Ṣáká lara mi dá, mi ò lárùn ọpọlọ o - Portbale sọ̀rọ̀ níwájú adájọ́

Aworan Portbale nile ẹjọ
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 7

Gbajugbaja onkọrin takasufee nni, Habeeb Okikiọla Olalomi Badmus ti ọpọ awọn ololufẹ rẹ mọ si Portable ti sọ fun ile ẹjọ majisireeti ti ipinlẹ Ogun wi pe ṣaka lara oun da, oun ko ni aisan tabi arun kankan lara.

Portable lo sọrọ naa niwaju Onidajọ O. L. Oke ti ile ẹjọ mijisireeti ipinle Ogun to wa niluu Abẹokuta, lati le fidi eto ilera ara rẹ lelẹ lori fọnran to ṣe sita laipẹ yii wi pe oun ni kaadi ni ile iwosan Aro, nibi ti wọn ti n tọju awọn alaarun ọpọlọ.

Portable lo n jẹjọ lori ẹsun to nii ṣe pẹlu igbimọpọ lati huwa iwa ibajẹ, ṣiṣe ikọlu pẹlu ada ati ibọn, dida alaafia ilu laamu ati didi awọn oṣiṣẹ ijọba lọwọ iṣẹ wọn.

Onidajọ Oke to gbọ ẹjọ naa lonii, Ọjọbọ, ogunjọ oṣu keji, ọdun 2025 sọ pe ki Portable rii daju pe oun tẹlẹ awọn ilana beeli rẹ.

Ọjọru to kọja ni Portable jọwọ ara rẹ fun ọlọpaa nipinlẹ Eko, ko to di pe wọn fa a le awọn ọlọpaa ipinlẹ Ogun lọwọ.

Agbefọba Timileyin Oredehin to fẹsun kan Portable niwaju ile ẹjọ jẹ ko di mimọ pe Portable lo lu awọn oṣiṣẹ ijọba ti wọn n ri sọrọ ile kikọ, iyẹn Town Planning nipinlẹ Ogun.

Portable loun o jẹbi ẹsun ti wọn fi kan oun

Ẹsun marun ọtọọtọ ni wọn fi kan Portable, eyi to nii ṣe pẹlu igbimọ papọ iwa ibajẹ ti lodi si ofin iwa ọdaran, ṣiṣe ikọlu ati awọn miran.

Gbogbo awọn ẹsun wọnyi ni Portable sọ fun ile ẹjọ wi pe oun ko jẹbi wọn.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Agbẹjọro Portable, Oluwatoyin Omomeyin Ayodele nigba to n sọrọ rọ ile ẹjọ lati faye beeli silẹ fun onibara oun, nitori pe ẹsun ti wọn fi kan an kii ṣe eyi to pọ to bẹẹ.

Omomeyin ni oun nigbagbọ ninu onibara oun, wi pe yoo maa yọju sile ẹjọ loore koore lasiko ẹjọ naa, bẹẹ si ni ko nii salọ fun igbẹjọ.

Agbẹjọro naa ni ki ile ẹjọ ma ṣe wo ti awọn ẹsun ti wọn fi kan Portable, bi ko ṣe pe ko da a silẹ lati maa gba ile wa jẹjọ, nitori pe yoo tẹle awọn ilana ti ile ẹjọ ba fi silẹ fun beeli.

Ninu ọrọ Onidajọ Oke, o loun yoo fun Portable ni beeli pẹlu miliọnu meji naira ati oniduuro meji ọtọọtọ ti wọn n gbe nipinlẹ Ogun.

"Bi o ba kuro nile ẹjọ yii, ti o si lọ sita lati lọ ṣe fọnran lori eyikeyi itakun ayelujara lati sọ nipa ohun to ṣẹlẹ nile ẹjọ yii, a maa gbẹsẹ le beeli rẹ.

Bi o ba kuro nile ẹjọ yii, ti o tun lọ n da wahala silẹ tabi dunkoko mọ awọn oṣiṣẹ ijọba naa, ile ẹjọ maa gbẹsẹ le beeli rẹ.

"Bi Portable ba kọ lati yọju si ile ẹjọ lasiko igbẹjọ, tabi ti o pẹ ki o to de ile ẹjọ, a maa gbẹsẹ le beeli rẹ.

O ni lati bẹrẹ sii ṣe jẹjẹ, ki o si maa ṣe bii ọmọluabi," Onidajọ Oke lo sọ bẹẹ.

Onidajọ Oke ti wa sun igbẹjọ siwaju di ọjọ karun, oṣu Kẹta, ọdun 2025, to si fidi rẹ mulẹ pe ọjọ naa ni wọn yoo tun gbo ẹjọ awọn ọmọ ẹyin rẹ ti wọn ti kọkọ ṣe ṣaaju, eyi ti wọn sun siwaju di ọjọ kẹtadinlogun, oṣu Kẹta, ọdun yii tẹlẹ.

Iléẹjọ́ gba béèlì Portable lẹ́yìn tí ọlọ́pàá wọ́ọ lọ sílé ẹjọ́ l'Ọ́jọ́bọ̀

Aworan Portable nile ẹjọ ni Ọjọbọ.

Ile ẹjọ giga ipinlẹ Ogun kan eyi to fikalẹ si agbegbe Ishabọ nilu Abẹokuta ni pinlẹ Ogun ti gba oniduro fun gbajumọ akọrin takasufe, Habeeb Okunọla ti ọpọ mọ si Portable lori ẹsun kikọlu awọn agbefọba ileeṣẹ ato ilu ti ijọba ipinlẹ Ogun laipẹ yii.

