"Torí mo fẹ́ k'ọ́lé, mo sì fẹ́ san gbèsè ló jẹ́ kí n ta kíndìnrín mi"

Aworan ikun

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Iṣẹlẹ kayeefi to n ṣẹlẹ l'awọn abule kan lorilẹede Myanmar ni pe awọn eeyan kan n ta kíndìnrín wọn tori owo.

Ọkan lara iru awọn eeyan yii, Zeya, to jẹ agbẹ ṣalaye pe oun fẹ kọ ile, oun si tun fẹ san gbese to wa lọrun oun lo jẹ koun ta kíndìnrín oun.

Ọwọngogo nnkan gbode ni Myanmar lẹyin iditẹgbajọba to waye nibẹ lọdun 2021.

Zeya ṣalaye bi fifi ẹya ara eeyan ṣe kata kara ṣe wọpọ nilẹ Asia

Idunadura

Zeya ni ẹni to da bi alarina mu oun lọ sọdọ ẹni to nilo kindinrin ni Yangon.

O ni nibẹ ni ọkunrin kan to pe ara rẹ ni dokita ti kìlọ foun pe oun yoo san owo faini toun ba ni oun ko ṣe mọ.

Ọkùnrin pada sọ fun BBC pe isẹ toun ni lati ṣayẹwo bo ya ẹni to fẹ fi ẹya ara silẹ lagbara lati ṣe bẹẹ.

Zeya ni wọn sọ foun pe owo to to $1,700 si $2,700 l'awọn yoo foun to ba fi kíndìnrín oun silẹ.

Ile iwosan nla kan ni Zeya sọ pe ile iwosan nla kan lorilẹede India ni wọn ti yọ kíndìnrín oun.

Gbogbo iru iṣẹ abẹ bayii ni igbimọ kan ti ile iwosan tabi ijọba ibilẹ gbe kalẹ gbọdọ buwọ́lù ki wọn to ṣe e.

"Wọn beere lọwọ mi bo ya lootọ ni mo fẹ fi kíndìnrín mi kan silẹ fun obinrin to nilo rẹ.

Mo si sọ fun wọn pe ibatan mi ni ẹni to nilo kindinrin yii, lẹyin naa ni wọn buwọ́lù u.

Ọsẹ kan ni mo lo nile iwosan lẹyin ti wọn ṣe iṣẹ abẹ naa tan," Zeya ṣalaye.

Aworan ibi ti wọn ti n ṣiṣẹ abẹ

Mama ayederu

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ẹlomiran toun naa fi kíndìnrín rẹ silẹ, Myo Win, (eyi kii ṣe orúkọ rẹ gan an) sọ pe oun dibọn bi ẹni pe ibatan oun ni ajeji kan.

Win sọ pe "wọn nilo lati ba mama mi sọrọ ṣaaju iṣẹ abẹ naa ṣugbọn ẹni to da bi alarina lori ọrọ mi ni lati wa obinrin kan pe ko duro bi iya fun mi."

Myo Win ni iye ti wọn fun Zeya loun naa gba, amọ, o ni oun ni lati fun alarina oun ni idamẹwaa owo naa.

Awọn ọkunrin méjèèjì yii sọ pe wọn ti ida kan ninu ida mẹta owo naa fawọn ṣaaju iṣẹ abẹ ti wọn ṣe fawọn.

Win ni oun lati gba ki wọn yọ kíndìnrín oun lati le sanwo ile iwosan fun itọju iyawo oun ati lati le sab gbese toun jẹ.

Iṣoro airiṣẹṣe ti pọ si ni Myanmar lati igba ti wọn dìtẹ gbajọba nibẹ, eyi si ti jẹ ki ida kan ninu ida mẹrin awọn eeyan orilẹ ede naa to n gbe ninu iṣẹ ati oṣi ida kan ninu ida meji awọn eeyan ilẹ naa bayii gẹgẹ bi akọsilẹ ajọ UNDP.

Myo Win ni wọn o sọ foun pe tita kíndìnrín eeyan lodi sofin, bi bẹẹ kọọ, oun ko ba ti ṣe e tori oun ko fẹ dero ẹwọn.

Fifi ọwọ ofin mawọn eeyan ni India

Siṣe iṣẹ abẹ lati yọ ẹya ara eeyan kan fi paarọ fun ti elomiran ti wọ pọ ni India lati ọdun 2010.

Ajọ eleto ilera lagbaaye WHO sọ pe ko din ni 150,000 iṣẹ abẹ lati fi ṣe pasipaarọ ẹya ara to n waye ni India lọdọọdun.

Amọ, ajọ WHO bi ida mẹwaa ẹya ara tawọn eeyan nilo pere lo wa nlẹ.

Fifi ẹya ara eeyan ṣe kata kara lodi sofin kaakiri agbaye, ajọ WHO ni bi ida 5% si 10% eya ara ti wọn n lo fi ṣe pasipaarọ fawọn eeyan ni wọn n ra lọna aitọ.

Oṣi ati iṣẹ lo n mu kawon eeyan kan maa ta eya ara wọn bii kindinrin tori owo.

"Mi o kabamọọ pe mo ta kindinrin mi"

Ọga agba kan ni ẹka eto ilera ni India kọwe sawọn ipinlẹ lorilẹede pe ṣiṣe biṣẹ abẹ lati yọ ẹya ara awọn eeyan to n wa lati ilẹ okeere ti n pọ si.

BBC kan si ẹka eto ilera ni India ati ajọ to n ri si iṣẹ abẹ yiyọ ẹyà ara ẹnìkan si ti ẹlomiran, ko si ẹni to fesi ninu wọn.

Amọ, dokita kan ni Myanmar, Dokita Thurein Hlaing Win sọ pe awọn agbofinro ko ṣiṣẹ wọn bi iṣẹ lori ọrọ naa.

O fikun ọrọ rẹ pe o yẹ k'awọn to ba fẹ fi ẹya ara wọn silẹ mọ ewu to wa nibẹ ki wọn to ṣe iru nkan bayii.

Ẹwẹ, nigba ti BBC kan si Zeya leyin to ta ọkan lara kíndìnrín rẹ tan, o ni oun ti san gbese toun jẹ, oun si tun ti ra ilẹ pẹlu.

Amọ, Zeya ni oun ko tii le kọ ile bi oun ti n gbadun bọ lẹyin iṣẹ abẹ toun fi ta kíndìnrín oun.

Zeya ni lo n ro oun julọ lati igba ti wọn ti ṣiṣẹ abẹ naa foun.

O ni oun maa to bẹrẹ iṣẹ laipẹ, ati pe bi ẹyin to n ro oun ba si tun pada, oun ni lati faramọ bẹẹ ni.

Amọ, Zeya ni oun o kabamọọ pe oun ta kíndìnrín oun.