Ilé ẹjọ́ Kòtẹ́milọ́rùn gbé ìdájọ́ kalẹ̀ lórí ìyànsípò Ọba Ghandi Olaoye gẹ́gẹ́ bíi Soun Ogbomoso

Oríṣun àwòrán, Soun of Ogbomoso/Instagram
Ile ẹjọ Kotẹmilọrun niluu Ibadan ti fontẹ lu Ọba Ghandi Afolabi Olaoye, Orumogege Kẹta gẹgẹ Soun ti ilu Ogbomoso.
Igbimọ onidajọ ẹlẹni mẹta ti Ile ẹjọ kotẹmilọrun niluu Ibadan ti Adajọ Yargata Nimpar dari wọn yi idajọ ile ẹjọ giga danu, eyi to fagile Ọba Olaoye gẹgẹ bii Soun ilu Ogbomoso.
Ti ẹ o ba gbagbe, Ọmọba Muhammed Kabiru Olaoye lo gbe Ọba Ghandi lọ ile ẹjọ ti o si sọ fun ile ẹjọ wi pe ko koju oṣunwọn lati jẹ oye naa.
Ninu idajọ ile ẹjọ kotẹmilọrun lọjọ Iṣẹgun ọjọ kejidinlogun oṣu Keji yii, ile ẹjọ naa yi ẹsun ti Ọmọba Kabiru fi kan Ọba Ghandi pe ki i ṣe ọmọ ọba to ti wa lori apeere Soun ri danu.
Bakan naa tun ni ile ẹjọ wọgile ẹsun mii ti Ọmọba Kabiru sọ fun ile ẹjọ wi pe oju oori baba Ọba Ghandi ko si ni Abata nibi ti wọn maa n sin awọn Soun to ti waja si.
Ile ẹjọ kotẹmilọrun tun fontẹ lu igbesẹ awọn afọbajẹ to yan Ọba Ghandi sori oye Soun ilu Ogbomoso.
Lẹyin to kede idajọ rẹ ni ile ẹjọ kotẹmilọrun sọ pe ki olupẹjọ san faini N500,000.
Idajọ yii ti fagile idajọ ile ẹjọ giga ilu Ogbomoso ti Adajọ K.A. Adedokun fi wọgile iyansipo Ọba Ghandi lọkọ kẹẹdọgbọn oṣu Kẹwaa ọdun 2023.
Ninu idajọ ọhun ni Adajọ Adedokun ti dajọ wi pe iyansipo Ọba Ghandi tako ofin jijẹ ọba fun apere Soun ọdun 1958.
Ki lo de ti adajọ fi wọgile iyansipo Soun tuntun?

Oríṣun àwòrán, Soun of Ogbomoso/Instagram
Ọmọọba Kabir Olaoye to pe ẹjọ lati tako iyansipo Ghandi salaye pe aise deede wa ninu ilana ti wọn fi yan an.
O wa n rọ ile ẹjọ giga naa lati wọle iyansipo ọba tuntun yii, ko si pasẹ fun awọn afọbajẹ lati bẹrẹ igbesẹ yiyan ọmọ oye miran.
Nigba to n gbe idajọ rẹ kalẹ, Adajọ Adedokun to n gbọ ẹjọ naa wa kede pe iyansipo ọba Laoye ko bofinmu.
Bakan naa lo pasẹ pe ki awọn afọbajẹ lọ bẹrẹ ilana ọtun lati yan Soun tuntun
Saaju ni Adajọ Adedokun ti wọgile ẹbẹ mẹta ti ọkan ninu awọn olupẹjọ, Ọmọọba Adeyemi Taofiq Akorede Laoye gbe siwaju rẹ.
Awọn ẹbẹ naa loun naa fi n pe iyansipo oriade tuntun naa nija
Ijọba ipinlẹ Oyo pe ẹjọ kotẹmilọrun tako idajọ to rọ Soun Ogbomoso loye
Ijọba ipinlẹ Oyo pe ẹjọ kotẹmilọrun tako idajọ ile ẹjọ to rọ Soun ilu Ogbomosho, Oba Ghandi Afolabi Olaoye, loye.
Yatọ si ẹjọ kọtẹmilọrun yii, ijọba tun bẹbẹ pe ki ile ẹjọ maṣe gba ki wọn yọ ori ade ọhun loye titi ti yoo fi gbọ ẹjọ ti awọn pe.
Olupẹjọ naa tun n beere pe ki awọn to pe ẹjọ akọkọ, eyii ti ile ẹjọ da lare maṣe ṣe ohunkohun lati yọ Ghandi loye lasiko yii.
Ti ẹ ko ba gbabe, ọjọ karundinlọgbọn, oṣu Kẹwaa, ọdun 2023 yii ni Adajọ K. A. Adedokun da ẹjọ naa laarin ọmọba Muhammed Olaoye ati ijọba ipinlẹ Oyo atawọn mọkanla mii, ninu eyii to ti ni kudiẹkudiẹ wa ninu iyansipo ọba Ghandi Olaoye, nitori naa ko fi ipo naa silẹ.
Lẹyin idajọ ọhun ni Akin Onigbinde, SAN, pe ẹjọ kotẹmilọrun lorukọ gomina ipinlẹ Oyo, Seyi Makinde atawọn mii ti ọrọ naa kan nipinlẹ lori idajọ to gba ade Ọba lori Soun tuntun.
Ipẹjọ yii ni agbẹjọro ijọba ti fa koko mẹfa yọ ninu eyii to ti tako idajọ ile ẹjọ akọkọ.
O ni awọn ẹri to wa nilẹ tako idajọ to waye pe Ghandi ko yẹ loye Soun ilu Ogomosho.
Lara awọn ti ijọba pe lẹjọ kotẹmilọrun yii ni agbẹjọro Oladapo Atanda, ijọba ibilẹ ariwa Ogbomosho ati igbimọ afọbajẹ Ariwa Ogbomosho.
Awọn to ku ni agbẹjọro S.A. Mohammed, ileeṣẹ Mohammed & Mohammed & Co., Mobolaji Chambers, Kola Fatoye, Oloye Samuel Otolorin, Oloye Salawu Ajadi, Oloye Tijani Abioye, Oloye David Adeniran Ojo, atawọn mii.















