Ìdí tí àjọ DSS fi ya wọ ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin Eko lọ́jọ́ Ajé

Aworan awọn ọmọ ile aṣofin ipinlẹ Eko

Oríṣun àwòrán, Mojisola Meranda/X

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ajọ ọtẹlẹmuyẹ DSS ti sọ pe awọn ko ṣadeede ya wọ ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Eko lọjọ Aje ṣaaju ijokoo ile.

Ajọ naa sọ adele akọwe ile igbimọ aṣofin naa, Họnọrebu A.T.B. Ottun lo fi iwe pe ajọ naa lati pese abo fun ile.

Laarọ ọjọ Aje ọjọ kẹtadinlogun oṣu Keji ni fọnran to ṣafihan bii awọn oṣiṣẹ ajọ DSS ti yabo ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Eko duro wamu wamu nile aṣofin ipinlẹ Eko ti ọpọ ọmọ ile ko si rọna wọle to fi mọ Olori ile tuntun Họnọrebu Mojisola Lasbat Meranda.

Adele akọwe ile naa fun ra rẹ sọ ninu iwe to fi ranṣẹ si ajọ DSS pe ile lo ranṣẹ pe ajọ naa lati pese abo.

Amọ, o ni ile ko sọ fun wọn pe ki wọn wa ti awọn ọfiisi pa nile aṣofin ipinlẹ Eko.

Gẹgẹ bi ohun to wa ninu lẹta ti adele akọwe ile kọ si DSS lọjọ kẹrinla oṣu Keji yii, Họnọrebu Ottun fi to ajọ DSS atawọn ileeṣẹ eleto abo mii nipinlẹ Eko lati pese abo to peye fawọn aṣofin tori awọn n wu gbọ pe awọn n gbero lati fi ipa da Olori ile ti wọn yọ nipo, Mudashiru Obasa, pada sipo lọjọ Iṣẹgun ọjọ kejidinlogun oṣu Keji yii.

O ni ile sọ fun ajọ DSS wi pe nnkan tawọn eeyan naa n gbero le ṣakoba fawọn ọmọ ile aṣofin.

Ọga agba ajọ DSS nipinlẹ Eko ni adele akọwe ile aṣofin kọ iwe naa si atawọn ileeṣẹ eleto abo mii nipinlẹ Eko.

Họnọrebu ṣalaye ninu lẹta wi pe ''a n fẹ ki ajọ DSS pese abo to peye nile aṣofin ipinlẹ Eko lati ọjọ Aiku ọjọ kẹrindinlogun.

A si fẹ kawọn oṣiṣẹ ajọ DSS to maa wa si ile igbimọ aṣofin pọ si ki wọn si maa wa nibẹ lojoojumọ bayii.''

Lẹyin o rẹyin, awọn aṣofin ati olori ile pada jokoo, nibi ijokoo naa si ni wọn ti kede wi pe gbọin gbọin lawọn wa lẹyin Meranda.