Ìwádìí BBC rèé lórí bí ojú òpó TikTok ṣe ń fi ìhòhò àwọn ọmọdé pawó

Àkọlé fídíò,
    • Author, Nalini Sivathasan, Patrick Clahane & Debula Kemoli
    • Role, BBC News Investigations & Africa Eye
  • Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 9
Ẹnikan to mọ nipa iwa yii lo n fi ohun to n ṣẹlẹ han akọroyin BBC ninu aworan yii.

Iroyin to tẹ BBC lọwọ bayii ni pe oju opo ayelujara TikTok ti bẹrẹ si i fi ihoho awọn ọmọde ti ọjọ ori wọn ko ju mẹẹẹdogun lọ pawo.

A ba awọn obinrin mẹta sọrọ lorilẹede Kenya, wọn si fidi ẹ mulẹ fun wa pe awọn ti bẹrẹ si i fi ihoho awọn han loju opo naa nigba ti ọjọ ori awọn ṣi wa laaarin ọdun mẹẹẹdogun si mọkandinlogun.

Awọn obinrin naa ṣalaye pe awọn n lo oju opo TikTok lati polowo ihoho awọn, nibẹ lawọn yoo si ti ri awọn to nifẹẹ si ihoho ọ̀hún, ti awọn yoo jọ sọrọ nipa iye ti ẹni naa yoo san, lẹyin eyi lawọn yoo bẹrẹ si i fi atẹjiṣẹ ranṣẹ si ara awọn loju opo ayelujara mi-in.

Ohun ti BBC gbọ ni pe, TikTok mọ pe eyi n ṣẹlẹ, ati pe ida aadọrin owo (70%) lo n lọ sọdọ TikTok ninu awọn okoowo bi eyi, lasiko to ba waye nibẹ.

Ṣugbọn ninu alaye ti TikTok ṣe fun BBC, oju opo yii sọ pe oun ko faaye gba iyanjẹ bẹẹ rara.

Ki wọn maa fi aworan han bo ṣe n ṣẹlẹ wọpọ lorilẹede Kenya, o si gbilẹ nibẹ gan-an.

Ni alaalẹ laaarin ọsẹ kan, iwadii wa fi han pe o maa n to obinrin mejila ti wọn yoo maa jo ijo oge, ẹgbẹlẹgbẹ eeyan lo si n wo wọn kaakiri agbaye.

Ikilọ: Awọn nnkan to ni i ṣe pẹlu ibalopọ wa ninu àyọka yii.

Aworan awọn obinrin to n jo ijo oge nikọọkan loju opo TikTok, eyi to n jade bi wọn ṣe n jo o lọwọ (livestream), pẹlu awọn to n wo wọn. (A bo oju wọn ka le fi aṣiri naa bo) .
Àkọlé àwòrán, Aworan awọn obinrin to n jo ijo oge nikọọkan loju opo TikTok, eyi to n jade bi wọn ṣe n jo o lọwọ (livestream), pẹlu awọn to n wo wọn. (A bo oju wọn ka le fi aṣiri naa bo)

Bó ṣe ń lọ ní Nairobi, Kenya

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Aago meji oru lo lu ni Nairobi, oju opo TikTok ibẹ si ti bẹrẹ iṣẹ ni pẹrẹwu.

Orin faaji si n ja too loju opo naa, awọn to n ba ara wọn dọrẹ loju opo naa si wa nibẹ biba.

Bẹẹ lobinrin kan ṣi oju kamẹra ẹ si ojuu gbogbo aye, o si bẹrẹ si i redi, o n yi sibi-sọhun lọna to le fa ọkunrin mọra.

Lẹyin eyi ni wọn yoo gbe awọn ami kan jade.

"Ẹyin eeyan, ẹ ba mi sọrọ ''Tap, tap," awọn onijo aramọnda naa lo n kede bẹẹ pẹlu lilo ede ti a mọ si Tap to wọpọ loju opo TikTok.

