'Ẹ̀yin gómìnà wa, ẹ fura o! Àwọn jàndùkú darandaran àtàwọn agbébọn tún ti ń ṣọṣẹ́ nílẹ̀ Yorùbá'

Gomina Sanwo-Olu, Seyi Makinde ati Dapo Abiodun

Oríṣun àwòrán, Facebook

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Awọn alufaa ijọ Aguda ti a mọ si 'Catholic Bishops'', ẹka ti Ibadan, nipinlẹ Oyo, ti rọ awọn gomina ilẹ Yoruba lati sowọpọ, ki wọn le ṣegun awọn agbebọn to n wọ ilẹ Yoruba wa, paapaa julọ, lagbegbe Oke Ogun.

Ipe naa jade lẹyin ipade ọlọjọ meji to waye n'Ibadan, nibi ti awọn alufaa naa ti ke gbajare pe ikọlu awọn daran-daran, ijinigbe, idigunjale ati awọn iwa ọdaran mi-in ti n pada si ipinlẹ Oyo ati Ogun.

Eyi ko yọ awọn ilẹ Yoruba yooku silẹ bi wọn ṣe sọ.

Alaga awọn Biṣọọbu ijọ Aguda n'Ibadan, Archbishop Gabriel Abegunrin, ṣalaye ninu atẹjade to waye lẹyin ipade naa, pe idunkooko ti n waye bayii lati ọwọ awọn agbesunmọmi si awọn eeyan ilẹ Yoruba.

Bi eyi yoo ba dopin, afi ki awọn gomina mẹfa to wa nilẹẹ Yoruba pese irinṣẹ to tọ fun awọn agbofinro, ṣe afikun owo oṣu wọn, ki wọn si wa ọna ti wọn yoo fi hu awọn agbebọn to n sa pamọ silẹ yii jade.

Wọ́n jí ìbátan mi gbé láàárín Ibadan sí Iwere-ile, mílíọ̀nù rẹpẹtẹ la san kí wọ́n tóó yọ̀nda rẹ̀

Nigba to n ṣalaye bi ijinigbe ṣe ti gogo to lasiko yii, paapaa lagbegbe Oke Ogun, Alufaa Abegunrin sọ nipa ibatan rẹ obinrin ti wọn jigbe.

" Ai si aabo ti pọ gan-an l'Oke-Ogun, wọn ji ibatan mi obinrin gbe nigba to n pada lọ si abule, n'Iwere-Ile lati Ibadan.

''Ọjọ marun-un lo lo lọdọ wọn ki wọn too fi i silẹ lẹyin ti a ti san miliọnu naira rẹpẹtẹ.

''Bẹẹ ni wọn tun ji ọkunrin kan gbe labule wa naa, wọn pa a, wọn tun pa aburo rẹ to fẹẹ lọọ gbe oku rẹ.

''Awọn ṣọja ati agbofinro yooku ti wọn tun lọọ pe, awọn eeyan yii maa n pa wọn.

''Awọn agbẹ ko le lọ soko tẹlẹ, boya wọn ti n le maa lọ bayii.

''Mo ṣaa n beere ni, pe ki lo de ti ijọba ko le kapa aabo niluu to kere to Iwere-Ile bẹẹ yẹn.

Bi ẹ ba lọ si ilu Saki naa, wọn pa awọn eeyan nibẹ, o ti le debi pe awọn eeyan ko fẹẹ ran awọn ọmọ wọn lọ sileewe mọ''

Alufaa Abegunrin lo ṣalaye bẹẹ.

Tẹ o ba gbagbe, loṣu to kọja ni Gomina ipinlẹ Oyo, Seyi Makinde, ke gbajare pe awọn agbesunmọmi to sa kuro lapa Ariwa ti n wọ ilẹ Yoruba, lati huwa laabi ọwọ wọn.