Karim Adeyemi, agbábọ́ọ̀lù ọmọ Naijiria tó ń ran àwọn ọ̀dọ́ lọ́wọ́

Àkọlé fídíò, Karim Adeyemi, agbábọ́ọ̀lù ọmọ Naijiria tó ń ran àwón ọ̀dọ́ lọ́wọ́
Karim Adeyemi, agbábọ́ọ̀lù ọmọ Naijiria tó ń ran àwọn ọ̀dọ́ lọ́wọ́

Ọmọ orilẹede Naijiria ni Karim Adeyemi, ṣugbọn Munich, ni Germany ni wọn bi i si.

Iṣẹ agbabọọlu ni ọdọkunrin ẹni ọdun mẹtalelogun (23) yii yan an layo, ikọ agbabọọlu Borussia Dortmund ati Germany lo si n gba bọọlu fun.

Adeyemi ṣalaye bo ṣe nifẹẹ orilẹede Naijiria lọkan to, to si fẹran lati maa ri awọn ọdọ orilẹede yii ti wọn ni ẹbun ere alafẹsẹgba naa.

Eyi lo ni o maa n jẹ iwuri foun, to si tori rẹ da ẹgbẹ agbabọọlu ẹlẹyinju aanu kan kalẹ siluu Ibadan, nibi ti wọn ti n ṣawari awọn ọdọ to lẹbun bọọlu gbigba.

Eeyan ẹgbẹrun lọna aadọta (50,000) ni wọn ti ri aanu gba lati ọdọ ajọ ẹlẹyinju aanu Adeyemi to wa n'Ibadan naa, gẹgẹ bi akọsilẹ ṣe sọ.

Adeyemi Karim gba awọn oṣiṣẹ to n sanwo oṣu fun, ti wọn si n ti ipasẹ rẹ ṣe ohun rere.

Awọn ọdọ fẹran rẹ fun agbekalẹ yii, bẹẹ si ni awọn agba naa n ṣadura fun un.