Ede yii ni wọn fi maa n pe awọn onibaara ti yoo wo ihoho wọn loju opo naa lati maa ba wọn ka lọ.

"Bakan naa ni awọn obinrin yii maa n lo ede kan ti a mọ si ''Kinembe", idọ oju abẹ obinrin ni wọn n pe bẹẹ ni Swahili.

Bi wọn ṣe n sọ pe ki onibaara ba awọn sọrọ labẹnu, naa ni awọn iwa bii ki eeyan maa ki ọwọ bọ oju ara rẹ, ko maa ba ara rẹ ṣere bii ẹni ti wọn n ba lo pọ wa loju opo yii.

Bakan naa, asa bibọ ara wọn sihooho ni wọn yoo maa fi han loju opo fun ẹni naa.

"Ki i ṣe pe o wu TikTok lati maa ran ibalopọ lọwọ.

Bawọn eeyan ba ṣe n fun ara wọn ni nnkan si loju opo naa, bẹẹ ni yoo ṣe maa pawo wọle fun TikTok."

Olootu eto tẹlẹ kan ni Kenya, ti wọn pe orukọ ẹ ni Jo lo sọ bẹẹ, ọkan lara awọn ẹgbẹrun lọna ogoji olootu eto ti wọn ni TitkTok gba lagbaaye ni.

Ṣé lóòótọ́ ni TikTok ń gba ida aadọrin 70% lórí ohun tó ń jáde yìí?

Iwadii fi han wa pe TikTok ṣi n gba ida aadọrin lori awọn ẹbun to n jade loju opo wọn lasiko ti wọn ba n gbe awọn aworan ihooho naa jade. Ṣugbọn ileeṣẹ naa sọ pe oun ko gba to bẹẹ, koda lẹyin ti a tun ri iru nnkan bẹẹ ninu iwadii kan ti a ṣe ni 2022.

O pẹ ti TikTok naa ti mọ nipa fifi ọmọde pawo pẹlu ihooho yii, nitori awọn naa ti ṣe iwadii wọn ni 2022.

Ṣugbọn wọn gboju nibi ọrọ naa nitori ere ti wọn n jẹ nibẹ, gẹgẹ bi ileeṣẹ agbẹjọro kan to tako wọn l'America lọdun to kọja ṣe sọ.

TikTok naa da ileeṣẹ agbẹjọro naa lohun pe ko ro ti awọn nnkan toun ti ṣe siwaju lati mu aabo dara si i.

Ileeṣẹ kan ti ki i ṣe ti ijọba ni Kenya, Child Fund Kenya, ṣalaye pe Kenya jẹ ibi kan ti aaye ti gba aṣilo nnkan.

O ni bo ṣe tun jẹ pe awọn ọmọde lo pọ ju, to n lo oju opo naa, nibẹ tun ni ipa buruku.

Gbogbo ilẹ Africa jakẹjado ni abojuto to peye ko si fun lori ọna ti eeyan n gba loju opo ayelujara, bi ajọ naa ṣe sọ.

Apẹẹrẹ awọn ami ti wọn n lo loju opo TikTok, eyi ti wọn n pada sọ di owo bi ọrọ ba wọ tan laaarin awọn ti wọn jọ n ba ara wọn sọrọ nibẹ.
Àkọlé àwòrán, Eeyan le kọ ẹkọ loju opo yii, bii ọna ti wọn n gba ṣe oju loge ti a mọ si 'make-up'. Bi wọn yoo ba sanwo ẹkọ yii, nipa ọna ti a mọ si emoji gifts ni, wọn yoo pada sọ ọ di owo.

Báwo làwọn tó ń fi ìhòhò hàn náà ṣe ń ṣe é?

Jo, ọkunrin to ṣiṣẹ nileeṣe ayelujara, ṣalaye pe wọn maa n fun awọn atọkun eto ni ilana ti wọn yoo fi ṣiṣẹ, ki wọn ma baa lu ofin ọrọ ibalopọ ati ìṣe.

