'Ìbúgbàmù mìíràn tó wáyé ló ṣokùnfà ikú àwọn aráàlú mẹ́wàá kìí ṣe àdó olóró iléeṣẹ́ ológun'

Iléeṣẹ́ ológun ní Nàìjíríà ti dẹ̀bi àdó olóró tó ṣekúpa èèyàn mẹ́wàá ní ìpínlẹ̀ Sokoto ru àwọn ẹ̀rúnrún tó máa ń fọ́nká lẹ́yìn tí àdó olóró bá dáhùn tán.
Adarí ẹ̀ka ìròyìn iléeṣẹ́ ológun, Ọ̀gágun Edward Buba ló sọ èyí nígbà tó ń bá àwọn akọ̀ròyìn sọ̀rọ̀ lọ́jọ́ Ẹtì, ọjọ́ Kẹtàdínlọ́gbọ̀n, oṣù Kejìlá, ọdún 2024.
Buba, tó sọ̀rọ̀ yìí lẹ́yìn ọjọ́ méjì tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà wáyé, ṣàlàyé pé kìí ṣe pé wọ́n ju àdó olóró sáwọn ará ìlú náà taara àmọ́ tó jẹ́ àwọn èrúnrún àdó olóró tó ń ba afẹ́fẹ́ rìn ló lọ báwọn.
Èèyàn mẹ́wàá ló jáde láyé, táwọn mẹ́fà mìíràn sì farapa.
Gẹ́gẹ́ bí àlàyé Buba, ní ọjọ́ Kẹẹ̀dọ́gbọ̀n, oṣù Kejìlá ni ikọ̀ ọmọ ogun òfurufú àti torí ilẹ̀ tẹ̀ka FANSAN YAMMA dìjọ gbìmọ̀ pọ̀ láti fòpin sí ikọ̀ agbéṣùmọ̀mí Lakurawa ní agbègbè Gidan Bisa àti Gida Runtuwa nínú igbó Jirikon, ní ìjọba ìbílẹ̀ Silame tí wọ́n fara pamọ́ sí.
Ó ní lẹ́yìn tí àdó olóró bá dún gbàmù tán, ìbúgbàmù míì máa ń wáyé lẹ́yìn rẹ̀ tó máa ń fa àwọn èrúnrún sínú afẹ́fẹ́ èyí tó fa ikú èèyàn mẹ́wàá.
"Kìí ṣe àdó olóró tí wọ́n jù náà ló ṣe okùnfà ikú àwọn èèyàn náà bíkòṣe àwọn èrúnrún rẹ̀.
"Àwọn ikọ̀ agbèṣùmọ̀mí Lakurawa tí àdó olóró náà bà jóná mímọ̀."
Àdó olóró náà ṣe ohun tí a fẹ́
Iléeṣẹ́ ológun ní èròńgbà láti pa ikọ̀ agbèṣùmọ̀mí Lakurawa rẹ̀ ní ibùba tí wọ́n sá sí ni ó wa sí ìmúṣẹ pẹ̀lú ìkọlù tí àwọn ṣe náà.
Ó ní gbogbo àwọn ohun èlò táwọn agbéṣùmọ̀mí náà ń lò tí adó olóró náà ṣe ìkọlù sí ṣàfihàn pé èròńgbà àwọn wá sí ìmúṣẹ.
Ó fi kún ọ̀rọ̀ pé àwọn ohun èlò ìjà ogun táwọn agbéṣùmọ̀mí náà ń lò, tí àdó olóró iléeṣẹ́ ológun bá ló fa ìbúgbàmú kejì, èyí tó fọ́n káàkiri tó sì lọ ṣe ìkọlù sáwọn aráàlú.
Bákan náà ló ní ìwádìí ń lọ lọ́wọ́ láti fìdí rẹ̀ múlẹ̀ bóyá àwọn tí wọ́n pàdánù ẹ̀mí wọn náà àtàwọn tó farapa kìí ṣe agbódegbà fáwọn ikọ̀ agbéṣùmọ̀mí náà.
Buba ní àwọn aráàlú ti fìdí rẹ̀ múlẹ̀ fáwọn pé àwọn ikọ̀ Lakurawa ń gbé nínú ìlú àwọn àti pé wọ́n ń lo agbègbè náà láti fi ṣiṣẹ́ ibi wọn.
Ó sọ pé iléeṣẹ́ ológun yóò túnbọ̀ máa gbìyànjú láti ri dájú àwọn kò ṣe ìkọlù sí aráàlú nígbà tí àwọn bá ń dajú oro kọ àwọn agbéṣùmọ̀mí.
Ọ̀gágun Nàìjíríà ní kò sí àṣìṣe nínú ìkọlú tó wáyé ní Sokoto, aráàlú tó bá fara gbọta ṣe agbódegbà àwọn agbésùmọ̀mí Lakurawa ni

