Iléẹjọ́ ju Olorí tẹ́lẹ̀, Naomi ati Oriyomi Hamzat sọ́gbá ẹ̀wọ̀n

Oríṣun àwòrán, Screenshot
Onidajọ Olabisi Ogunkanmi ti ile-ẹjọ Majisireeti to wa ni Iyaganku nilu Ibadan, ipinlẹ Oyo ti paṣẹ pe ki wọn fi Olori Ọọni Ile-Ifẹ tẹlẹ, Naomi Silekunola, Oriyomi Hamzat to jẹ alakoso agba fun ileeṣẹ redio kan nilu Ibadan pamọ si atimọle lọgba ẹwọn.
Adajọ naa tun sọ pe ki ọga agba nileẹkọ girama ti Islamic High School to wa lagbegbe Bashorun, Ibadan naa tẹle wọn lọ.
Ọgba ẹwọn Agodi to wa nipinlẹ Ọyọ ni adajọ naa sọ pe ki awọn afurasi naa ti lọ maa gbatẹgun titi di igba ti wọn yoo fi tun gbọ ẹjọ wọn.
- Ààrẹ Tinubu sọ̀rọ̀ lórí ikú àwọn ọmọdé tó wáyé níbi ayẹyẹ Naomi nìlùú Ibadan
- Ààfin Ooni sọ̀rọ̀ lórí àpèjẹ Olori Naomi níbi tí ọ̀pọ̀ ọmọdé ti kú n'Ibadan
- 'N5,000 tí wọ́n ṣèlérí ni mo fẹ́ lọ gbà níbi àpèjẹ tí wọ́n ti tẹ ọmọ mi mọ́lẹ̀'
- Iléèṣẹ́ ọlọ́pàá sọ pàtó iye ọmọ tó kú níbi àpèjẹ́ Naomi Ogunwusi n'Ibadan
Awọn mẹta wọnyi la gbọ pe wọn lọwọ si ajalu itẹra-ẹni-pa to waye niluu Ibadan laipẹ yii, nibi tawọn ọmọde ti ko din ni marundinlogoji ti pade iku ojiji.
Bi ẹ ko ba gbagbe, Olori Naomi lo ṣagbekalẹ eto pinpin ounjẹ ọdun fawọn ọmọde ti ko din ni ẹgbẹrun marun-un niluu Ibadan, pẹlu erongba lati ṣọdun Keresimesi fun wọn.
Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, ẹsun mẹrin ileeṣẹ ọlọpaa ni wọn fi kan awọn afurasi naa nile ẹjọ, leyi ti wọn lo tako iwe ofin ọdaran ipinlẹ tọdun 2000 ni abala 324.
Agbefọba to tako awọn mẹtẹẹta niwaju ile-ẹjọ sọ pe awọn eeyan naa lo ṣagbatẹru eto to mu ọpọ ẹmi awọn ọmọde lọ.
Onidajọ Ogunkanmi ti wa sọ pe ki awọn mẹtẹẹta naa wa lọgba ẹwọn titi ti wọn yoo fi ri amọran gba lati ọdọ ajọ Director of Public Prosecutions.
Ki la wọn nnkan to ti ṣẹlẹ sẹyin?
O kere tan, ọmọde marunlelọgbọn lo ku, ti ọpọ si farapa, nibi apejẹ ti olori Ooni Ile-Ife tẹlẹ, Naomi Ogunwusi, ṣe niluu Ibadan.
Ọjọru, ọjọ kejidinlogun, oṣu Kejila, ọdun 2024, ni eto naa yẹ ko waye, amọ gbogbo rẹ foriṣanpọn nitori ohun to ṣẹlẹ
Awọn ti iṣẹlẹ naa ṣoju wọn sọ fun BBC Yoruba pe ko tii pẹ ti eto bẹrẹ, ti awọn eeyan fi bẹrẹ si ni tẹ ara wọn.
Igba akọkọ kọ ree ti Olori Naomi Silekunola Ogunwusi ṣe eto apejẹ naa.
