Gbogbo èrò inú bàlúù tó já, dojúdé l'Ámẹ́ríkà ló móríbọ́

Ọkọ̀ òfurufú tó jà lulẹ̀

Oríṣun àwòrán, Reuters

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Orí kó èèyàn ọgọ́rin yọ nígbà tí ọkọ̀ òfurufú tí wọ́n wà nínú rẹ̀ já lulẹ̀, tó sì dojúdé lásìkò tó fẹ́ bà sílẹ̀ ní pápákọ̀ òfurufú Toronto Pearson Airport ní Canada.

Deborah Flint, òṣìṣẹ́ pápákọ̀ òfurufú Greater Toronto Airports Authority sọ pé inú àwọn dùn pé ìjàmbá náà kò mú ẹ̀mí ẹnikẹ́ni lọ.

Àwọn aláṣẹ sọ pé èèyàn mejìdínlógún ló farapa nínú ìjàmbá ọ̀hún, tó fi mọ́ ọmọdé àtàwọn àgbàlagbà méjì tí ìfarapa wọn lágbára gidi.

Àwọn àwòrán tó jáde ṣàfihàn bí ọkọ òfurufú náà ṣe dojúdé níbi tó já sí, tí yìnyín sì gba gbogbo ibi tó wà kan.

Ohun tó ṣokùnfà tí ọkọ̀ òfurufú Delta Air, tó kúrò ní ìlú Minneapolis ní orílẹ̀ èdè US, fi já lulẹ̀ kò ì tíì ye àmọ́ ìwádìí ti bẹ̀rẹ̀.

Èrò mẹ́rìndínlọ́gọ́rin ló wà nínú ọkọ̀ òfurufú náà nígbà táwọn òṣìṣẹ́ sì jẹ́ mẹ́rin.

Àwọn èrò méjìdínlógún ni wọ́n gbé lọ sí ilé ìwòsàn fún ìtọ́jú.

Flint, nígbà tó ń sọ̀rọ̀ ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ Ajé kan sáárá sáwọn òṣìṣẹ́ àjọ tó ń mójútó ìṣẹ̀lẹ̀ pàjáwìrì fún bí wọ́n ṣe ri dájú pé ẹnikẹ́ni kò pàdánù ẹ̀mí wọn nínú ìjàmbá náà.

Àjọ tó ń rí sí ètò ìrìnnà òfurufú ní Amẹ́ríkà sọ pé ẹ̀ka iléeṣẹ́ ìrìnnà òfurufú Delta, Endeavor Air ló ń ṣàmójútó ọkọ̀ òfurufú náà.

Flint ṣàlàyé pé èèyàn méjìlélógún ló jẹ́ ọmọ orílẹ̀ èdè Canada nígbà tí àwọn yóòkù jẹ́ ọmọ orílẹ̀ èdè mìíràn.

Wọ́n ti pápákọ̀ òfurufú náà lẹ́yìn ìṣẹ̀lẹ̀ náà àmọ́ tí iṣẹ́ bẹ̀rẹ̀ padà ní pápákọ̀ òfurufú Toronto Pearson nǹkan aago márùn-ún ìrọ̀lẹ́ ní Canada.

Àjọ tó ń rí sí ààbò ètò ìrìnnà ní Canada ní àwọn ti bẹ̀rẹ̀ ìwádìí láti mọ ohun tó ṣẹlẹ̀ lórí ìjàmbá ọ̀hún.

Níṣe ni àwọn ojú pópó ìrìnnà àwọn ọkọ̀ òfurufú máa wà ní títì pa fún ọ̀pọ̀ ọjọ́, tí wọ́n sì ti sọ fún àwọn èrò pé kí wọ́n retí ìdíwọ́ díẹ̀díẹ̀ lórí ìrìnàjò wọn.

Ọ̀gá àgbà àjọ tó ń mójútó ìjàmbá iná ní Toronto Pearson, Todd Aitken sọ pé ojú ọ̀nà náà dá, kò sí sí àpẹẹrẹ ìjì líle.

Èyí yàtọ̀ sí ìjábọ̀ tó ti ṣaájú wáyé tẹ́lẹ̀ pé ìjì líle wà lásìkò ìjàmbá náà.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Fídíò tó gba orí ayélujára ṣàfihàn báwọn èèyàn ṣe ń sá jáde nínú ọkọ̀ òfurufú tó ti dojú bolẹ̀ náà, táwọn òṣìṣẹ́ panápaná sì ń fọ́n omi ọṣẹ si.

"Ọkọ̀ òfurufú wa já lulẹ̀, ó dojú bolẹ̀," ọ̀kan lára àwọn èrò tó wà nínú ọkọ̀ náà sọ nínú fídíò kan tó ṣe.

Fídíò náà ṣàfihàn báwọn òṣìṣẹ́ pápákọ̀ òfurufú náà ṣe ń ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ láti jáde.

"Ọ̀pọ̀ èèyàn lọ jọ pé wọ́n wà ní àláfíà. Gbogbo wa ti ń jáde, èéfín gbalẹ̀," àwọn nǹkan tó ń sọ nínú fídíò náà nìyí.

Gómìnà Minnesota, Tim Walz sọ pé òun dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn tó tètè jí gìrì sí ìṣẹ̀lẹ̀ náà àtàwọn akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ tó wà níbẹ̀.

Lẹ́yìn ìjàmbá náà, ibi àtiwọlé àti àtijáde ṣàfihàn bí wọ́n ṣe wọ́gilé ọ̀pọ̀ ìrìnnà. Ọ̀pọ̀ àwọn èrò sọ fún BBC pé àwọn ti há sí Toronto fún ọ̀pọ̀ ọjọ́ báyìí.

Láti bíi ọjọ́ díẹ̀ sẹ́yìn ni ojú ọjọ́ ti ń ṣe ìdíwọ́ fún pápáks òfurufú Toronto Pearson bí yìnyín àti ojú ọjọ́ tó tutù ṣe ń ṣọṣẹ́ ní Ontario.

CBS, alábàáṣiṣẹ́ BBC ní US ti ṣáájú sọ pé tìnyín yóò wà lójú ọjọ́ lásìkò tí ìjàmbá náà wáyé.

Ìjàmbá ọkọ̀ òfurufú yìí ni ẹ̀kẹrin irú rẹ̀ tó ń wáyé ní ẹkùn North America ní oṣù kan sẹ́yìn tó fi mọ́ ìkọlù ọkọ̀ òfurufú ológun àti ti ọkọ̀ èrò tó forí sọ ara wọn lójú òfurufú lẹ́bàá Washington DC níbi ti èèyàn mẹ́tàdínláàádọ́rin ti jáde láyé.