'Àbá ìṣúná 2025: Ó ṣeé ṣe kí ohun tí aráàlú ń fẹ́ má rí bẹ́ẹ̀'

Oríṣun àwòrán, Nigerian Presidency
Lẹyin ti Aarẹ Bola Tinubu ti gbe aba iṣuna ọdun 2025 lọ sile igbimọ aṣofin ti wọn si ti buwọlu u ni awọn awoye lẹka ọrọ aje ti n fi oju inu wo o.
Aba 54.99 trillion naira naa lo jẹ afikun iye ti aarẹ gbe lọ sile igbimọ lakọkọ.
Afikun naa gẹgẹ bi wọn ṣe wi, yẹ ko jẹ anfaani fun ọrọ aje Naijiria.
Ṣugbọn pẹlu aito owo ti a mọ si 'deficit', to pọ ninu aba yii, o ṣee ṣe ko nipa aburu lara ọrọ aje, nitori Naijiria yoo ni lati maa yawo ṣe awọn nnkan to yẹ.
Wọnyi ni awọn ohun to le fa ki aba iṣuna naa ma ri bi araalu ṣe n ro pe yoo ri lẹka ọrọ aje, gẹgẹ bi onimọ nipa ọrọ aje ati amofin, Bisi Iyaniwura ṣe ṣalaye fun BBC.
Àìlè pèsè ohun tí a nílò, ẹ̀yáwó ṣe nǹkan amáyédẹrùn lè ṣàkóbá fún ọrọ̀ ajé
Amofin Bisi Iyaniwura nigba to n ṣatupalẹ aba iṣuna ọdun 2025, ṣalaye pe jijẹ ọwọn ninu ọpọ ni aba yii.
O ni bi afikun ṣe ba owo iṣuna naa, niṣe lo yẹ ko ran ọrọ aje lọwọ, ṣugbọn Naijiria ko ni ọrọ aje kan pato to duro ire.
''Nibi ti nnkan ba ti ri bo ṣe yẹ ko ri, bi wọn ba ṣe afikun owo iṣuna bayii, o yẹ ko pese afikun iṣẹ ko si jẹ ki owo pọ si lẹka ọrọ aje ni.
''Ṣugbọn o ṣeni laaanu pe ọpọ nnkan ti yingin nibi.
''Niṣe la gbe ọrọ aje wa si ori kiko nnkan wa lati oke okun. Itumọ eyi ni pe a ko le mọ ọn lara pe wọn tiẹ fi kun owo iṣuna 2025.
''Kaka bẹẹ, niṣe la tun maa maa pese owo fun ọrọ aje awọn ti a n ra nnkan lati ọdọ wọn.
''Ẹ si ma gbagbe, pe nibi ti aito ba ti wa, afi ka maa ya owo ti a o maa fi gbọ ohun ti a ba fẹẹ ṣe gẹgẹ bii orilẹede. Bi a ba n yawo tun orilẹẹde mi-in ṣe, ṣe awijare kankan wa fun iru iwa bẹẹ.
''Looootọ ni ijọba loun ko ni i fi kun owo ori, ṣugbọn wọn n fi kun owo ori ọja , itumọ rẹ naa ni pe wọn n fi owo kun owo ori naa ni.
''Eyi yoo mu igbesi aye irọrun nira diẹ, nigba ti araalu ba n nawo ju iye ti wọn n na lori awọn nnkan ti wọn nlo tẹlẹ lọ.
Fun idi eyi, aba iṣuna 2025 yii le ma ri bi araalu ṣe ro pe yoo ri rara''
Bayii ni Amofin Bisi Iyaniwura ṣalaye
Ilé aṣòfin buwọ́lu àbá ìsúná 2025

Oríṣun àwòrán, Others
Ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin Nàìjíríà ti buwọ́lu àbá ìsúná ọdún 2025.
Níbi ìjókòó ilé tó wáyé l'Ọjọ́bọ̀, ọjọ́ Kẹtàlá, oṣù Kejì ọdún 2025 ni àpapọ̀ ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin àgbà àti ilé aṣojúṣòfin ti buwọ́lu àbá ìsúná tí iye rẹ̀ jẹ́ ₦ 54.99trn náà.
Àtúpalẹ̀ àbá ìsúná náà ṣàfihàn pé ₦3.65trn ni wọ́n yà fún àwọn iléeṣẹ́ àti lájọlájọ ìjọba, tí iye tí wọn yóò fi máa san gbèsè sì jẹ́ ₦14.32trn.
Bákan náà ni owó tí wọ́n fi máa ṣe ìjọba jẹ́ ₦13.64trn nígbà tí iye tó wà fún àwọn àkànṣe iṣẹ́ sì jẹ́ ₦23.96trn.
₦13.08trn ni iye tí àbá ìsúná náà fi dín sí owó tí yóò wọlé fún ìjọba lọ́dún 2025.
Lọ́jọ́ Karùn-ún, oṣù Kejì, ọdún 2025 ni ààrẹ Bola Ahmed Tinubu mú àlékún bá àbá ìsúná náà di ₦54.2trn láti ₦49.7trn tó gbé síwájú ilé náà ní ọdún tó kọjá.
Tinubu ní àlékún tó bá owó tó ń wọlé sí àpò ìjọba ni wọ́n ṣe fi kún àbá ìsúná náà.
Nínú lẹ́tà kan tí Tinubu fi ránṣẹ́ sí ilé aṣòfin àpapọ̀, tí ààrẹ ilé aṣòfin àgbà, Godswill Akpabio kà síta ni Tinubu bèèrè fún àlékún ọ̀hún.
Ní oṣù Kejìlá, ọdún 2024 ni Tinubu gbé àbá ìsúná ọdún 2025 síwájú ilé náà èyí tó pè ní àbá ìsáná ṣíṣe àrídájú àláfíà àti mímú ìgbé ayé rọrùn.
Àbá ìsúná yìí ni ìkejì tí Tinubu máa gbé síwájú ilé aṣòfin, èyí tó pọ̀ ju ti ọdún 2024, láti ìgbà tó ti gba àkóso ìjọba Nàìjíríà lọ́dún 2023.
Orí títa àgbá epo rọ̀bì jálà kan ní $75 àti pípèsè mííọ̀nù méjì jálà epo rọ̀bì ni ìjọba gbé àbá ìsúná náà lé.
Tinubu ṣàlàyé pé ẹ̀yàwó láti abẹ́lé àti lọ́wọ́ àjọ àgbáyé ni wọ́n fi máa rí owó tí wọ́n fi ma kún iye tó dín níbi àbá ìsúná náà.
Ẹ̀wẹ̀, alága tó ń rí sí ọ̀rọ̀ àbá ìsúná nílé aṣòfin, Abubakar Bichi nígbà tó ń tẹ́ pẹpẹ àbá ìsúná ọ̀hún fún àyẹ̀wò ní àwọn ti ṣe ìpàdé pẹ̀lú ìgbìmọ̀ tó ń rí sí ààtò ọrọ̀ ajé fún ìjọba tí àwọn sì jọ jíròrò lórí àbá ìsúná náà.
Bichi ní ó pẹ́ kí ìjọba àpapọ̀ tó tẹ́ pẹpẹ àbá ìsúná síwájú ilé aṣòfin, tó sì rọ ìjọba láti máa gbé àbá ìsúná náà sílé nígbà tó bá ku oṣù mẹ́ta kí ọdún tó parí kí ìtẹ̀síwájú le bá ṣíṣe àbá oní oṣù Kìíní sí oṣù Kejìlá lọ́dọọdún.















