Oriyomi Hamzat kọ́ ilé tuntun fún gbajúmọ̀ òṣèré, Iya Niwe n'Ibadan, ló bá bú sẹ́kún

Oríṣun àwòrán, Oriyomi Hamzat/Facebook
Níṣe ni ìdùnnú ṣubú layọ̀ fún àgbà òṣèré nnì Abigail Oladeji tí ọ̀pọ̀ mọ̀ sí Iya Niwe nígbà tí adarí iléeṣẹ́ rédíò Agidigbo FM tó wà ní Ibadan, Oriyomi Hamzat ṣi ilé fún-un.
Nínú fídíò kan tó gba orí ayélujára ṣàfihàn bí Oriyomi Hamzat ṣe ń ṣí ilé náà, tó sì ń ṣàdúrà fún Iya Niwe.
Gbogbo bí wọ́n ṣe ń ṣí ilé náà ni Iya Niwe ń wa omi lójú, tó sì ń sunkún ayọ̀.
Iya Niwe jẹ́ ọ̀kan lára àwọn tó ń bá Oriyomi Hamzat ṣe ètò Kọ́kọ́rọ́ Alátẹ, ètò kan tí Oriyomi Hamzat máa ń ṣe ní lórí Agidigbo FM.
Nínú fídíò náà, Iya Niwe tó ń wa ẹkún mu ní òun kò mọ ẹni tí yóò bá òun dúpẹ́ fún oore ńlá tí Oriyomi Hamzat ṣe fún òun.
Gẹ́gẹ́ bí ìròyìn tí a gbọ́, wọ́n ní Iya Niwe ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣe ìrìnàjò dé láti Jerusalem ni Oriyomi Hamzat fi ilé náà ta á lọ́rẹ̀.

Oríṣun àwòrán, Oriyomi Hamzat/Facebook

Oríṣun àwòrán, Oriyomi Hamzat/Facebook
Ta ni Iya Niwe?

Oríṣun àwòrán, Others
Fún àwọn tó bá máa ń wo fíìmù àgbáléwò Yorùbá láàárín ọdún 1990 sí ìbẹ̀rẹ̀ ọdún 2000, òdú Iya Niwe kìí ṣe àìmọ̀ fún olóko wọn.
Iya Niwe pẹ̀lú àwọn àgbà òṣèré bíi Kunle Adetokunbo tí ọ̀pọ̀ mọ̀ sí Dejo Tunfulu, Babatunde Omidina tí ọ̀pọ̀ mọ̀ sí Baba Suwe ni wọ́n jọ lo ìgbà lásìkò náà láti dẹ́rìn-ín pa àwọn èèyàn.
Lásìkò náà, ìyà arúgbó tó máa ń pani lẹ́rìn-ín tàbí ṣe bíi àjẹ́ ni ipa tí Iya Niwe máa ń kó nínú àwọn eré.
Ó máa ń kun ojú rẹ̀ àti eyin rẹ̀ pẹ̀lú èédú dúdú láti ṣàfihàn ara rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àgbàlagbà.
Bákan náà ló máa ń tẹ ọ̀pá tàbí kó máa tẹ̀ rìn láti ṣe bí arúgbó.
Ó ti tó bíi ọdún mẹ́wàá sẹ́yìn báyìí tí a kò ti gbúròó Iya Niwe nínú eré.
Nígbà tó ń bá Kunle Afod sọ̀rọ̀ lásìkò kan, Iye Niwe ní iṣẹ́ àgbẹ̀ ni òun ń ṣe kí Oriyomi Hamzat tó kàn sí òun pé kí òun fi iṣẹ́ náà sílẹ̀ láti wá máa kópa lórí ètò pẹ̀lú òun.
Ọ̀pọ̀ sinimá ni Iye Niwe kópa nínú rẹ̀ bíi Agogo Idanile, Osumare, Koto Aye àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.















