Àwọn ààfáà faraya níbi àdúrà Fìdáù Yetunde tí wọ́n ní ààfáà kan ṣekúpa n'Ilorin

Awon aafaa nibi adua Fidau naa, Oloogbe Yetunde ati Abdurahman ti wọn mu fun iku rẹ.

Oríṣun àwòrán, BBC/Kwara Police

Àkọlé àwòrán, Awon aafaa nibi adua Fidau naa, Oloogbe Yetunde ati Abdurahman ti wọn mu fun iku rẹ.
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 6

Adua Fidau fun Oloogbe Hafsah Yetunde Lawal, waye lonii nilee wọn, Ile Adefalu, Ojuẹkun, n'Ilọrin, ipinlẹ Kwara.

Nibi adua Fidau naa ni awọn aafaa ti rọjo epe le ẹni to pa a lori, ti wọn ke Suraa Tabatiada fun un.

awọn afaa naa faraya to bẹ ẹ gẹ ti wọn fi awọn ẹsẹ Kurani kan sọrọ odi si gbogbo awọn to lọwọ ninu iku arabinrin naa.

Tẹ o ba gbagbe, Hafsah Yetunde Lawal, ni awọn kan n tọka iku rẹ si Aafaa kan ti orukọ rẹ n jẹ Abdurahman Muhamadu Bello, n'Ilọrin; ti wọn ni o kun oku rẹ wẹlẹwẹlẹ.

Lẹyin ọjọ kẹrin ti wọn ti n wa ọmọ naa ni aṣiri ohun to ṣẹlẹ too tu.

Niṣe ni ẹkun n pe ara wọn ran niṣẹ nibi eto adua Fidau naa, awọn eeyan n sun ẹkun asungba, ti kaluku si n beere fun idajọ ododo.

Nigba ti wọn fi ẹdun ọkan wọn han, awọn obi Oloogbe, Ọgbẹni Lawal ati iyawo rẹ, Taibat, sọ pe akọbi awọn ni Yetunde.

Wọn ṣalaye pe ọmọ to ku yii ki i rin irinkurin, ko si ni iwa palapala lọwọ.

Awọn obi Yetunde sọ pe koda, awọn ti mọ ọkọ afẹsọna rẹ, awọn si ti n gbero lati ṣe igbeyawo fun un lọdun yii ki wọn to o fi i da awọn loro.

Awọn obi Oloogbe ni idajọ ododo nikan lo ku tawọn n reti lati ọdọ ijọba.

Adua Fidau fun Oloogbe Hafsah Yetunde Lawal

Abdurahman ti jẹ́wọ́- Ọlọpaa Kwara

Abdurahmon Bello, gbe ike to rọ ẹjẹ Yetunde si dani pẹlu bata Oloogbe naa ni ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Kwara

Oríṣun àwòrán, Kwara Police

Àkọlé àwòrán, Abdurahmon Bello, gbe ike to rọ ẹjẹ Yetunde si dani pẹlu bata Oloogbe naa.

Alukoro ọlọpaa ipinlẹ Kwara, DSP Ejirẹ Toun Adeyẹmi, ti fidi ẹ mulẹ, pe Abdurahman Bello, afurasi lori iku naa ti jẹwọ ẹṣẹ rẹ nileeṣẹ ọlọpaa.

Ninu atẹjade ti Alukoro fi sita lo ti fidi eyi mulẹ.

DSP Ejide sọ pe Abdurahman Muhamadu ṣalaye pe oun pa Yetunde lati fi ṣe oogun owo ni.

O tẹsiwaju pe nigba ti awọn ọlọpaa de ile afurasi naa, wọn ba ẹjẹ Oloogbe naa ninu rọba to rọ ọ si.

Wọn tun ba ọwọ rẹ mejeeji to ti ge, wọn ri ada ati ọbẹ to fi ṣiṣẹ buruku naa.

Ẹbí Yetunde tí wọ́n rí òkú rẹ̀ nílé Àáfà Abdurahman n'Ilorin ń bèèrè ìdájọ́ òdodo

Aworan Oloogbe Hafsah Yetunde Lawal

Oríṣun àwòrán, Hafsah Yetunde Lawal

Ẹbi oloogbe Hafisha Yetunde Lawal ti wọn sekupa ni ilu Ilọrin ipinlẹ Kwara ti beere fun idajọ ododo lori iku ọmọ wọn.

Lasiko to n ba aṣoju kọroyin ile iṣẹ wa BBC Yoruba sọrọ ni ile rẹ ni agbegbe Adefalu ojuẹkun Ilọrin, baba oloogbe naa Ọgbẹni Lawal sọ pe, inu ile ni ọmọ oun wa ni ibi iṣọmọ lorukọ ṣaaju asiko ti iṣẹlẹ laabi yii waye.

O fikun pe, ṣadeede ni ẹnikan pe e lori ẹrọ ibanisọrọ pe ko wa ba oun nile ni agbegbe Offa Garage ni ilu Ilọrin.

Baba olóògbé naa ni ogun lo fi ba ọmọ oun sọrọ lori ẹrọ ibanisọrọ tori lori ẹrọ ayelujara Facebook ni wọn ti pade ati pe wọn o si ti ri ara wọn ri.

