Wo àdínkù tó ṣẹ̀ṣẹ̀ bá iye tí NNPC àti MRS ń ta epo bẹntiróòlù, ìdí táwọn ilé epo míì kò fi dinwó

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Adinku ti n ba iye tawọn ile epo n ta lita kan epo bẹntiroolu lẹyin ti ileeṣẹ epo rọbi Naijiria NNPC sọ lita kan epo bẹntiroolu ni ibudo igbepo di N899.
Bo tilẹ jẹ wi pe ọpọ ile epo ni ko tii mu adinku ba iye ti wọn n ta epo, aarẹ ẹgbẹ alagbata epo bẹntiroolu ni Naijiria, PETROAN, Billy Gillis-Harry ti sọ pe adinku yoo ba iye tawọn araalu n ra epo kaakiri Naijiria laarin ọsẹ kan.
Fun bii oṣu meloo bayii lawọn eeyan ti n ra lita kan epo bẹntiroolu ni bii N1,200 tabi ju bẹẹ lọ.
Ibi ti eeyan ba n gbe lo maa sọ iye ti yoo maa ra lita kan epo bẹtiroolu.
Lọjọ Aiku ni ẹgbẹ alagbata epo IPMAN kede wi pe awọn ọmọ ẹgbẹ awọn yoo beẹrẹ si ni epo bẹntiroolu ni N935 pẹlu adehun to wa laarin wọn pẹlu ileeṣẹ ifọporọbi Dangote.
Aarẹ ẹgbẹ IPMAN, Mafandi Garima, sọ pe adinku to ba iye ti Dangote n ta lita kan epo bẹntiroolu ni ibudo igbepo lo jẹ kawọn alagbata naa le maa ta a ni ẹdinwo fun araalu.
Ẹwẹ, awọn ile epo kan ti bẹrẹ si ni ta epo bẹntiroolu ni ẹdinwo fun araalu lẹyin ti Dangote kede adinku iye tawọn alagbata epo yoo maa gbe e ni ibudo igbepo.
Ni bayii, ile epo MRS ti bẹrẹ si ni ta lita kan epo bẹntiroolu ni N935 pẹlu adehun kan to wa laarin ile epo naa ati ileeṣẹ ifọporọbi Dangote.
Ọpọ awakọ lo ti bẹrẹ si ni ra lita kan epo bẹntiroolu ni N935 niluu Eko lawọn ile epo MRS.
Niluu Abuja, ile epo MRS ati NNPC ti n ta lita kan epo bẹntiroolu ni N965 bayii.
N1,060 lawọn ile epo yii ti n ta lita kan epo bẹntiroolu tẹlẹ ṣaaju akoko yii.
Idi tawọn ile epo mii ko ṣe ti maa ta bẹntiroolu ni ẹdinwo
Aarẹ ẹgbẹ PETROAN sọ pe tawọn alagbata ba ti n gbe epo sii lati ibudo igbepo Dangote ati NNPC ni adinku iye tawọn eeyan yoo maa ra epo yoo maa kari sii.
Ọgbẹni Gillis-Harry sọ lori ero Sunrise Daily ti ileeṣẹ tẹlifisan Channels pe awọn ọmọ ẹgbẹ awọn ti ko tii maa ta epo ni ẹdinwo ko tii gbe epo ni owo tuntun ti Dangote n ta a ni.
O ni ọpọ ninu wọn lo ra epo to wa lọwọ wọn ni N970, eyi to tumọ si pe wọn tun maa fi owo ọkọ gbe de awọn ile epo wọn.
Ọgbẹni Gillis-Harry ni idi niyii to fi pẹ diẹ ki gbogbo ọmọ ẹgbẹ awọn to maa le ta epo bẹntiroolu ni N935.
Ibeere ti ọpọ eeyan n beere bayii ni bo ya eyi yoo tun jẹ ki owo epo bẹntiroolu maa walẹ si bi ọdun 2024 ṣe n kogba wọle lọ.















