'Mo lè kú láàárìn oṣù mẹ́ta pẹ̀lú bí Trump ṣe dáwọ́ ìrànwọ́ àjọ USAID dúró lórí oògùn ìtọ́jú àrùn HIV'

Laipẹ yii ni Aarẹ ilẹ America, Donald Trump pẹlu oludamọran pataki rẹ lorii bi wọn yoo ṣe maa ṣọ owo America na, Elon Musk, kede pe awọn yoo fagile ajọ Oluranlọwọ agbaye;USAID.
Ajọ naa lo wa fun iranwọ ọlọkan-o-jọkan, paapaa lẹka ilera fun awọn orilẹede agbaye.
Ọkan pataki lara ibi ti ọwọ aanu USAID si de ni ọdọ awọn to n gbe ile aye pẹlu arun ko gboogun, HIV.
Awọn eeyan naa n ri oogun ati anfaani iwosan irọrun gba lati ipasẹ USAID ti Trump fẹẹ fagile.
Eyi lo mu awọn eeyan to n gbe pẹlu arun naa ke gbajare, wọn ni bii ẹni to de pakute iku silẹ, to fẹ kawọn ko si i ni bi wọn ba fi le fagile USAID.
Àárín ìyè àti ikú ni mó wà bayii -Elvis
Ọkunrin kan,Mike Elvis Tusubira, ọmọ orilẹede Uganda to ni arun HIV to si n ṣiṣẹ ọkada wiwa, sọ pe ẹmi oun ko dè mọ.
O ni o ṣee ṣe koun ku laaarin oṣu mẹta si asiko yii nitori ohun to ti n ṣẹlẹ lara oun latigba ti igbesẹ ati fopin si USAID ti gbode.
Lati ọdun 2022 lo ti n gbe pẹlu arun ko gboogun.
O ni.
" Ai si USAID ti nipa lara mi ati lori ẹmi mi, mi o mọ ohun to kan ti yoo ṣẹlẹ. Ki ni yoo ṣẹlẹ si mi bayii?"
" Oludanilẹkọọ mi ko si nile iwosan mọ, ki ni yoo ṣẹlẹ si ọmọ ati iyawo mi?"
"Ọjọ iwaju mi ko ye mi mọ, o si ṣee ṣe ki n tiẹ ma ni ọjọ iwaju kankan mọ, nitori ko si ẹwọn apẹfọn fun mi mọ, ko si oogun ti mo nilo fun HIV, ko si kọndọọmu ti n o fi ba iyawo mi lo pọ mọ, ko si nnkan kan mọ rara."
Bẹẹ ni Elvis fi ẹdun ọkan sọrọ fun BBC.
Iyawo Elvis ko ni arun HIV, oogun kan to n dena rẹ lo n lo, eyi si n ti ọwọ USAID wa tẹlẹ, ṣugbọn o ti duro bayii.
Elvis sọ pe latigba ti wọn ti dawọ USAID duro, oun ati iyawo oun ko ti i ra oogun tawọn nilo, eyi to le mu ibaṣepọ awọn wa sopin.
Orilẹede Uganda wa lara awọn ilu mẹwaa akọkọ to n gba iranlọwọ ju lati ọdọ USAID nilẹ Africa.
Gẹgẹ bi ijọba America ṣe wi, Uganda gba $295 million fun ilera ni 2023, lati ọwọ USAID.
Uganda lo tẹlẹ Tanzania to gba $337 million, nigba ti Naijiria gba $368 million.
Yatọ si HIV, ajọ USAID tun n ṣeranwọ fun aisan iba, ikọ ife, arun ẹ̀tẹ̀, eto owo idena iku iya atọmọ lasiko igbẹbi ati bẹẹ bẹẹ lọ.
Ó kan àwọn elétò ìlera náà

Ẹgbẹrun awọn oṣiṣẹ eto ilera ni ai si owo lati ọdọ USAID naa ti kan bayii.
Olutọju ni Shamirah ni Uganda, bi wọn ṣe n pese iwosan ni wọn tun maa n sọrọ itunu fun awọn to ba ni arun HIV atawọn mi-in nileewosan to ti n ṣiṣẹ.
Ṣugbọn latigba ti wọn ti dawọ iranwọ USAID duro, ohun gbogbo ti duro ṣii.
Wọn ti le awọn oṣiṣẹ yooku naa danu.
Ẹka ti wọn ti n tọju ikọ ife ti di ibi idakẹrọrọ, ko si oogun kankan fun wọn.
Abala awọn ọmọ orukan naa n jiya ai si iranwọ.
" A n duro ki aadọrun-un ọjọ ti wọn fi ni ka kuro lẹnu iṣẹ pe ni, emi o ti reti isinmi ojiji ti wọn fun wa yii.
"Wọn o sọ fun wa tẹlẹ, a o tiẹ ṣe gbogbo eto to yẹ ka ṣe ka too kuro lẹnu iṣẹ, a kan daṣẹ duro ni"
Shamira lo sọ bẹẹ.
Ìbẹ̀rùbojo mú wọn ni Malawi

