Èèyàn mẹ́tàlá jóná nínú ìjàmbá ọkọ̀ lọ́nà mọ́rosẹ̀ Owo sí Ikare ní ìpínlẹ̀ Ondo

Aworan oku awọn eeyan

Oríṣun àwòrán, FRSC

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Eniyan metala lo jẹ ipe Ẹlẹda ni owurọ oni ọjọ Abamẹta tii ṣe ọjọ kejidinlọgbọn oṣu Kejiula ninu ijamba ọkọ to waye ni agbegbe Abule Panu ni opopona Marose Owo silu Ikare nipinlẹ Ondo.

Ajọ to n bojuto abo oju popo FRSC lo kede iṣẹlẹ yi ninu atejade ti wọn fi sọwọ si awọn oniroyin.

Ọga Agba Ajọ naa nipinlẹ Ondo, Ọgbẹni Samuel Ibitoye, ẹni to sọrọ yi di mimọ ninu atejade kan sọ pe iṣẹlẹ yi waye ni deedee aago mẹwaa owurọ lẹyin ti ọkọ akero meji kọlu ara wọn.

Ọga agba FRSC naa sọ di mimọ pe eniyan merinla lo wa ninu awọn ọkọ mejeeji, tí metala si jona lai da wọn mọ, ti wọn si doola ẹmi enikan eyi to wa lẹṣe kan aye, ẹsẹ kan ọrun.

Awọn osojumikoro to wa lagbegbe naa lasiko ijamba ọkọ yi salaye pe, taya ọkọ to n bọ lati ilu Ikare lo fọ eyi to mu ki ọkọ na kọju si ọkọ keji to n bọ lati agbegbe Ọwọ. Wọn salaye pe ina sọ lara ọkọ méjèèjì kete ti wọn fi ori sọ ara wọn.

Àwọn eniyan naa fikun ọrọ wọn pe kete ti iṣẹlẹ naa waye làwọn ikọ Ọlọpaa, FRSC ati panapana de oriko iṣẹlẹ naa lati doola ẹmi awọn eniyan to wa nibẹ.

Ọga agba Ajọ EFCC naa sọ pe wọn ti gbe ẹni to farapa lọ ile iwosan FMC ni ilu Ọwọ fun itọju ti o peye, ti wọn si ko ara awọn metala to doloogbe naa lọ si ibi igboku si ni ile iwosan kan naa.

O wa rọ awọn awakọ láti ma ṣe jẹjẹ loju popo ki wọn si ri daju pe gbogbo ẹya ara ọkọ wọn lo wa ni ipo ti o dara ki wọn to gunle irin ajo.

Ọga agba FRSC naa tun rọ awọn ero ọkọ lati maa ba awọn awakọ sọrọ ti wọn ba ti n se ohun ti ko tọna loju popo.