Àwọn nǹkan mánigbàgbé nípa Gbenga Adeboye Funwontan

Aworan Gbenga Adeboye

Oríṣun àwòrán, Others

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Kò sí àníàní, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni kò lé gbàgbé gbajúgbajà ádẹ́rìnposónu sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀ nnì, Gbẹnga Adeboye, nítori àwọn iṣẹ́ to ti gbése kí ó to gbà fún ikú lọgbọ̀n ọjọ oṣù kẹrin, ọdún 2003.

Ọpọ̀ èèyàn ló mọ Adeboye oríṣìíríṣíì bíi Fúnwọntán, Alhaji pastor Olúwo, Abẹfẹ, Jengbetiele, Itu baba ita, àti Alaye mi Gbengulo.

Ó ti lé lọ́dún mọ́kànlélógún báyìí tí ìlúmọ̀ọ́ká ádẹ́rìnposónu yìí ti jáde láyé báyìí.

Láti túbọ̀ ṣe ìràntí Gbẹnga Adeboye, a ṣe àkójọ àwọn nǹkan mánigbàgbé mẹ́wàá tó ti ṣe nile aye.

1. Gbenga Adeboye lo sọ awada di itẹwọgba kaakiri

Aworan Gbenga Adeboye ati Fathia Balogun

Oríṣun àwòrán, Itu Baba Ita

Gbenga Adeboye ti gbogbo ènìyàn mọ̀ sí Funwọntan, ni ó wà lára àwọn ẹni àkọ́kọ́ tó sọ àwàda kẹrikẹri dí itẹwọgba gbogbo ènìyàn, kí àwọn ènìyàn mii tó lájú síbẹ̀.

Títí di àsìkò yìí, kò tíì ṣí ẹni tí o le ti ẹsẹ̀ bọ bata Gbenga Adeboye láti àsìkò yii titi di igba tó lọ sinmi láyà Oluwa.

Lẹ́yin tó ṣe àìsàn tó niṣe pẹ̀lú kíndìrín ní Gbega Adeboye gba èkuru jẹ lọ́wọ́ ẹbọra jẹ lọ́dún 2003.

2. Gbenga Adeboye lo ni orukọ inagijẹ to pọju lẹnu isẹ

Nígbà tí a bí Gbenga Adeboye, Elijah Oluwagbemiga Adeboye ni wọn sọ ọ́, sùgbọ́n nígbà tí yóò fi kú, o níra láti le sọ iye orúkọ tó n jẹ́ lẹnu isẹ.

Ìdí ni pé nínú orín àti àwàdà tí o má n ṣe, ló ti jẹ́ oníruurú orúkọ bii Funwontan, Alhaji Pastor Oluwo, Jengbetiele, Itu baba Ita, Alaye mi Gbengulo àti àwọn orúkọ mííràn.

Gbenga Adeboye ni ẹbun pupọ ti ko se ka

Gbenga Adeboye jẹ ọkan ninu àwọn to ni ẹbun púpọ, ti o sì ni ìmọ̀ tó pọ̀ nínú iṣẹ̀ tọ yàn láàyò.

Kò sí ìgbà tó bá ń ṣe ohunkóhun ki àwọn ènìyàn má rín ẹ̀rin àrìn tàkìtì, sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀ ni, oludari ayẹyẹ lóde àríyá ni pẹlu, bakan naa lo tu maa n kọrin.

3. Oloju aanu ati Onididun ọlọrẹ ni Gbenga Adeboye

Aworan Gbenga Adeboye

Oríṣun àwòrán, Others

Nígbà ayé rẹ̀ àti lásìkò tó kú tan, gbogbo ènìyàn ló n jẹ̀rí si pé Gbenga Adeboye jẹ́ onínu dídùn ọlọ́rẹ ati ẹni ti kò máyé le rara.

Ọ̀kàn nínú ọ̀mọ̀ Funwọntan lo fi idi ọ̀rọ̀ yìí múlẹ̀ fún BBC lásíkò ìfọ̀rọ̀wérọ̀ pẹ̀lú rẹ̀.

