''Ìmọ̀ ẹ̀rọ fóònù ti gba iṣẹ́ aago tí mo máa ń tún ṣe lọ́wọ́ mi''

Oríṣun àwòrán, Ifiokabasi Ettang / BBC
- Author, Mansur Abubakar
- Role, BBC News, Kaduna
- Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5
Iṣe aago titunṣe ni Bala Muhammad n ṣe niluu Kaduna, ni Naijiria.
Ti ẹ ba wọ inu ṣọọbu rẹ, oniruru aago atijọ ati aago aye ode oni ni ẹ maa ba ninu ṣọọbu naa.
Ọkan lara awọn agbegbe ti ero maa n pọ si julọ niluu Kaduna ni ṣọọbu ọhun wa laarin awọn to n ta ohun elo ti wọn fi n kọ ile.
Ọpọ ero lo maa n wọ inu ṣọọbu ọkunrin naa lojumọ lati paarọ batiri tabi ṣe aago wọn, amọ eyii ti yipada bayii.
Ọkunrin naa ti orukọ inagijẹ rẹ n jẹ Baba Bala sọ fun BBC pe "Laye igba kan, mo maa n ṣe aago to bii ọgọrun lojumọ kan."
Amọ ni bayii, o ni ẹru n ba oun nitori pe gbogbo ẹbun titun aago ṣe ti oun jogun lọwọ baba oun yo di ohun igbagbe laipẹ.
Baba Bala sọ pe "Lawọn ọjọ mii, mi o n ki n ni onibara kankan."
Gẹgẹ bii ọrọ rẹ, eyii ko ṣẹyin bi awọn eeyan ṣe n lo ẹrọ ibaraẹnisọrọ wọn lati wo aago.
"Ẹrọ ibaraẹnisọrọ ati imọ ẹrọ ti gba iṣẹ kan ṣoṣo ti mo mọ lọwọ mi, eyii si n ba ọkan mi jẹ.
"Iṣẹ yii ni mo ṣe ti mo fi kọ ile mi ti mo si fi ran awọn ọmọ mi nile ẹkọ."
This is what I love doing, I consider myself a doctor for sick wristwatches"
Ọkunrin naa ṣalaye fun wa pe baba oun maa n rinrinajo kaakiri iwọ oorun Africa, lati Senegal titi de Sierra Leone lati lọ tun aago ṣe.
Lasiko igba kan, Ilu Abuja ni Baba Bala n gbe nibi to ti n tun aago awọn eeyan nla ṣe.
Gẹgẹ bii alaye rẹ, lara awọn olowo to n ba tun aago ṣe ni awọn oṣiṣẹ NNPC.
Lara awọn eeyan naa n lo aago Rolex ti iye ti wọn n ta aago naa to $10,000.
Baba Bala ni oun fẹran Rolex gan nitori aago ọhun rẹwa pupọ, oun si fẹran awọn aago ti wọn n ṣe ni Switzerland.
Ninu ṣọọbu rẹ awora nla baba rẹ ti wọn ya ṣaaju iku rẹ lọdun 1988 si wa ni ẹgbẹ ogiri.

Oríṣun àwòrán, Ifiokabasi Ettang / BBC
Baba to bi Baba Bala ti orukọ rẹ n jẹ Isah ni awọn onibara niluu Freetown ati Darkar ti wọn maa n pe e ti wọn ba ti ni ọpọlọpọ aago ti wọn fẹ ṣe.
Loorekoore lo maa n lọ siluu Ibadan lati lọ ṣe aago nibẹ.
Gẹgẹ bo ṣe sọ, ko si ẹni to mọ ibi ti baba rẹ ti kọ iṣẹ aago titunṣe naa amọ o ni lati jẹ asiko ijọba awọn oyinbo amunisin.
O ni "Baba mi jẹ ogbontarigi ninu ẹni to n tun aago ṣe, iṣẹ naa si gbe rinrinajo kaakiri ọpọ ilu.
"Igba ti mo wa ni kekere lo kọ mi ni iṣẹ naa, inu mi si dun pe mo tọ ipasẹ rẹ.
"Nigba ti ko ba si owo lọwọ awọn akẹgbẹ mi nile ẹkọ, owo ki n wọn mi nitori mo maa n ri owo nidi aago titunṣẹ.
"Nigba kan ti aago olukọ mi kọṣẹ ti o si mu lọ si oniruru ṣọọbu fun atunṣe lai si atunṣe, nigba ti o sọ fun mi, ọjọ keji ni mo tun aago rẹ mẹta to kọṣẹ ṣe.
Laye igba kan, aago wiwọ ṣe pataki ni Naijiria bii aṣọ ti eeyan n wọ sọrun.

Oríṣun àwòrán, Ifiokabasi Ettang / BBC
Agbegbe kan wa niluu Kaduna nibi ti ọpọ awọn to n tun aago ṣe maa n ga ṣọọbu si.
Baba Bala ni "Ibẹ ti dahoro bayii lẹyin ti wọn wo."
O ṣalaye pe pupọ ninu awọn ti wọn jọ n ṣe iṣẹ aago naa tẹlẹ lo ti dagba ti awọn kan ninu wọn si ti jade laye.
Ọkunrin mii to n ṣe aago sọ pe "O ti sun mi lati maa lọ si ṣọọbu lojojumọ lai ri iṣẹ kankan ṣe, ohun lo mu mi ki n dẹkun ṣọọbu lilọ lati ọdun 2019.

Oríṣun àwòrán, Ifiokabasi Ettang / BBC
"Mo ni ilẹ, awọn ọmọ mi si n ba mi da oko lori rẹ, bi mo ṣe n ri ounjẹ oojọ mi niyẹn.
"Mi o lero pe awọn eeyan le maa lo aago bii ti atijọ mọ."
Awọn ọdukunrin meji ti a tun ba sọrọ, Faisal Abdulkarim and Yusuf Yusha'u, ti wọn ko lo aago ri gba ọrọ Isah wọle nigba ti ọkan ninu wọn sọ pe "Mo le wo aago lori foonu mi nigba to ba wu mi nitori gbogbo igba ni foonu naa n wa lọwọ mi."
Wọn sọ pe awọn ko nilo aago ọwọ niwọn igba ti awọn ti ni foonu lọwọ.
A tun kan si Ọmọwe Umar Abdulmajid, to jẹ olukọ imọ ibaraẹnisọrọ ni fasiti Yusuf Maitama niluu Kano.
Umar ni nnkan ṣi le yipada nipa aago lilo.
O ni "Lootọ ni pe ọpọ eeyan ko lo awọn aago atijọ yẹn mọ amọ pẹlu awọn aago oni kọmputa ti wọn ṣẹṣẹ n lo bayii, iṣẹ wọn ṣi le pada sọji.
"Fun idi pataki pe aago igbalode le ṣe ju ki eeyan kan wo oju ọjọ lasan lọ n tumọ si pe ọpọ eeyan ni yoo fẹran lati ra a."
Lẹyin na lo rọ awọn to n tun aago ṣe lati lọ kọ imọ nipa aagọ to n lo imọ ẹrọ nitori ti wọn ko ba ba igba yii, ebi yoo pa wọn.















