Bí o ṣe le di ọmọ ilẹ̀ America pẹ̀lú 'Gold Card' tí Trump fẹ́ ṣe ìfilọ́lẹ̀ rẹ̀

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ijọba orilẹede America ti kede ọna tuntun ti awọn arinrin-ajo to ba fẹẹ di ọmọ oniluu, le gba.
Ọjọ Iṣẹgun, ọjọ karundilọgbọn, oṣu Keji, ọfiisi rẹ ni Aarẹ Donald Trump ti kede eyi, lasiko to n buwọlu awọn iwe àṣẹ kan, niṣoju Akọwe fun eto ọrọ-aje, Howard Lutnick.
Aarẹ Trump sọ pe awọn yoo ta kaadi kan ti wọn pe ni 'Gold Card', fun iru awọn atipo bẹẹ, ni miliọnu marun-un Dola.
O ni kaadi naa niyi ju Green Card ti wọn n fun awọn atipo lọ, lati di ọmọ oniluu.
Ọna tuntun yii to n foju sọ awọn oludokowo, yoo fun wọn ni ẹtọ lati maa gbe ni US, wọn o tun le ṣiṣẹ pẹlu - yoo si rọpo fisa EB-5 to ti wa nilẹ tẹlẹ fun awọn oludokowo lati ọdun marundinlogoji sẹyin.
"Kaadi alawọ goolu ti a fẹ ta ni miliọnu marun-un Dola, yoo fun ọ ni awọn anfaani Green Card, yoo si tun jẹ ọna lati di ọmọ ilẹ America.
" Awọn to lowo lọwọ yoo wa si orilẹede wa ti wọn ba ti ra kaadi yii, wọn o ṣe aṣeyọri, wọn o na ọpọlọpọ owo, wọn o san owo ori to pọ, wọn o si gba awọn eeyan ṣiṣẹ."
Trump sọ pe ọsẹ meji si asiko yii ni awọn yoo ṣe ifilọlẹ fisa 'Gold Card' ọhun, to si ni oun ko lero pe oun nilo àṣẹ ile aṣofin lati ṣe bẹẹ.
Ninu ọrọ tiẹ, Ọgbẹni Lutnick sọ pe, Fisa EB-5 ti wọn n lo tẹlẹ ko dara to, to si jẹ awuruju.















