Ọmọ tó ń tọ́jú mi ni wọ́n dá ẹ̀mí rẹ̀ légbodò – Ìyá ọkùnrin tó kú s'àgọ́ ọlọ́pàá Ilorin

Alhaja Morenike Olatunji, to jẹ mama oloogbe, Abdukadir Olatunji Jimoh, to ku satimọle ọlọpaa niluu Ilorin ti sọ pe, oloogbe naa ni o n tọju oun ki wọn to da ẹmi rẹ logbodo.
Alhaja Morenike lo sọ eyi lasiko to n ba BBC Yoruba sọrọ nile rẹ to wa ni Balogun Fulani, niluu Ilorin.
Obinrin naa ni kii ṣe pe oloogbe naa nikan loun bi, ṣugbọn oun pẹlu rẹ lawọn mọ ọwọ ara awọn julọ, ti awọn si jọ maa n damọran.
Alhaja Morenike ni ilu Offa ni ọmọ oun ti n ṣisẹ ṣugbọn awọn ọmọ rẹ mejeeji wa lọdọ oun, ti ọmọ naa si maa n yọju sile ni gbogbo igba.
O fi kun-un pe baba rẹ wa lori akete aisan ti awọn n jọ tọju rẹ lọwọ, laimọ pe yoo fi baba naa saye lọ lojiji, lai saisan, lai rotẹlẹ.
Awọn obi oloogbe Abduquadir Olatunji ti wa ke gbajare si Aarẹ Bola Ahmed Tinubu lati kan-an nipa fun ileeṣẹ ọlọpaa ki wọn ṣe iwadii ati idajọ ododo lori iku to pa ọmọ awọn.
Iya oloogbe naa sọrọ pẹlu omije loju wi pe ki Ọlọrun ṣedajọ gbogbo awọn to lọwọ ninu iku ọdọkunrin naa.
O wa rawọ ẹbẹ si Aarẹ Bola Ahmed Tinubu, Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ti ipinlẹ Kwara ati gbogbo awọn alẹnulọrọ lawujọ ki wọn masṣe wo ẹbi oun niran.
O ni ki wọn dasi ọrọ yii, lati ṣewadii iku to pa ọmọ oun, ki wọn si ṣe idajọ ododo.
Gbogbo awọn ọdọ agbegbe naa lo peju si ibi ti ọfọ ti ṣẹ ọhun ti wọn si n fapa janu pe Awọn ko ni gba ṣugbọn awọn agba ile naa n fọwọ le wọn lejika.
Ẹwẹ, ọga agba ọlọpaa patapata nilẹ ni Naijiria, Kayọde Adeolu Egbetokun ti ṣabẹwo si iluu Ilorin lati ki mọlẹbi oloogbe ọhun.
Ọga ọlọpaa naa ni oun waa ba awọn mọlẹbi Ọlatunji kẹdun lori ohun to ṣẹlẹ.
O ti wa paṣẹ ki iwadii to lagbara bẹrẹ lori iku gende naa lẹṣẹ-kẹṣẹ.
Olatunji kú sí àhámọ́ ọlọ́pàá ní Kwara, wọ́n ní ṣe ló pokùnso

Ọdunkunrin kan, Jimoh Abdulkadir Olatunji ti ku si ahamọ ọlọpaa ipinlẹ Kwara.
Mọlẹbi ọdọkunrin oloogbe naa ti ke si gbogbo ọmọ Naijiria ati ileeṣẹ ọlọpaa fun idajọ ododo lori iku ọmọ wọn.
Ogunjọ, oṣu Kejila ọdun 2024 yii ni iṣẹlẹ naa waye.
Bi iṣẹlẹ naa ṣe waye
Lasiko to n ba BBC Yoruba sọrọ, iya oloogbe naa, Morike Olatunji ṣalaye pe inu ile ni ọmọ oun wa lasiko ti ọkan lara awọn ti wọn jọ n ṣiṣẹ papọ ti orukọ rẹ n jẹ Jelili pe e lati pade ohun ni opopona Balogun Fulani niluu Ilorin.
O ni bo ṣe de ibẹ lo ba awọn ọlọọpa meji ti wọn si gbe Olatunji sori ọkada lọ si olu ọọfisi wọn niluu Ilorin.
Iya Olatunji salaye pe oun lọ si agọ ọlọọpa lati gba ọmọ oun silẹ ṣugbọn awọn ọlọọpa kọ jalẹ, wọn ni ọga rẹ toun ba ṣiṣẹ ti orukọ rẹ n jẹ Gabriel lo jẹ lowo tawọn fi mu.
Ẹgbọn oloogbe to ba wa sọrọ, Ismail Olarewaju ni nnkan bii aagọ mẹwaa alẹ lawọn ọlọpaa pe awọn lati wa gba beli rẹ tawọn si sọ fun wọn pe ki wọn jẹ ki ilẹ mọ.
Ṣugbọn ni gba tawọn de agọ ọlọpaa lọjọ keji ọlọpaa ni Ọlatunji ti ku.
Ismail ni awọn bi ọlọpaa leere ohun to pa ọmọ wọn, wọn ni ṣe ni o pokunso.
O fi kun pe awọn ri ẹjẹ nilẹ.
Nigba ti wọn yoo fi de ile igbokupamọ si, wọn tun ri ẹjẹ ni imu oloogbe ọhun, gẹgẹ bii bii ohun to sọ.
Iwadii ti bẹrẹ

Oríṣun àwòrán, Olumuyiwa Adejobi
Ninu atẹdaje kan, alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Kwara, ASP Adeyẹmi Ejirẹ sọ pe iwadii ti bẹrẹ lori iku ọdọkunrin naa.
Ẹwẹ, ọgba ileeṣẹ ọlọpaa Naijiria, IGP Kayode Adeolu Egbetokun, ti ṣabẹwo si awọn obi oloogbe naa lọjọ Aiku.
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa Naijiria, ACP Olumuyiwa Adejobi lo fi ọrọ naa lede.
Adejobi sọ pe ileeṣe ọlọpaa ko ni gba ki awọn oṣiṣẹ rẹ maa ṣi agbara wọn lo, iwadii to peye ni yoo si tẹle iṣẹlẹ naa.
Ti ẹ ko ba gbagbe, nnkan bii oṣu meji ṣeyin ni awọn ọlọpaa lu ọdọkunrin kan pa nipinlẹ Kawara yii kan naa, ti awọn mọlẹbi rẹ ko si tii ri idajọ ododo gba titi di asiko yii.














