Àwọn ọ̀dọ́ jó àgọ́ ọlọ́pàá lẹ́yìn tí wọ́n fẹ̀sùn kàn pé wọ́n pa èèyàn kan sí àgọ́ wọn

Oríṣun àwòrán, Others
Níṣe ni ọ̀rọ̀ di bó ò lọ ko yàgò fún mi ní àgọ́ ọlọ́pàá Ifon, ìjọba ìbílẹ̀ Ose ní ìpínlẹ̀ Ondo lọ́jọ́ Àbámẹ́ta, ọjọ́ Karùndínlógún, oṣù Kejì, ọdún 2025 nígbà tí àwọn ọ̀dọ́ kan lọ dáná sun àgọ́ ọlọ́pàá náà.
Gẹ́gẹ́ bí ìròyìn tó tẹ̀ wá lọ́wọ́, wàhálà bẹ́ sílẹ̀ ní ìlú náà lẹ́yìn táwọn igun ọ̀dọ́ méjì kan fìjà pẹ́ẹ́ta ní àyájọ́ olólùfẹ́ tó wáyé lọ́jọ́ Ẹtì.
Ikọ̀ kan lára àwọn tó ń fa wàhálà náà lọ fi ẹjọ́ sùn ní àgọ́ ọlọ́pàá, táwọn ọlọ́pàá sì mú méjì lára àwọn igun kejì.
Wọ́n ní ìyà táwọn ọlọ́pàá fi jẹ àwọn ọ̀dọ́ méjì tí wọ́n mú náà ṣokùnfà ikú ọ̀kan lára wọn, tí ìkejì sì farapa, tí òun náà wà nílé ìwòsàn níbi tó ti ń gba ìtọ́jú.
Èyí ni wọ́n sọ pé ó fa ìbínú táwọn ọ̀dọ́ sì ṣe ìfẹ̀hónúhàn lọ sí àgọ́ ọlọ́pàá náà, lé àwọn ọlọ́pàá jáde kí wọ́n tó dáná sun àgọ́ ọlọ́pàá náà.
Ìròyìn ní àwọn ọ̀dọ́ náà kò dáwọ́ ìfẹ̀hónúhàn wọn dúró títí di ọjọ́ Àìkú, tí Kọmíṣánnà ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ondo, Wilfred Afolabi sì lọ ṣàbẹ̀wò sí ìlú náà.
Agbẹnusọ ọlọ́pàá Ondo, Funmilayo Odunlaminínú àtẹ̀jáde kan tó fi léde ṣàlàyé pé ìdílé méjì kan ní òpópónà Ogbomo ní ìlú Ifon ló ń ba ara wọn fa wàhálà.
Odunlami ní wàhálà náà di ìjà ìgboro èyí tó mú kí àwọn ọlọ́pàá láti àgọ́ ọlọ́pàá fi lọ síbẹ̀.
Ó ní àwọn ọlọ́pàá náwọ́ gán àwọn afurasí kan tí wọ́n gbàgbọ́ pé wọ́n lọ́wọ́ nhínú ìjà náà, táwọn mìíràn sì fi ẹsẹ̀ fẹ nígbà tí àwọn ọlọ́pàá dé ibẹ̀.
Ó ṣàlàyé pé nígbà tó yá ni èèyàn kan tí wọ́n ń pè ní ọ̀gbẹ́ni Losilosi mú èèyàn kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Tobi Bobade, tí òun náà lọ́wọ́ nínú ìjà náà wá sí àgọ́ ọlọ́pàá.
"Ara Tobi kò le nígbà tí wọ́n fi máa gbé e dé àgọ́ ọlọ́pàá, táwọn ọlọ́pàá sì gbe lọ sí ilé ìwòsàn ní kíákíá fún ìtọ́jú.
"Lásìkò tó ń gba ìtọ́jú lọ́wọ́ ni àwọn ilé ìwòsàn kéde pé ó ti jáde láyé."
Odunlami ní àwọn ti gbé òkú rẹ̀ lọ sí ilé ìwòsàn Federal Medical Centre ti ìlú Owo fún àyẹ̀wò láti le fìdí ohun tó ṣokùnfà ikú rẹ̀ múlẹ̀.
Ó ní ṣàdédé ní àwọn ọlọ́pàá tó wà lẹ́nu iṣẹ́ dédé rí àwọn ọ̀dọ́, tí bàbá olóògbé ṣaájú wọn, tí wọ́n ṣe ìkọlù sí àgọ́ ọlọ́pàá, jó àgọ́ ọlọ́pàá náà àtàwọn ọkọ̀ méjì tó wà nínú ọgbà àgọ́ ọlọ́pàá náà.
Agbẹnusọ ọlọ́pàá náà sọ pé kò sí ẹnikẹ́ni tó bá ìṣẹ̀lẹ̀ iná náà lọ nítorí àwọn ọlọ́pàá tó wà lẹ́nu iṣẹ́ tètè pè fún àtìlẹyìn àwọn ọlọ́pàá mìíràn láti tètè dá ààbò bo agbègbè náà.
Ó ní Kọmíṣánnà ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ondo ti wá ṣèkìlọ̀ pé àwọn kò ní fàyè gba ìwà kò tọ́ ní ìpínlẹ̀ náà àti pé gbogbo àwọn tó bá lọ́wọ́ nínú ìwà bẹ́ẹ̀ yóò fojú winá òfin.
Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá wá pàrọwà sáwọn èèyàn ìlú náà, àtàwọn tí inú ń bí láti gba àláfíà láàyè.
Bákan náà ló ní kí àwọn èèyàn yé ṣe ìdájọ́ lọ́wọ́ ara wọn àti pé ìwádìí ti bẹ̀rẹ̀ àti pé àwọn yóò máa fi ọ̀rọ̀ náà tó àwọn ará ìlú létí bí ó bá ṣe ń lọ.