Ọdọọdun lo maa n ṣe e labẹ ajọ ẹlẹyinju aanu rẹ to pe ni, Women in Need of Guidance and Support (WINGS).
Awọn ti ọmọ wọn farapa ba BBC sọrọ
Ọkan lara obi awọn ọmọ ti ori ko yọ lọwọ iku ojiji nibi apejẹ ti Olori Ooni Ile-Ife tẹlẹ, Naomi Ogunwusi ṣe niluu Ibadan, ti ṣe alaye bi ọgọọrọ ero ṣe tẹ awọn ọmọ rẹ meji mọlẹ lasiko ijijadu fun ẹbun ọdun.
Ninu ọrọ ti o ba awọn oniroyin sọ, Arabinrin naa ṣe alaye wi pe ori redio ni awọn ti gbọ ikede wi pe Olori Ooni Ile-Ife tẹlẹri, Naomi fẹ pin ẹgbẹrun Naira fun awọn eeyan lati ṣe ami ayẹyẹ opin ọdun.
Ilepa ati gba ẹbun ọdun lo si mu ki o ko awọn ọmọ tiẹ naa lọ si ibi eto naa.
Ọkan ninu awọn ọmọ mejeeji naa ti pada sile lẹyin ti o gba itọju nile iwosan, ṣugbọn ikeji ṣi wa ni ibi ti wọn ti n tọju rẹ ni ọkan lara awọn ile iwosan ijọba ipinlẹ Ọyọ.
Ẹlomii ti o ko awọn ọmọ rẹ mẹtẹẹta lọ si ibi eto naa ni lati Olodo lẹ Baṣọrun sọ ohun ti oju rẹ ri lasiko ti igbakeji Gomina ipinlẹ Ọyọ, Adebayo Lawal ṣe abẹwo si ọkan lara awọn ile iwosan ti wọn ko awọn eeyan to fi ara pa nibi iṣẹlẹ naa lọ.
O ni ori redio naa ni ohun ti gbọ wi pe ounjẹ ọfẹ ati ẹbun ọdun wa fun awọn ọmọ kekeeke, eyii lo mu ki oun naa tara ṣaṣa lọ si ibi eto naa.
Awọn ọmọ mẹtẹẹta ti o ko lọ naa ni wọn tẹ mọlẹ lasiko ti awọn eeyan n kọlu ara wọn ni ibi ti wọn ti fẹ gba ẹbun ọdun, ṣugbọn a ko le sọ boya awọn mẹtẹẹta naa ni o ṣi wa laye, nitori pe ọmọ kan ṣoṣo ni a ri pẹlu Arabinrin naa lasiko ti o ba igbakeji Gomina ipinlẹ Ọyọ sọrọ.
Ileeṣẹ ọlọpaa mu Naomi Silekunola ati awọn eeyan mi
Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Oyo ti sọ pe ọmọde marunlelọgbọn lo ku nibi iṣẹlẹ ikọluraẹni to waye lasiko ti apejẹ opin ọdun ti olori Ooni Ile-Ife nigba kan, Naomi Ogunwusi, ṣe niluu Ibadan.
Bakan naa ni ọmọde mẹfa ṣi wa nileewosan nitori wọn farapa kọja aala.
Ninu atẹjade kan ti agbẹnusọ fun ileeṣẹ ọlọpaa, Osifeso Adewale fi sita ni ọsan Ọjọbọ, o ni awọn tun ti mu ẹni to ṣonigbọwọ eto naa, Wooli Naomi Silekunola.
Lara awọn ti agbẹnusọ ọlọpaa sọ pe awọn ti mu ni Fasasi Abdulahi (Ọga agba ile-ẹkọ Islamic High School, Ibadan), Genesis Christopher, Tanimowo Moruf, Anisolaja Olabode, Idowu Ibrahim, ati Abiola Oluwatimilehin.
SP Osifeso sọ pe awọn ti gbe iwadii lori iṣẹlẹ naa le ẹka ileeṣẹ ọlọpaa to n mojuto iwa ọdaran lọwọ fun iwadii to yẹ.















