Obìnrin kan tí wọ́n dáná sun nínú rélùwéè jáde láyé

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ọwọ awọn agbofinro ti tẹ ọkunrin kan lori ẹsun wi pe o mọ nipa bi wọn ṣe dana sun obinrin kan laarin opopona reluwee to wa ni Booklyn, New York.
Ọga ọlọpaa New York, Jessica Tisch to fidi iroyin naa mulẹ lọjọ Aiku to kọja yii gẹgẹ bi "ọkan lara iwa ọdaran to burujai ti eeyan le hu lodi si ẹda ẹgbẹ rẹ".
Tisch sọ pe obinrin naa ni duro lati wọ reluwee ni Brooklyn ni, nigba ti ọkunrin kan sunmọ ọdọ rẹ, to si ṣa ina si aṣọ to wọ.
Oju ẹsẹ ni obinrin ọhun ku, nigba ti ina naa mu gbogbo ara rẹ, ti si ko si tete ri oluranlọwọ.
Tisch jẹ ko di mimọ pe ọwọ ọlọpaa ti tẹ afurasi ọhun lẹyin iṣẹ iwadii ti ikọ akẹkọọ ile ẹkọ girama kan ṣe, lasiko to n ri kọja nirọlẹ ọjọ naa.
Ọlọpaa sọ pe nnkan bi agogo meje abọ aarọ (12:30 GMT) ni obinrin ti wọn ko tii da mọ naa duro lẹgbẹ oju irin ti Coney Island-Stillwell Avenue ni Brooklyn, nigba ti ọkunrin naa lọ ba a.
Awọn ọlọpaa jẹ ko di mimọ pe bo tilẹ jẹ pe awọn ko le sọ boya obinrin naa n sun lọwọ ni, ṣugbọn ti wọn ni ko le mira nigba ti ọkunrin naa ju ina sii lara.
Wọn ni kii ṣe pe awọn mejeeji jọ sọrọ ko to di pe ọkunrin naa ju ina sii lara, ati pe ko jọ bi ẹni pe awọn mejeeji mọ ara wọn tẹlẹ, ṣaaju asiko iṣẹlẹ naa.
Niṣe ni wọn sọ pe ọkunrin naa na papa bora, bi awọn ọlọpaa ṣe sare lọ lati pa ina naa.
"Awọn ọlọpaa n ṣiṣẹ wọn lapa oke ileeṣẹ reluwee naa, ibẹ ni wọn wa ti wọn fi n gbọ oorun ati eefin to n jade, ko to di pe wọn lọ latri ṣe iwadii," Tisch sọ bẹẹ
"Ohun ti wọn ri ni ẹnikan to duro ninu ọkọ oju irin naa, ti eefin n jade lara rẹ."
Ileeṣẹ ọlọpaa ṣi n ṣiṣẹ lati mọ iru ẹni ti obinrin naa jẹ, ati ohun to fa ikọlu naa.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
"Lai mọ ohunkohun, awọn ọlọpaa to sare lọ sibẹ ko mọ pe ọkunrin naa wa nibi iṣẹlẹ ọhun, to jokoo lori aga ni ita reluwee naa," Tisch fi kun ọrọ rẹ.
Tisch tẹsiwaju pe wa pada ri ohun to ṣẹlẹ lẹkunrẹrẹ, wọn si wo ọkunrin naa ninu fọnran to wa ninu aṣọ awọn ọlọpaa to lọ sibẹ.
Loju ẹsẹ ni awọn ọlọpaa New York Police Department (NYPD) ti pin awọn aworan naa kaakiri sita.
Tisch sọ pe irọlẹ ọjọ naa ni awọn akẹkọọ ile ẹkọ girama pe awọn ọlọpaa lori aago 911, ti wọn si fi ọrọ ọkunrin naa to wọn leti.
Wọn pada ri ọkunrin naa nibi to jokoo si.
Agbegbe Herald Square ninu ileeṣẹ reluwee naa – nitosi Empire State Building to wa ni Manhattan lọwọ ti tẹ ẹ.
Bi wọn ṣe mu, ni wọn ti yẹ ara rẹ wo, ti wọn si ri iṣana igbalode to lo ninu apo rẹ.
Mo fẹẹ dupẹ lọwọ awọn ọdọmọde naa ti wọn pe 911 lati ṣe iranwọ," ọga ọlọpaa naa dupẹ.
"Wọn ri nnkankan, sọ nnkankan, bẹẹ ni wọn ṣe nnkankan."

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ọdun 2018 ni wọn sọ pe ọkunrin to wa lati Guatemala naa de si ilẹ Amẹrika, Joseph Gulotta ti NYPD lo sọ bẹẹ.
Gulotta ṣalaye pe awọn agbofinro ṣi n ṣe iwadii lati mọ boya obinrin naa n sun lọwọ lasiko iṣẹlẹ naa ni.
"Lotitọ lo wa nibẹ, ti ko si mira," Gulotta sọ bẹẹ.
"Boya o n sun lọwọ tabi ko sun, a ko le fidi rẹ mulẹ, ṣugbọn ohun ti a ṣakiyesi ni pe ko mira loju kan naa to wa.
"Ko si itakurọsọ kankan to ṣẹlẹ laarin awọn mejeeji rara."