"O yá bábá mi kí a mú gàrí ju kí ará ìta má ri ounjẹ jẹ lọ."

4. Amunimọna ni Gbenga Adeboye, paapaa awọn to sẹsẹ n didelẹ

Ọ̀pọ̀ ló má a n pè Gbenga Adeboye ni olùtọ́nisọ́nà fún àwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń dìde ni Alayé mi Gbengulo, bi ọ̀pọ̀ ṣe má a n pè é.

Ìròyìn fi ye ni pé, Gbenga Adeboye lo jẹ́ kí gbogbo ènìyàn mọ gbájúgbàjà òṣèré Fathia Balogun bii isana ẹlẹẹta nítorí pé ó ṣe àfihàn rẹ̀ nínú ijó orin rẹ̀ kan.

Àwọn ènìyàn bí Baba Gboin, Ereke ni Sọobu àti àwọn mííràn ló ti ara Adeboye dide pẹlu.

5. Ọjọru jẹ ọjọ ọ̀wọ̀ fun Gbenga Adeboye, kii fi sere rara

AWoran Gbenga Adeboye

Oríṣun àwòrán, Others

Gbenga Adeboye jẹ́ ẹni ti kìí fi Ọjọ́rú ṣere nígbà ayé rẹ̀, abúrò rẹ̀ kan lo fi ìdí ọ̀rọ̀ yìí múlẹ nínú àwo orin kan tó gbé jáde.

Ninu awo orin naa lo ti sọ ìtàn ayé Gbenga Adeboye kí ó tó di ìlúmọ̀ọ̀ká lásìkò náà, Ọmọ Majẹmu lo pe àkọle orin náà.

Ọjọ́rú jẹ́ ọjọ́ àrà ọ̀tọ̀ fún Gbenga Adeboye, gẹ́gẹ́ bí ó ṣe sọ, ọgbọ̀n ọjọ́, oṣù kẹsan ọdun 1959 ni wọ́n bíi

Ọjọ́rú ló bẹ̀rẹ̀ ilé ìwé, Ọjọ́rú bákan náà ló rin ìrìnàjò àkọ́kọ́ rẹ̀ lọ sí ilẹ̀ Amẹrika, Ọjọ́rú náà lo ṣe ètò Radio rẹ̀ àkọ́kọ́.

Ọjọ́rú, ọgbọ̀n ọjọ́, Oṣù kẹrin ọdún 2003 lo kú, wọ́n sì sí ni Ọjọ́rú, ọjọ́ kẹrinlà, oṣù karun ọdún 2003.

6. Gbenga Adeboye 'ri ọrun,' ko to ku

Wọ́n máá n ri Gbenga Adeboye gẹ́gẹ́ bí ẹni tó ti rí ọ̀run, kí ó tó kú.

idi ni pe o ti kọkọ ku nile iwosan, ti okiki si ti gba aye kan, ko to tun wa ji pada, ko si pẹ lẹyin igba naa, to tun jade laye pada.

Asiko perete to lo laye lẹyin iku rẹ akọkọ naa si lo gbe awo orin kan sita, ninu eyi to ti sọ bi ọrun se ri ati iriri ranpẹ to ni lajule ọrun nigba iku rẹ akọkọ.

Gẹ́gẹ́ bí ó ṣe sọ nínú àwo orin naa, o ni òun kú, òun si rí Ọlọ́rún, sùgbọ́n ó dá òun pada láti lọ pari iṣẹ́ tó ran òun láti gbé ilé ayé ṣe ni.

Bákan náà lo ni Ọlọrun sọ fún oun pé, tí òun bá kú, wọ́n gbọdọ sin òun pẹ̀lú Bíbelì àti ìwé orin.

Àwo orin rẹ̀ yìí si lo dá onirúrú awuyewuye sílẹ̀ láwujọ lásìkò náà.