Ẹkún sọ níbi ètò ìsìnkú Jimoh Olatunji táwọn ọlọ́pàá ló pokùn so látìmọ́lé n'Ilorin

Wọn ti sin oku Jimọh Ọlatunji Abdulkadir lọjọ Satide ọjọ kejidinlọgbọn oṣu kejila ọdun yìí ẹni to tawọn ọlọpaa lo ku si ahamọ awọn ọlọ́pàá ni Ilọrin.
Eto isinku oloogbe náà lo waye ni itẹ oku awọn musulumi to wa ni agbegbe Irewọlede ni ilu Ilọrin.
Lasiko isinku ọhun lariwo ẹkun tun sọ pẹlu bi awọn ọrẹ rẹ, mọlẹbi ati awọn abanikẹdun se n sun ẹkun asungba, bẹẹ ni wọn beere fun idajọ ododo.
Ninu ọrọ rẹ lasiko to n ba BBC Yoruba sọrọ, ẹgbọn oloogbe naa Ọgbẹni Jimọh Isimali Olarenwaju salaye pe ana ọjọ Ẹti ni wọn lọ seto ayẹwo oku oloogbe naa pẹlu awọn ọlọ́pàá ni ile iwosan nla ẹkọsẹ iṣegun fasiti UITH Ilọrin.
Ọgbẹni Olarenwaju ni idajọ ododo lawọn n reti lọdọ ijọba lori iṣẹlẹ naa.
Bi iṣẹlẹ naa ṣe waye
Lasiko to n ba BBC Yoruba sọrọ, iya oloogbe naa, Morike Olatunji ṣalaye pe inu ile ni ọmọ oun wa lasiko ti ọkan lara awọn ti wọn jọ n ṣiṣẹ papọ ti orukọ rẹ n jẹ Jelili pe e lati pade ohun ni opopona Balogun Fulani niluu Ilorin.
O ni bo ṣe de ibẹ lo ba awọn ọlọọpa meji ti wọn si gbe Olatunji sori ọkada lọ si olu ọọfisi wọn niluu Ilorin.
Iya Olatunji salaye pe oun lọ si agọ ọlọọpa lati gba ọmọ oun silẹ ṣugbọn awọn ọlọọpa kọ jalẹ, wọn ni ọga rẹ toun ba ṣiṣẹ ti orukọ rẹ n jẹ Gabriel lo jẹ lowo tawọn fi mu.
Ẹgbọn oloogbe to ba wa sọrọ, Ismail Olarewaju ni nnkan bii aagọ mẹwaa alẹ lawọn ọlọpaa pe awọn lati wa gba beli rẹ tawọn si sọ fun wọn pe ki wọn jẹ ki ilẹ mọ.
Ṣugbọn ni gba tawọn de agọ ọlọpaa lọjọ keji ọlọpaa ni Ọlatunji ti ku.
Ismail ni awọn bi ọlọpaa leere ohun to pa ọmọ wọn, wọn ni ṣe ni o pokunso.
O fi kun pe awọn ri ẹjẹ nilẹ.
Nigba ti wọn yoo fi de ile igbokupamọ si, wọn tun ri ẹjẹ ni imu oloogbe ọhun, gẹgẹ bii bii ohun to sọ.
Ọga agba ọlọpaa lorilẹede Naijiria ti da si ọrọ naa pẹlu ileri iwadi to rinlẹ

Oríṣun àwòrán, Nigeria Police Force
Ninu atẹdaje kan, alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Kwara, ASP Adeyẹmi Ejirẹ sọ pe iwadii ti bẹrẹ lori iku ọdọkunrin naa.
Ẹwẹ, ọgba ileeṣẹ ọlọpaa Naijiria, IGP Kayode Adeolu Egbetokun, ti ṣabẹwo si awọn obi oloogbe naa lọjọ Aiku.
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa Naijiria, ACP Olumuyiwa Adejobi lo fi ọrọ naa lede.
Adejobi sọ pe ileeṣe ọlọpaa ko ni gba ki awọn oṣiṣẹ rẹ maa ṣi agbara wọn lo, iwadii to peye ni yoo si tẹle iṣẹlẹ naa.
Ti ẹ ko ba gbagbe, nnkan bii oṣu meji ṣeyin ni awọn ọlọpaa lu ọdọkunrin kan pa nipinlẹ Kawara yii kan naa, ti awọn mọlẹbi rẹ ko si tii ri idajọ ododo gba titi di asiko yii.