Bakan naa ni ọmọ ṣe ori ni Malawi, iranwọ USAID ti dopin nibẹ naa.
Ni ileewosan Macro Mzuzu Clinic, nibi ti wọn ti n pese itọju oriṣiiriṣii fun awọn to ni HIV, niṣe ni wọn ti ilẹkun ibẹ pa.
Eddah Simfukwe Banda, ọkan lara awọn ara agbegbe ti ọsibitu naa wa, sọ pe wọn ti i pa latigba ti wọn ti paṣẹ pe kawọn oṣiṣẹ dawọ iṣẹ duro.
Koda, pẹlu aṣẹ to ti ẹka idajọ wa l'America, pe ki wọn ṣi jẹ ki wọn ko oogun lọ si awọn ileewosan yii, sibẹ, ohunkohun ko yipada.
Nigba ti ko si oṣiṣẹ ti yoo tilẹ pin oogun ọhun bi wọn ba gbe e de.
Iṣakoso Trump ti sọ pe ipinnu oun ni lati din awọn oṣiṣẹ USAID ku ni ida aadọrun-un (90%)
Nipa iranwọ gbigba, Malawi gba $154 million lọwọ USAID ni 2023, awọn ni wọn wa nipo kẹwaa ninu awọn to n gba iranwọ l'Africa
Orilẹede naa wa lara awọn ilu to kuṣẹẹ ju lagbaaye.
Gẹgẹ bi banki agbaye ṣe wi, wọn ni Malawi wa ninu ewu ijamba to le ṣe wọn lati ilẹ okeere mi-in.
Wọn tun le koju iṣoro ọgbẹlẹ ati ai to òjò.
Obinrin kan, Eddah Simfukwe Banda, ọmọ Malawi, loun ko ni agbekẹlẹ kankan bayii ju ireti ti oun ni lọdọ Ọlọrun lọ.
Obinrin naa ati iyawo ẹgbọn rẹ ni wọn jọ n gba itọju ọfẹ tẹlẹ.
Ikú nípasẹ̀ HIV/ AIDS yóò pọ̀ sí i bí ìrànlọ́wọ́ USAID bá dúrọ
Gẹgẹ bi ajọ UNAIDS ṣe sọ,wọn ni igboro agbaye ko rẹrin-in bayii pẹlu ohun to n ṣẹlẹ yii.
Ni 2023, eeyan 630,000 ni wọn sọ pe wọn ku nipasẹ AIDS atawọn arun to farapẹ ẹ, eeyan 1.5 million lo si tun lugbadi arun tuntun.
Wọn ni bi arun naa ṣe n pọ si i ti dinku tẹlẹ pẹlu iranwọ USAID, ṣugbọn bi wọn ba dawọ iranwọ naa duro, yoo maa pọ si i ni wọn sọ.
"Bi a ba yọwọ iranwọ nla lati ọdọ ijọba America, afojusun wa ni pe alekun yoo ba iku awọn eeyan lati ara AIDS.
Alekun 6.3 million ni iku ti yoo wa lati ara arun ko gboogun"
Adari UNAIDS;Winnie Byanyima, lo ṣalaye bẹẹ fun BBC.
" Arun tuntun to to 8.7 million yoo wa, awọn ọmọ ti yoo padanu obi yoo to 3.4 million.
" Mi o fẹẹ maa sọrọ bi iranṣẹ iku, ṣugbọn iṣẹ ti mo gba ni lati sọ ọ bi mo ṣe ri i"
Bakan naa ni wọn ni ewu to wa ninuu dida oogun HIV duro lagbara pupọ.
Wọn ni o maa n jẹ ki wọn ma le kapa arun naa mọ ni.
Njẹ Africa le tẹri si iranwọ yii?
Atari Ajanaku ki i ṣe ẹru ọmọde ni ọrọ iranwọ USAID.
Fun ọdun gbọọrọ ni wọn ti n ṣe iranwọ, wọn si ti gab ẹmi to le ni miliọnu mẹẹẹdọgbọn (25m) silẹ
"Lọdun to kọja, USAID fun Africa ni $8 billion fun iranwọ, ida 70% rẹ wa fun ilera." Adari eto naa fun Africa, Jean Kaseya, lo sọ bẹẹ fun BBC
Awọn onimọ nipa ilera ti sọ pe yoo ṣoro ki ilẹ Aafrica too le gbe iranwọ yii.
Bi ayipada oju ọjọ si s'\e n ṣe tiẹ pẹlu, ti inawo ilẹ Africa naa n pọ si i, awọn awoye ilera sọ pe yoo daa bi ilẹ Africa naa ba loe ṣe afiku owo eto ilera wọn
Bi wọn ko ba le ṣe ohun ti USAID ti n fi ọdun gbọọrọ sẹ













