Nuhu Ribadu sọ̀rọ̀ sí Canada, nítorí wọn kò fún ọ̀gá ológun Naijiria ní físà

Aworan ọga ologun ati Nuhu Ribadu

Oríṣun àwòrán, Nuhu Ribadu/ Defence Headquarters

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Oludamọran pataki fun oriilẹede Naijiria lori eto aabo, Nuhu Ribadu, ti fi ibinu rẹ han si bi orilẹ ede Canada ṣe kọ lati fun olori ologun Naijiria, Ọgagun Christopher Musa ati awọn ọga ṣoja mi-in ni fisa lati wọle si orilẹede naa.

L'Ọjọbọ, ọjọ kẹtala, oṣu Keji ọdun 2025 ni Ọgagun Christopher ṣalaye bi Canada ko ṣe fun un ni fisa lati lọ sibi eto awọn ologun ti wọn pe oun ati awọn ṣọja mi-in si lorilẹede ọhun.

Ọga ṣoja pata naa sọ pe Canada fun idaji ninu awọn to yẹ ko wa nibi eto naa ni fisa, ṣugbọn fun idi ti oun ko tiẹ mọ, wọn ko fun oun ati awọn ikọ oun mi-in rara.

Eto to ni i ṣe pẹlu biba awọn ṣọja to di alaabọ ara nibi ti wọn ti n ja fun ilu wọn, kẹdun, ni olori ogun Naijiria naa fẹẹ lọọ fun ni Canada.

O ṣalaye pe ijakulẹ gbaa ni fisa ti wọn ko fun oun naa jẹ.

Ọgagun Christopher ni iwa ti Canada hu fi han pe wọn ko ri ti Naijiria ro, orilẹede wa si gbọdọ ja fun ori ara rẹ ni, ki wọn ma baa maa fi iwọsi lọ ọ.

Kí Canada bá ara ẹ̀ dà sọ́hùn-ún,àì ní ìbọ̀wọ̀ ni ìwà tí wọ́n hù-Ribadu

Nigba to n sọrọ si ilẹ Canada, Nuhu Ribadu to lọ sibi eto kan naa, fi asiko ti ọrọ kan an sọ fun Canada pe iwa ai ni ibọwọ ni wọn hu.

Oludamọran pataki fun oriilẹede Naijiria lori eto aabo naa sọ pe,''ẹ ṣeun fun igboya ti ẹ ni lati jẹ ka mọ pe Canada ko fun yin ni fisa. Ki wọn ba ara wọn da sọhun-un.

''Bo tiẹ jẹ pe o dun wa, o si fi han pe wọn ko bọwọ fun wa. Mo gba ohun ti ẹ sọ pe a gbọdọ tun orilẹede wa ṣe, a si gbọdọ ṣee daadaa ''

Bẹẹ ni Nuhu Ribadu wi.

Oriṣiiriṣii ọrọ lo ti n jẹ jade nipa ohun to ṣẹlẹ yii, ọpọ eeyan lo n sọ pe o daa bi ọga ologun ṣe jẹ ki aye mọ ohun to ṣẹlẹ.

Bẹẹ ni wọn tun n sọ pe eyi yoo mu ki awọn olori orilẹede Naijiria mọ pe o yẹ kawọn naa tun ilu awọn ṣe.

Laipẹ yii ni Canada ṣe atunṣe si bi awọn arinrinajo ṣe n ya wọ ilu wọn. Atunṣe naa wa fun lati din iye eeyan to fẹẹ maa ti okeere waa gbe ni Canada ku.

Wo ìdí tí Canada fi lè má jẹ́ kí o wọ orílẹ̀èdè wọn

*Ààbò:

*Ṣiṣe alamí

*Igbiyanju lati ditẹ gba ijọba

*Iwa janduku

*Wiwa ninu ẹgbẹ agbesunmọmi

*Iwa ọdaran nipa ogun

*Hihu iwa ika si awujọ eeyan

*Bi o ba wa ninu ijọba ti o si n gbabọde

*Kiko owo ilu rẹ lọna èrú lọ si Canada, fifi iṣẹ gidi boju nigba ti eeyan n ṣiṣẹ ti ko ba ofin mu labẹnu.

*Ilera ti ko pe

*Bi o ba bi aisan to le ran araalu

*To le fi ẹmi wọn sinu ewu

*To le ko wọn si idaamu itọju

*Bi o ko ba ni owo gidi to le gbọ bukaata rẹ ati tawọn ẹbi rẹ ti o fẹẹ ko wọ Canada.