Èsì àyẹ̀wò òkú Abdulkadir Jimoh ti ṣàfihàn ohun tó ṣokùnfà ikú rẹ̀ ní àtìmọ́lé ọlọ́pàá n'Ilorin

Aworan igba ti wọn n sinku Oloogbe Jimoh Olatunji ati igba to wa laye.

Oríṣun àwòrán, Others

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Ayẹwo oku ti wọn ṣe ni Ile-iwosan ẹkọṣẹ iṣegun oyinbo ti ipinlẹ Kwara, ti ṣafihan ohun to fa iku ọkunrin kan, Abdulkadir Olatunji Jimoh, to ku si atimọle ọlọpaa ipinlẹ Kwara.

Tẹ o ba gbagbe, Jimoh ku si atimọle ọlọpaa n'Ilorin l'ogunjọ oṣu kejila, ọdun 2024, lẹyin ti wọn mu un fun ẹsun pe o jẹ ọga rẹ, Gabriel Sunday, ni owo tiye rẹ jẹ N220,000.

Lati igba naa ni iwadii ti bẹrẹ ni pẹrewu lati mọ ohun to sokunfa iku gendekunrin naa.

Lara awọn iwadii naa ni bi ileesẹ ọlọpaa ṣe ni ki ileewosan ṣe ayẹwo oku; "autopsy" lori oku oloogbe Jimoh.

Kí ni àyẹ̀wò òku gbé jáde pé ó pa Abdukadir Olatunji Jimoh?

Oju ewe akọkọ iwe ayẹwe oku naa ree
Àkọlé àwòrán, Oju ewe akọkọ iwe ayẹwe oku naa
Oju ewe to kede esi ayẹwo oku Jimoh Olatunji ree

Ẹdà ayẹwo naa to tẹ BBC Yoruba lọwọ, sọ pe, Jimoh, ẹni ọdun marundinlogoji (35), ku nipasẹ awọn arun wọnyii: 'Acute ventricular failure and hypertensive heart disease).

Itumọ eyi ni pe iku naa ni i ṣe pẹlu ki ọkan eeyan da iṣẹ silẹ ati ki eeyan ni aisan ọkan to ni i ṣe pẹlu ẹjẹ riru.

Ninu esi ayẹwo ọhun ni wọn kọ orukọ awọn dokita to ṣe e si, iyẹn Dokita O.L Lawal , ti wọn lo ṣe e niwaju Dokita Ismail Olayiwola.

Wọn ni ayẹwo oku naa ṣoju ẹgbọn Oloogbe ti orukọ tiẹ n jẹ Jimoh Oladimeji.

Gẹgẹ bi alaye ti Dokita Lawal ṣe, o ni awọn eyin ẹnu oloogbe naa pe, o si wa ni ipo to dara.

Eekanna ọwọ ati ika ẹsẹ rẹ si duro deede pẹlu bo ṣe sọ.

Ìdílé Olóògbé wọ́ iléeṣẹ́ ọlọ́pàá lọ síIé ẹjọ́

Wayi o, idile Oloogbe naa ti wọ ileeṣe ọlọpaa lọ sile ẹjọ giga ilu Ilorin.

Ohun ti wọn n beere fun ninu ẹjọ naa ni owo-gba-ma-binu to n lọ si bii 750 million naira.

Ṣaaju ni idile ọhun ti ṣe ifẹhonuhan ati iwọde alaafia, pe awọn ọlọpaa n se makaruru pẹlu esi ayẹwo oku naa.

Wọn ni wọn kọ lati fun awọn ni esi ọhun.

Awọn ẹbi Jimoh kesi gomina ipinle Kwara, Emir ilu Ilorin ati ile igbimọ asofin pe ki wọn da si ọrọ naa.

Ṣugbọn awọn ọlọpaa ti da wọn lohun, pe esi ayẹwo naa wa fun ileejọ ni pato, nitori awọn mọ pe adajọ yoo beere rẹ ti ẹjọ ba de ikorita kan.

Ni bayii, awọn ti mọlẹbi Jimoh pe lẹjọ ni pato ni: Ọga agba ọlọpaa Naijiria, IPO to n ṣe ẹjọ naa, ileeṣẹ eto ilera, Kọmisanna ọlọpaa Kwara to fi mọ dokita to se ayẹwo oku naa ati awọn mi-in.

Kí ni ọlọ́pàá sọ?

BBC kan si Alukoro ọlọpaa ipinlẹ Kwara, Ejire Adetoun Adeyemi, ẹni to sọ pe bẹẹ gẹlẹ ni esi ayẹwo oku naa ri.

Alukoro sọ pe ẹjọ naa ko si nipinlẹ Kwara mọ,wọn ti gbe e lọ si Abuja fun iwadii to peye.

Adetoun ni gbogbo awọn ọlọpaa tọ wa nibẹ nigba ti iṣẹlẹ naa sẹlẹ ni wọn ti wa niluu Abuja bayii.