Àìsàn sémìí-sémìí, Asthma ló pa Yetunde, mo kan gé e wẹ́lẹ̀wẹ̀lẹ nítorí ẹ̀rù tó bà mí ni – Ààfáà Mohammed Bello

Mohammed Bello ati Yetunde Lawal ti wọn pa

Oríṣun àwòrán, Kwara state police

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Alfa ilu Ilorin ti ọwọ ọlọpaa tẹ lori ẹsun pe oun lo ṣeku pa ọrẹbinrin rẹ, Mohammed Bello, ti sọ pe aisan semi-semi lo pa oloogbe naa, kii ṣe oun.

Ṣaaju ni ọlọpaa ti kọkọ fi ṣikun ofin mu Bello, lẹyin ti wọn ṣawari ibi to kun Hafsoh Lawal, to ni oun pade loju opo Facebook si.

Ninu fidio ifọrọwerọ kan to gba ori ayelujara ni afurasi naa ti sọ pe oun kun ẹya ara oloogbe naa lọna ṣe ọrọ iku rẹ ni oku oru.

Hafsoh Lawal, to jẹ olukọ nile ẹkọ alakọbẹrẹ kan lo di awati lọjọ Aje to kọja lẹyin to kuro nibi ayẹyẹ isọmọlorukọ kan, lati lọ pade afurasi naa to pade loju opo Facebook.

Lẹyin ti ko pada wale mọ lawọn mọlẹbi rẹ fi ọrọ naa to ileeṣẹ ọlọpaa leti ti iwadii si bẹrẹ.

Lẹyin ti ọwọ ọlọpaa tẹ afurasi naa tan, o ni oun kọ mọ bi oloogbe naa ṣe rin, eyii to mu ki ọlọpaa lọ yẹ ile rẹ wo ti wọn si ba ẹya ara oloogbe ọhun nibẹ.

Nigba to n sọrọ lori iku Hafsoh, Bello sọ pe oun kọ loun gbẹmi rẹ.

Bello ṣalaye pe ọrẹbinrin oun ni ni Hafsoh, nigba to dele oun lo sọ pe ebi n pa oun, ti oun si jade lọ lati ra ounjẹ fun.

Gẹgẹ bi afurasi naa ṣe sọ, o ni nigba ti oun yoo fi paa dele, oun ba to n mi gulegule, ti eemi rẹ ko si jake.

O ni "ọrẹbinrin mi ni Hasoh, ori Facebook ni a ti pade, emi kọ ni mo pa, akoba ni ọrọ yii jẹ fun mi.

"Nigba to dele mi, o sọ pe oun ko tii jẹun, mo si jade lọ lati lọ ra ounjẹ fun, nigba ti mo maa fi pada dele, niṣe lo n mi gulegule."

Bello sọ pe oloogbe naa sọ fun oun ṣaaju pe oun ni arun semi-semi, ati pe niṣe loun ge ẹya ara reo si wẹwẹ ki akara iṣẹlẹ naa ma ba tu sepo.

O ni "ẹru ba mi nigba to dakẹ, mi o le pariwo sita.

"Mo ge ara rẹ si wẹwẹ ti mo si lọ da a si ori akitan nitori mi o mọ ọna mii ti mo le gbe ọrọ naa gba.

"Mi o tii wu irufẹ bayii ri, igba akọkọ mi ree."

Amọ ṣa, nigba ti awọn mọlẹbi oloogbe naa n sọrọ, wọn ni irọ pọnbele ni afurasi naa n pa nitori ọmọ awọn ko ni arun semi-semi ṣaaju iṣẹlẹ naa.