O ni ṣugbọn ofin naa nibi to de, ko si kan isọkusọ ati ki eeyan maa jo ijo to le mu ara ọkunrin dide.

"Ẹyin naa yoo ti ri i pẹlu bi wọn ṣe maa n ṣe bi wọn ba gbe kamẹra wọn dani, wọn yoo gbe kamẹra foonu wọn sibi aarin meji ọyan wọn, wọn tun maa n gbe e sibi itan wọn, wọn yoo maa kede pe awọn n wa ibalopọ. Wọn le ma sọ nnkan kan jade o, ṣugbọn ẹyin naa le ri i furan yin ninu ìṣe wọn ati loju opo mi-in paapaaa, ṣugbọn ko si nnkan kan ti mo le ṣe si i ni temi."

Jo lo ṣalaye bẹẹ.

Oṣiṣẹ mi-in ti a pe ni Kelvin, ṣalaye pe ẹka AI naa tun jẹ ko ṣoro fun TikTok

Jo ati Kelvin wa lara awọn meje to ti ba TikTok ṣiṣẹ, ẹnikan ti kuro nibẹ ninu wọn, ikeji ṣi wa nibẹ .

Jo sọ pe ida ọgọrin ( 80%) aworan oju ẹsẹ (livestreams) ti wọn n gbe jade ni i ṣe pẹlu ibalopọ, tabi ki wọn maa kede rẹ. O ni TikTok si mọ ibi ti kinni ọhun de duro.

Aworan foonu to n ṣafihan ọmọbinrin kan to n jo labẹnu, pẹlu àmì oju opo Tiktok

''Àwọn ọmọdé tí ọjọ́ orí wọn kò ju mẹ́sàn-án lọ náà ti ń kópa nínú fífi ìhòhò hàn ní TikTok''

Ajọ ChildFund Kenya ati awọn ajọ alaanu bi eyi ni Kenya, sọ fun BBC pe awọn ọmọde ti ọjọ ori wọn ko ju mẹsan-an lọ naa ti n kopa ninu fifi ihoho ẹni han loju opo TikTok.

A ti ba awọn ọlọmọge ati awọn ọsọrọ obinrin sọrọ lori ohun to n ṣẹlẹ yii, wọn si jẹwọ fun wa pe awọn maa n lo to wakati mẹfa si meje loru lati pa owo to to ọgbọn pọn-un (£30 ) lojumọ.

Wọn ni owo naa yoo to awọn lati jẹun lọsẹ kan, awọn yoo si tun roro wọ mọto lọ sibi tawọn ba fẹẹ lọ.

"Mo n ta ara mi ni TikTok. Mo maa n jo nihooho. Mo n ṣe bẹẹ nitori ibi ti mo ti le rowo gbọ bukaata ara mi niyẹn."

Ọmọbinrin ẹni ọdun mẹtadinlogun kan ti a pe orukọ ẹ ni Esther lo salaye bẹe. Agbegbe awọn ti ìṣẹ́ n ṣẹ ni Nairobi lo n gbe , nibi ti eeyan bii ẹgbẹrun mẹta ti n pin ile igbọnsẹ lo .

O ni owo toun n ri naa loun maa n fi ra ounjẹ fun ọmọ oun, oun si tun n fi ran mama oun lọwọ pẹlu, nitori latigba ti baba oun ti ku ni iya naa ti n daamu lati san owo ile tawọn n gbe, ko le baa ri owo naa san tun wa lara idi toun fi n lo ihoho oun lati pawo lori ayelujara.

Esther sọ pe ọmọ ọdun mẹẹẹdogun (15) loun wa nigba ti ọrẹ oun kan mu oun mọ TikTok Lives yii.

O ni ọrẹ naa lo ba oun ṣe e ti wọn ko fi mọ pe ọjọ ori oun ko ti i pe mejidinlogun, (18),nitori ẹni ti ọjọ ori rẹ ba ti wọ mejidinlogun soke lo le lo oju opo yii gẹgẹ bii ofin. Ẹni to si fẹẹ lo oju opo TikTok Live gbọdọ ni eeyan ẹgbẹrun kan (1,000) to n tẹle loju opo naa.

