Nítorí ọjọ́ iwájú Naijiria la ṣe pa Ọgagun Vatsa, ọ̀rẹ́ mi ìgbà èwe-IBB

Ọgagun Ibrahim Badamosi Babangida ati Oloogbe Mamman Vatsa

Oríṣun àwòrán, Others

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 7

Ọrọ pọ ninu iwe kọbọ ni iwe ti aarẹ Naijiria tẹlẹ, Ibrahim Badamosi Babangida (IBB), kọ nipa ara rẹ to pe ni 'A journey in Service.'

Ẹ o ranti pe ninu iwe naa lo ti kede pe MKO Abiola lo gbegba oroke ninu idibo June 12, 1993, to si ti dohun ti awọn eeyan n ṣe atupalẹ ọrọ naa kiri bayii.

Abala mi-in to tun n ja ran-in nilẹ bayii ninu iwe naa ni apa ibi ti Babangida ti paṣẹ pe ki wọn yinbọn pa ọrẹ igba ewe rẹ, Ọgagun Mamman Vatsa ati awọn ṣọja mẹsan-an mi-in loṣu Kẹta ọdun 1986.

Ẹsun igbimọpọ lati gba ijọba lọwọ IBB to wa lori aleefa nigba naa ni wọn fi kan Vatsa toun ati Babangida ti n ṣe ọrẹ bọ lati Minna nigba ti won wa ni kekere.

Ẹsun naa ni IBB sọ pe o foju han kedere pe Vatsa lọwọ nibẹ, ati pe oun gan-an lo sanwo fun awọn ṣọja yooku lati wa ọna ti wọn yoo fi ditẹ gba ijọba mọ oun lọwọ.

''Mo ti n hu ọrọ naa gbọ, pe Vatsa, ọrẹ mi timọtimọ atawọn kan fẹẹ gbajọba mọ mi lọwọ. Mi o gba gbọ, mo ro pe ahesọ ni.

''Ṣugbọn a bẹrẹ si i fimu finlẹ gẹgẹ bi ologun lati mọ otitọ, mo si pe Vatsa funra rẹ, mo beere lọwọ rẹ, o sọ fun mi pe irọ ni.

''Aṣe Vatsa lo n fun awọn ṣọja to fẹẹ lo lowo iṣẹ iditẹgbajọba naa.

''O fun Lt-Col.Musa Bitiyong, ni ẹgbẹrun lọna aadọta naira (N50,000.) Bitiyong jẹwọ pe oun gba owo lọwọ rẹ, ṣugbọn Vatsa sọ pe owo iṣẹ oko kan to fẹẹ ṣe loun san fun un.

'' Lara ohun ti wọn tun fẹẹ ṣe nigba naa ni jiju bọmbu si ori afara Eko, ki wọn si gbabọde lori awọn nnkan ini ileeṣẹ ọlogun to ṣe pataki''

IBB sọ pe inu oun bajẹ nigba toun ri i pe Vatsa lọwọ ninu ipinnu naa, ṣugbọn ẹnikẹni to ba gbiyanju iditẹgbajọba ninu ologun to si kuna, ti mọ ohun ti yoo ṣẹlẹ si i.

''O dun mi bii ẹlẹran ara, o si ko irẹwẹsi ọkan ba mi. Ṣugbọn o di dandan ki wọn ku gẹgẹ bi ofin iṣẹ ologun. Ninu ki n padanu ọrẹ mi igba ewe tabi ki n ko gbogbo Naijiria si iyọnu ni mo wa, mo gbọdọ mu ọkan ninu mejeeji ni''

Bẹẹ ni IBB ṣalaye.

Mọ̀lẹ́bí Vatsa bínú, bèèrè àtúnṣe

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ọkan lara awọn mọlẹbi Oloogbe Ọgagun Vatsa to pe orukọ rẹ ni Jonathan, ti fi ibinu rẹ han si Babangida nipa alaye rẹ naa.

Jonathan sọ pe bi wọn ṣe pa ẹgbọn oun ko yẹ rara.

" Ohun ti mo ti n sọ tipẹ ni pe wọn pa a lai lẹtọọ ni, ko yẹ ko ku rara. Ko si idi pataki kan fun wọn lati pa a.

''Koda ko tiẹ jẹ pe ile ẹjọ ologun dajọ iku fun un, o ṣi lẹtọọ lati pe ẹjọ Ko-tẹ-mi-lọrun, ko tiẹ too pe ẹjọ naa rara ni won ti pa a, wọn kede pe wọn ti pa a ni wakati kan ṣaaju igba yẹn.

'' Ki lo n kan wọn loju lati pa alaiṣẹ?''

Jonathan sọ pe ki i ṣe nitori Naijiria ni wọn ṣe pa Vatsa, o ni won ri i pe o le ṣakoba fawọn ni wọn ṣe pa a. O ni won ko ni i le ṣe ohun ti won fẹ bi Vatsa ba wa laye ni wọn ṣe pa a.

"Babangida ni lati tọrọ aforiji to pọ lọwọ awon ọmọ Naijiria fun gbogbo aburu to ti ṣe si wọn. Aforiji nikan si kọ, o gbọdọ ṣe atunṣe, ko si da gbogbo ohun to ti fi ona èrú gba lọwọ awọn ọmọ Naijiria pada''

Bẹẹ ni mọlẹbi Oloogbe Ọgagun Vatsa wi.