Oríṣun àwòrán, Ahmad Aliyu/x
Ọga agba ileeṣẹ ologun orilẹede Naijiria, Ọgagun agba Christopher Musa ti tẹnu mọ ọ pe ko si aṣiṣe ninu awọn ado oloro ti baluu ologun ju si ibuba awọn ẹgbẹ agbesumọmi Lakurawa ni ilu Sokoto lọjọru.
Baluu ogun kan ju ado oloro si ileto meji kan ni ijọba ibilẹ Silame ni ipinlẹ Sokoto, eyi to ṣe iku pa awọn eeyan ti ko din ni mẹwaa, ti ọpọ miran si tun ṣeṣe.
Ijọba ipinlẹ Sokoto ti sọ pe awọn eeyan mẹwaa ti ko mọwọ mẹsẹ ninu ọrọ ẹgbẹ agbesunmọmi naa ni wọn ṣekupa lasiko ikọlu ọhun.
Amọṣa lasiko abẹwo rẹ si ẹkun iwọ oorun ariwa orilẹede Naijiria naa ni ọjọ keji ti iṣẹlẹ naa ṣẹlẹ, ọgagun agba ileeṣẹ ọmọogun Naijiria ṣalaye fun awọn akọroyin ni bareke awọn ologun Giginiya Cantonment ni ilu Sokoto pe awọn ọdaran lawọn ti wọn pa.
- Àwọn wo ló wà nídìí ikọ̀ agbébọn Lakurawa tó ń ṣọṣẹ́ ní ìpínlẹ̀ Sokoto?
- Wo ìgbà márùn-ún táwọn ẹ̀ṣọ́ aláàbò pàdé ikú lọ́wọ́ aráàlú ní Naijiria
- “Èèyàn 34 ló kú nínú ẹbí mi nígbà tí àdó olóró ọmọ ogun Naijria balẹ̀ sí abúlé wa”
- Ikọ̀ agbébọn ẹlẹ́sìn Islam kọlu ibùdó ológun àti ọkọ̀ ojú omi ní Mali, èèyàn 49 kú
Amọ o ni iwadii yoo ṣi waye lati mọ hulẹhulẹ ohun to ṣẹlẹ gangan.
"A ṣi ni awọn eeyan kan to ṣi n ṣe agbodegba fun awọn wọnyii, bi o ba si ti ṣe eyi iwọ naa ti sọ ara rẹ di ọdaran ti a le dojukọ niyẹn. Arọwa wa si ni pe ki awọn eeyan wa dẹkun lati maa gba awọn eeyan wọnyii laaye ni ayika wọn."
Ọgagun Agba Musa ni awọn gbe gbogbo igbesẹ lati rii daju pe ko si aṣiṣe rara. O ni bi awọn aṣiṣe miran ba wa waye o, awọn yoo ṣe iwadii to kuna lori rẹ.
"Ninu ohun ti a ri, awọn ọdaran wa nibẹ. Ẹnikẹni to ba ba wọn ṣe pọ a jẹ wi pe ara wọn loun naa."
Ọgagun agba ileeṣẹ ọmọogun Naijiria naa tun ṣalaye pe bi o ti wu ki awuyewuye naa o pọ to, ileeṣẹ ologun yoo ṣi tẹsiwaju lati maa da ina ya awọn ọdaran gbogbo, ṣugbọn gbogbo ọgbọn ni wọn yoo maa da lati ri i pe awọn araalu ti ọwọ wọn mọ ko ku si ipo ika.
Lójú mi ni ìyá àti bàbá mi àtàwọn àbúrò mi mẹ́ta ti jóná lẹ́yìn tí 'bàlúù ọmọogun Nàìjíríà' ju àdó olóró sí ìletò wa

Oríṣun àwòrán, AP
Ni aisun ọdun Keresimesi lọjọ Iṣẹgun ọjọ kẹrinlelogun oṣu Kejila, ni ẹkun sọ nipinlẹ Sokoto lẹyin ti ado oloro lati ara baalu ijagun dana sun iya, baba ati ọmọ mẹta ni abule meji nipinlẹ Sokoto.
Ọdọbinrin kan Hauwa'u to fidi ọrọ yii mulẹ ṣalaye pe loju oun bayii ni ado oloro naa ti dana sun awọn obi ati aburo oun mẹta.
Iroyin tun fidi rẹ mulẹ eeyan mẹwaa ni ado oloro lati ara baalu ijagun ṣeku pa nigba tawọn mẹfa mii farapa ni abule Ramtuwa ati Gidan Sam ni ijọba ibilẹ Silame nipinlẹ Sokoto.
Loju mi lawọn obi atawọn aburo mi ti jona
Hauwa'u, ti ọpọ eeyan n rọ wi pe ko rọra ṣe, sọ fun BBC pe oun ri ẹbi oun ti wọn n jona.
Ọkunrin kan Malam Muhammad to ba BBC Pidgin sọrọ ṣalaye pe laarọ ni nnkan bi ago meje ni iṣẹlẹ ọhun tawọn ọmogun si wọ abule meji ọhun.