Eyi lo jẹ ko ṣee ṣe fun awọn ti ero ba pọ lẹyin wọn ni TikTok lati le maa ta ihoho wọn, bi wọn ba fẹ bẹẹ. Oju opo awọn mi-in gan-an ko ṣiṣẹ mọ, nitori TikTok ti gbegile wọn nigba kan fun awọn idi kan.

Mo kábáàmọ̀ pé mo fi ìhòhò mi hàn ní TikTok- Sophie

"Sophie", orukọ rẹ gan-an kọ, sọ fun wa pe ọmọ ọdun mẹẹe\dogun loun naa wa toun ti bẹrẹ si i fi ihoho oun han ni TikTok.

o ni oun maa n ri awọn ọkunrin ti wọn yoo ni koun fi ọyan oun han wọn, tabi ki oun maa tọwọ bọ oju ara oun fun wọn. wọn yoo si sanwo rẹ foun.

Sophie loun ti n kabaamọ iwa naa bayii, nitori awọn fidio toun fi ranṣẹ sawọn onibaara oun loju opo ayelujara mi-in ni wọn ti fi ranṣẹ sibomi-in, wọn si n gbe e jade lori ayelujara lai beere aṣẹ lọwọ oun ki wọn too maa ṣe bẹẹ.

O ni awọn araale oun gan-an ti ri awọn fidio naa, wọn si n kilọ fun awọn ọdọ yopku lati ma ṣe ba oun ṣere tabi sun mọ ọdọ oun rara.

"Wọn ti ta mi nu, wọn dẹyẹ si mi, wọn sọ fawọn ọdọ bii temi pe mo maa ba aye wọn jé bi wọn ba sun mọ mi. Mo maa n da wa ni lọpọ igba." Sophie lo ṣalaye bẹẹ fun BBC.

Awọn obinrin mi-in ti a ba sọrọ naa sọ fun wa pe awọn ti ri awọn ọkunrin ori TikTok ti wọn ni kawọ wa fun ibasun ojukoju lẹyin tawọn pade ni TikTok.

Àwíjàre TikTok

''Ninu ẹka kaakiri ilẹ Africa jẹ TikTok logun, ṣugbọn wọn ko gba awọn oṣiṣẹ ti iye wọn to lati mojuto ohun to n lọ loju opo naa.''

Bayii ni awọn atọkun sọ fun wa ni Kenya

Ijọba Kenya naa ni awọn gbọ si ọrọ yii, iyẹn ni 2023.

Aarẹ Kenya, William Ruto, ṣepade pẹlu Adari TikTok, Shou Zi Chew, lati jẹ ki wọn maa mojuto ohun ti yoo maa jade loju opo naa. Ijọba sọ pe ileesẹ TikTok gba adehun tawọn jọ ṣe nigba naa wọle, wọn ni ọfiisi TikTok to wa ni Kenya yoo maa mojuto ohun to ba n jade.

Ṣugbọn lẹyin ọdun kan ati oṣu mẹfa, iyatọ kankan ko si, gẹgẹ bi awọn atọkun ti BBC ba sọrọ ṣe sọ fun wa.

Ẹnikan lati TikTok to ba BBC sọrọ sọ pe :

"TikTok ko nifẹẹ si irẹjẹ rara, a maa n ri i daju pe aabo to peye wa gan-an ni titi kan ofin to de gbigbe aworan jade bo ṣe n waye ti a mọ si Live Streaming.

''A n dari eto lede aadọrin ( 70 languages) titi kan Swahili, a si tun n ba awọn eleto ibilẹ paapaa dowopọ, titi kan ajọ to n gba wa nimọran nilẹẹ Africa, ki wọn le maa ro wa lagbara si i ninu ilana iṣẹ wa."