Aburo Baba oloogbe naa Ọgbẹni Sikirulahi Jonkto fi idi iṣẹlẹ naa mulẹ fun BBC Yoruba pe, afurasi to ti wa latimọle ọlọpaa bayii, ọdọ to jẹ akọrin ti orukọ rẹ njẹ Abdurahman Muhamadu Bello tan Yetunde Lawal wọ inu ile rẹ o si kun un wẹlẹwẹlẹ sinu rọba ike ọda.

Aworan iya oloogbe naa Arabinrin Toibat Lawal
Aworan awọn to n kẹdun nile oloogbe

Iya oloogbe naa Arabinrin Toibat Lawal rọ ijọba ipinlẹ Kwara ati ajọ ọlọọpa ipinlẹ Kwara lati se idajọ ododo lori ọrọ naa.

Yetunde Lawal Hafsah ni wọn ni o wa ni ipele asekagba ni ile ẹkọ giga olukọni ti ilu Ilorin.

Bakan naa ni a gbọ wi pe oloogbe ọhun n mura lati ṣe igbeyawo ninu ọdun yii.

Ọpọ awọn olubanikẹdun lo wa ni ile oloogbe naa ni Adefalu ojuẹkun Ilọrin.

Wọ́n rí òkú Yetunde nílé Ààfá Abdurahman lẹ́yìn ọjọ́ kẹ́rin tí wọ́n ti ń wá a n'Ilorin

Oloogbe Hafsah Yetunde Lawal

Oríṣun àwòrán, Sikirulai Ande

Àkọlé àwòrán, Oloogbe Hafsah Yetunde Lawal

Kayeefi ṣi ni iku ojiji to pa akẹkọọbinrin ileewe Olukọni agba nipinlẹ Kwara, Lawal Hafsah Yetunde ṣi n jẹ fun awọn eeyan niluu Ilọrin.

Yetunde ni a gbọ pe kinni kan ko ṣe e nigba to jade kuro nile wọn lagbegbe Adefalu, Ilọrin, lọjọ kẹwaa, oṣu Keji ọdun 2025 yii.

Ṣugbọn nigba to to akoko lati pada wale, awọn obi rẹ ko ri i.

Wọn bẹrẹ si i wa ọmọbinrin naa, wọn si fi to ileeṣẹ ọlọpaa leti.

Wiwa ti wọn n wa Yetunde Lawal ko so eso rere, afi lẹyin ọjọ kẹrin ti wọn ni wọn ba oku rẹ nile Aafaa kan lagbegbe Offa Garage, n'Ilorin.

Abdurahman Muhamadu Bello ni wọn pe orukọ aafaa naa.

Ọjọ Ẹti ti ayajọ ololufẹ waye ni wọn ri oku naa, eyi ti i ṣe ọjọ kẹrin ti wọn ti n wa a.

Ta a ni Ààfáà Abdurahman Muhamadu Bello tí wọ́n bá òkú Yetunde nílée rẹ̀?

Oloogbe Hafsah Yetunde Lawal

Oríṣun àwòrán, Sikirukai Ande

Àkọlé àwòrán, Oloogbe Hafsah Yetunde Lawal

Ọmọ agbegbe Idi Isin, Isale Koto, n'Ilorin ni Aafaa Abdurahman Muhamadu Bello.

Ohun ti a gbọ ni pe gbajugbaja aafaa nla kan ni baba rẹ ti wọn mọ si Muhammadu Bello, n'Ilorin, baba naa ti di oloogbe bayii.

Bakan naa la gbọ pe gbajumọ ni afurasi yii naa lagbegbe rẹ.

Ṣugbọn ohun to le da oun ati Oloogbe Yetunde pọ, ki wọn too ba oku rẹ nile ọkunrin yii ko ti i fi oju han lasiko ti a n ko iroyin yii jọ.

Ẹnikan to ba BBC sọrọ ninu ẹbi Oloogbe, Sikirulai Ande, sọ pe afurasi naa ti wa ni atimọle ọlọpaa.

Kí ni ọlọ́pàá Kwara wí?

DSP Ejirẹ Toun Adeyẹmi, Alukoro ọlọpaa ipinlẹ Kwara, fidi ẹ mulẹ pe ileeṣẹ ọlọpaa ti gbọ si iṣẹlẹ iku Omidan Yetunde Hafsah Lawal.

O ni lọjọ kọkanla, oṣu Keji ọdun 2025 ni baba ọmọ naa lọọ fi to teṣan ọlọpaa ẹkun Oja-Oba leti, pe awọn n wa Yetunde.

Alukoro sọ pe ẹsẹkẹsẹ ni iwadii ti bẹrẹ, ti awọn ọlọpaa dọdẹ nọmba rẹ, ti wọn si gbabẹ mu afurasi yii.

Ni bayii, wọn ti taari ẹjọ naa si ẹka iwadii abẹnu, bẹẹ ni bo ba ṣe n lọ yoo maa de etigbọọ araalu bi Alukoro ọlọpaa Kwara ṣe sọ.