Oríṣun àwòrán, Facebook/ Nigerian Airforce
Muhammad to n gbe lẹgbẹ awọn abule meji yii ṣalaye pe ''laarọ kutu lawọn sọja yi awọn abule meji yi ka.
Ko pẹ ko jina si asiko yii ni ọkọ ofurufu ijagun awọn ọmnogun mẹta bẹrẹ si ni yin ado oloro.''
Lẹyin ti wọn yin ado oloro lati ara baalu tan lawọn to wa layika abule mejeeji bẹrẹ si ni jade lati wo ohun to ṣẹlẹ gan an.
Amọ, wọn ni awọn sọja ko jẹ kawọn wọ inu abule meji naa.
Muhammad ṣalaye pe alaga ijọba ibilẹ Silame ati oloye kan nibẹ pada lọ wo ohun to ṣẹlẹ ni abule meji naa.
Olugbe agbegbe ti iṣẹlẹ ọhun ti waye mii, Usman Manuga sọ fun BBC pe lẹyin irun Asr ni iṣẹlẹ ọhun waye.
Aṣiṣe ni ado oloro to pawọn ara abule meji ni Sokoto – Ahmad Aliyu

Oríṣun àwòrán, Ahmad Aliyu/Facebook
Gomina Ahmad Aliyu ipinlẹ Sokoto to wa nibi eto isinku awọn ti ado oloro naa sẹku pa sọ pe awọn ọmogun lo ṣeeṣi ṣe ikọlu naa.
O ni ṣeni laanu pe iru iṣẹlẹ yii waye tori awọn ologun n gbiyanju lati daabo bo araalu ni.
Gomina Aliyu sọ pe ''gbogbo eeyan lo ti gbọ iroyin wi pe awọn ajijagbara alakakiti ẹsin kan ṣẹṣẹ wọ Naijiria, ati pe kii ṣe igba akọko niyi tawọn ọmogun yoo ṣe iru ikọlu bayii.
Wọn ti ṣe e bii igba mẹta ọtọtọ eleyii to si kẹsẹ jari lawọn akoko ti wọn ṣe e.
Ẹ jẹ ka gba wi pe ayanmọ ni nnkan to ṣẹlẹ yii, ati pe a ni lati gba ohunkohun to ṣẹlẹ gẹgẹ bii musulumi ko baa jẹ ibi abi ire.
Ijọba ipinlẹ Sokoto yoo ṣiṣẹ pọ pẹlu awọn ajọ tọrọ kan lati ṣe iwadii lori ohun to ṣẹlẹ ki a dena iru iṣẹlẹ bayii lọjọ iwaju.
''Awọn ọmogun ofurufu ati ọmogun ori ilẹ lo jọ ṣe ikọlu yii''
Abubakar Muhammad tọ jẹ alaga ijọba ibilẹ Silame sọ fun BBC pe awọn ọmogun ofurufu ati ti ori ilẹ lọ jọ ṣe ikọlu yii.
''Awọn ọmogun ofurufu lo kọkọ wọ agbegbe naa pẹlu awọn nnkan ija oloro.
Laarọ ọjọ Iṣẹgun ni wọn pe mi wi pe ado oloro ti bu gbamu, emi naa si ṣe iwadii lati ri pe o ṣẹlẹ ni toootọ.
Ọkọ ofurufu ijagun meji lo ju ado oloro silẹ sawọn abule meji yii,'' Muhammad ṣalaye.
Alaga ijọba ibilẹ Silame ni agbegbe Gidan Bisa ati Runtuwa ni ẹkun oun.
Awọn abule meji yii sun mọ igbo Surame ti wọn gbagbọ pe nibẹ ni ikọ agbesumọmi Lakurawa to ṣẹṣe wọ Naijiria fi ṣe ibuba.
Ileeṣẹ ọmogun Naijiria sọrọ lori iṣẹlẹ naa
Agbẹnusọ fun ikọ Fansan Yamma, Lt, Col Abubakar Abdullahi, ko le fidi rẹ mulẹ bo ya loootọ baalu ijagun ọmogun Naijiria ṣeeṣi ṣe ikọlu sawọn abule meji naa.
Ọgagun Abdullahi sọ pe o ṣee ṣe ko jẹ ikọ Lakurawa atawọn ikọ agbesunmọmi mii lo fẹ lo iroyin ofege lati bu ẹnu ẹtẹ lu iṣẹ takun takun tawọn ọmogun n ṣe nipa kikọ oju ija si awọn janduku agbebọn atawọn agbesunmọmi.
Abdullahi ni ileeṣẹ ologun ti sọrọ lori iroyin kan to jade laipẹ yii pe baalu ọmogun Naijiria yin ado oloro sawọn ile kan ni ijọba ibilẹ Silame nipinlẹ Sokoto.
O fikun ọrọ rẹ pe ileeṣẹ ologun maa n ṣe iwadii daadaa ki wọn to le ṣe ikọlu si ibikan tabi omiran.
Ọgagun Abdullahi wa rọ awọn araalu lati kọ eti ikun si iroyin ofege ki wọn ma ba da ibẹru bojo silẹ fawọn eeyan.
O ni awọn ibi ti wọn ṣe ikọlu si ni Gidan Sama ati Rumtuwa jẹ ibi tawọn eeyan ti mọ pe ikọ Lakurawa fi n ṣe ibuba.















