹ ni apa kan atẹjade CAN ka.
Iléèwé tí wọ́n tì pa nítorí Ramadan túmọ̀ sí pé òfin Sharia kò yọ àwọn tí kì í ṣe Mùsùlùmí sílẹ̀- MBF
Ninu ẹdun ọkan ẹgbẹ awọn eeyan to wa ni aarin gbungbun ẹkun ariwa ilẹ Naijria, Middle Belt Forum, (MBF), Agbẹnusọ apapọ wọn, Luka Binniyat, sọ ni Kaduna pe bi wọn ṣe ti ileewe pa nitori Ramadan tumọ si pe ofin Sharia ko yọ awọn ti ki i ṣe Musulumi silẹ.
" Ko tọna rara pe awọn akẹkọọ ti ki i ṣe Musulumi yoo fa sẹyin ninu ẹkọ wọn nitori pe awọn Musulumi fẹẹ ṣe ti wọn."
Binniyat lo sọ bẹẹ.
Ẹgbẹ MBF fi ohun to n ṣẹlẹ yii we bi awọn Boko HARAM ṣe lodi si iwe kika, wọn ni kawọn ọmọ Naijiria ma fi ọwọ yẹpẹrẹ mu ohun to n ṣẹlẹ yii rara.
MBF rọ Aarẹ Bola Tinubu lati da si ọrọ yii, ki wọn si gba awọn ipinlẹ to kan lọwọ akatakiti ẹsin.