Ileeṣẹ ọlọpaa wọ Portable lọ si ile ẹjọ lowurọ Ọjọbọ, ṣugbọn agbẹjọro rẹ, Amofin Oluwatoyin Ọmọmẹyin Ayọdele ṣalaye fun BBC pe ẹbẹ ti awọn ọlọpaa gbe ka iwaju ile ẹjọ naa ni pe ki adajọ maṣe fun un ni beeli titi di igba ti wọn yoo fi yanju ẹjọ naa.

Amofin Ayọdele ṣalaye siwaju sii pe, "ijọba ipinlẹ Ogun ti tẹwọ gba ẹjọ naa lọwọ awọn ọlọpaa wọn si ti fun un ni beeli".

Awọn ohun ti wọn beere fun ati gba beeli rẹ ni miliọnu meji Naira ati oniduro meji.

Ile ẹjọ naa tun ni ko gbdọ sọrọ lori ohunkohun to jọ mọ ẹjọ naa lori ayelujara tabi ita gbangba kankan rara.

Ileẹ ẹjọ Giga naa wa sun igbẹjọ rẹ si ọjọ karun un oṣu kẹta ọdun 2025.

Ileeṣẹ ọlọpaa gbe Portable lọ siwaju ile ẹjọ ni Ọjọbọ lẹyin to jọwọ ara rẹ fun ẹka ọtẹlẹmuyẹ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko to wa lagbegbe Yaba nilu Eko lọjọru.

Ileeṣẹ ọlọpaa ni ipinlẹ Ogun ti ṣaaju kede Portable gẹgẹbi ẹni ti ofin n wa fun ẹsun pe o lewaju awọn eeyan kan to kọlu awọn oṣiṣẹ ileeṣẹ ato ilu ni ipinlẹ Ogun lasiko ti wọn ṣe iṣẹ de agbegbe ile ọti rẹ ni ilu Sango Ota.

Awọn agbefọba naa farapa yanayana.

Bi otilẹ jẹ wi pe ọwọ tẹ mẹsan an ninu awọn amugbalẹgbẹ Portable, amọ gbajumọ akọrin naa sa mọ ofin lọwọ fun ọpọlọpọ ọjọ ki o to lọ jọwọ ara rẹ ni Ọjọru.

Portable jọ̀wọ́ ara rẹ̀ fún ọlọ́pàá Panti l'Eko, wọ́n bá taare rẹ̀ sí ìpínlẹ̀ Ogun
Portable

Lẹyin ọjọ diẹ ti wọn kede pe awọn n wa a, Habeeb Okikiola ti ọpọ mọ si Portable ti fa ara rẹ le awọn ọlọpaa lọwọ.

Ẹka ileeṣẹ naa to n ṣewadii iwa ọdaran, CID, eyii to wa ni Panti, niluu Eko ni Portable ti lọ jọwọ ara rẹ.

Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko, Benjamin Hundeyin ti fidi iroyin naa mulẹ fun awọn akọroyin.

Hundeyun ni "Portable ti jọwọ ara rẹ ni agọ ọlọpaa to wa ni Panti, a si ti ke si ọọfisi wa nipinlẹ Ogun pe ki wọn wa mu."

Portable balẹ si Abeokuta

Ẹwẹ, wọn ti gbe olorin naa de olu ileeṣẹ ọlọpaa to wa ni Eleweran, niluu Abeokuta.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun, Omolola Odutola sọ ninu atẹjade kan pe "ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun fẹ fi to araalu leti pe Habeeb Okikiola, ti ọpọ mọ si Portable, ti de si ẹka CID wa ni Eleweran, nillu Abeokuta ni nnkan bii aago kan kọja iṣẹju mẹtalelogun lọsan Ọjọru, ọjọ kọkandinlogun, oṣu Keji, ọdun 2025.

"Wiwa rẹ sọdọ wa ko ṣẹyin iwadii kan to n lọ lọwọ. A fi da gbogbo araalu loju pe a o ṣe gbogbo ohun to yẹ lori iwadii naa lọna to ba ofin mu, a o si maa bun araalu gbọ bi iwadii wa ba ṣe n lọ."

Ṣaaju ko to lọ jọwọ ara rẹ fun ọlọpaa lọjọru ni Portable ti kọkọ sọ loju opo Instagram rẹ pe oun ko mọọmọ ṣe ohun ti wọn n wa oun fun amọ oun ṣe wu iwa kotọ naa nitori arun ọpọlọ to n da oun laamu.

Portable sọ pe ilẹ ti ta si ti oun ko ti gbadun amọ oun n gba itọju lọwọ.

Laarọ Ọjọru, portable kọ atẹjade mii soju opo Instagram rẹ nibi to ti n bẹ ijọba ipinlẹ Ogun fun oju aanu.

Portable

Oríṣun àwòrán, Portable

O ni "Oba alaanu, mo n jade lọ loni, sọ ogun mi di ibukun. Jẹ ki ore ọfẹ rẹ fọhun fun mi.

"Ijọba ipinlẹ Ogun ẹ forijin mi, ẹru to ba mi lo mu ki n maa sa."

Portable wọ gau lẹyin to da seria fun awọn oṣiṣẹ ijọba ipinlẹ Ogun kan ti iṣẹ gbe lọ ile ọti rẹ, Odogwu Bar.

Iroyin ni iwe ile ọti naa ni awọn oṣiṣẹ ijọba naa bere lọwọ rẹ ki oun atawọn ẹmẹwa rẹ to bẹrẹ si n lu awọn eeyan ọhun.

Lẹyin naa ni awọn oṣiṣẹ ijọba ọhun fi ọrọ naa to ileeṣẹ ọlọpaa leti, ti ọlọpaa si fi panpẹ ofin mu awọn ẹmẹwa rẹ ọhun ti Portable funra rẹ si na papa bora.