Fún àǹfàní Nàìjíríà la ṣe fagilé ìbò June 12 tí MKO Abiola borí- IBB

Aworan Ibrahim Badamosi Babangida, olori Naijiria nigba kan.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Kí nńkan lè dáà fún Naijiria la ṣe fagilé ìbò June 12- Babangida

Bi nnkan ko ba ṣe ẹṣẹ, ẹṣẹ ki i deede ṣẹ ni ọrọ ti olori Naijiria nigba kan laye ologun, Ibrahim Badamosi Babangida n sọ bayii.

Babangida ni oun ko deede fagile ibo June 12, 1993, ko le baa da fun Naijiria ni.

Ni itẹsiwaju alaye to ṣe pe Oloogbe MKO Abiola lo wọle ibo ọhun, Babangida sọ pe labẹ akoso oun ni gbogbo aṣiṣe ọdun mejilelọgbọn naa ti waye.

Aarẹ tẹlẹ naa ṣalaye pe ṣugbọn ko le baa daa fun gbogbo Naijiria lapapọ loun ṣe fagile ibo alaafia naa.

IBB bi wọn tun ṣe maa n pe e, sọ pe oun kabaamọ pe oun fagile ibo Abiola, nitori ohun to ṣẹlẹ naa fa ijọba Dẹmokresi sẹyin lorilẹede yii.

" Irinajo wa si ijọba Dẹmokresi fa sẹyin, o si dun mi gan-an. Ṣugbọn Naijiria bori ẹ, Dẹmokresi dẹ wa laye titi doni, eyi to n tọka si iduroṣinṣin wa, to si n fi han pe a ṣetan lati tẹsiwaju. "

Babangida lo fi kun alaye rẹ bẹẹ.

"Bo tilẹ jẹ pe o wa lakọsilẹ pe mo sọ pe Abiola le ma wọle ibo naa, ṣugbọn lẹyin awofin ati ayẹwo kikun, paapaa ninu esi idibo naa to kun daadaa ti mo kọ sinu iwe mi yii, ko si iyemeji rara pe MKO Abiola bori ibo June 12"

Bẹẹ ni Babangida ṣalaye siwaju ninu iwe itan igbesi aye rẹ to kọ to pe ni ' A Journey in Service.'

Ibrahim Babangida kéde pé MKO Abiola ló wọlé ìbò ''June 12'' 1993 tó fagilé

Aworan MKO Abiola ati Ibrahim Babangida

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Fun igba akọkọ, olori orilẹede Naijiria tẹlẹ ri, Ọgagun fẹyinti Ibrahim Babangida, ti kede pe Oloye Moshood Kasimawo Olawale Abiola lo wọle ibo aarẹ ''June 12'' ọdun 1993 eyi to fagile.

Ọgagun Babangida kede ọrọ yii ninu iwe ti o kọ nipa ara rẹ eyi to ṣe ifilọlẹ rẹ l'Ọjọbọ ogunjọ oṣu Keji ọdun yii niluu Abuja.

Abiola dupo aarẹ labẹ asia ẹgbẹ oṣelu Social Democratic Party (SDP) lọdun naa.

Babangida sọ ninu iwe naa to pe akọri rẹ ni "Irinajo Lẹnu Iṣẹ (A Journey in Service) pe Abiola la Alhaji Bashir Tofa oludije ẹgbẹ oṣelu National Republican Council (NRC) mọlẹ ninu ibo ọhun.

''Moshood Abiola lo jawe olubori ninu ibo aarẹ ọdun 1993 lẹyin to ni ibo to le ni miliọnu mẹjọ ti o si la Tofa ẹgbẹ NRC to ni ibo miliónu marun un mọlẹ,'' Babangida lo sọ bẹẹ.

Ninu ọrọ rẹ, Babangida ni oun ti n gbero lati fagile le esi ibo naa tipẹ.

Babangida ni ''emi ni mo jẹbi gbogbo nnkan to ṣẹlẹ ni Naijiria lasiko naa ti mo jẹ aarẹ orilẹede Naijiria.''

Ohun to ṣẹlẹ ni ''June 12'' lọdun 1993

Lọjọ kejila oṣu Kéfa ọdun 1993 ni oludije sipo aarẹ labẹ asia ẹgbẹ oṣelu SDP, Abiola ati Tofa to jẹ ọludije ẹgbẹ NRC dije ninu eto idibo aarẹ Naijiria.

Baba Gana Kingibe lo dije pẹlu Abiola bii igbakeji rẹ, nigba ti Sylvester Ugoh si dije gẹgẹ bii igbakeji Tofa.

Bo tilẹ jẹ pe, awọn onwoye ṣapuwe ibo aarẹ 1993 gẹgẹ eto idibo to wọọrọ julọ ninu itan, Ọgagun Babangida wọgile ibo, o ni eeru wa nibẹ

Igbesẹ Babangida yii da wahala silẹ, o si pada kuro lori oye lọdun 1993 yii kan naa.

Lẹyin naa ni Ernest Shonekan di aarẹ fidihẹ orilẹede Naijiria.

Ni ọjọ kọkanla oṣu Kẹfa ọdun 1994 ni Abiola kede ara rẹ gẹgẹ bii aarẹ Naijiria niluu Eko.

Eyi lo jẹ ki ijọba ologun Sani Abacha fẹsun iditẹmọjọba kan an ti wọn si mu un lọjọ kẹtalelogun oṣu Kẹfa ọdun 1994.

Ọdun mẹrin ni Abiola fi wa lẹwọn, ohun ti a tiẹ gbọ ni pe wọn ko jẹ ki o lanfaani lati kawe kankan yatọ si Bibeli ati Quran.

Abiola ku lọjọ keje oṣu Keje ọdun 1998 ni ọjọ to yẹ ko kuro lẹwọn.