Àwọn tó kú níbi tí wọ́n ti ń pín oúnjẹ ọ̀fẹ́ ní Anambra ti di 22

Stampede

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Anambra ti fidi rẹ mulẹ pe awọn to ku nibi itẹra-ẹni pa nibi ti wọn ti n pin ounjẹ ni ipinlẹ naa ti di mejilelogun.

Ọjọ Aiku oni, ọjọ kejilelogun, oṣu Kejila ni ileeṣẹ ọlọpaa fi iroyin naa sita.

Agbẹnusọ ọlọpaa, Tochukwu Ikenga, lo fidi iroyin ọhun mulẹ fawọn akọroyin, to si jẹ ko di mimọ pe bo tilẹ jẹ pe ọpọ eeyan lo farapa, sibẹ o ni iwadii ṣi n lọ lọwọ.

Stanpeed

Oríṣun àwòrán, FCT Police Com

Ninu ọrọ rẹ, "Ọga ọlọpaa Nnaghe Obono Itam ti ṣabẹwo si ile iwosan ti wọn ko awọn eeyan ti wọn tẹ pa ati awọn to farapa lọ lọjọ kọkanlelogun, oṣu Kejila, ọdun 2024 ni Okija, ijọba ibilẹ Ihiala, ti awọn to farapa si n gba itọju, to si ba ni lọkan jẹ wi pe eeyan mejilelogun padanu ẹmi wọn.

"Ọga ọlọpaa bawọn mọlẹbi ati ọrẹ awọn to padanu ẹmi wọn kẹdun, bẹẹ lo fẹ ki alaafia tete jẹ fawọn to farapa."

Ọjọ Abamẹta to kọja ni awọn eeyan bẹrẹ sii tẹ ara wọn pa ni papa iṣere Amaranta to wa ni Ojika, ijọba ibilẹ Ihiala, eyi ti ajọ Obijackson Foundation ṣagbekalẹ rẹ.

Iṣẹlẹ itẹra-ẹni pa to waye ni Anambra yii kii ṣe akọkọ ti yoo ṣẹlẹ lorileede Naijiria. Bo ṣe waye niluu Abuja, naa tun waye niluu Ibadan, ipinlẹ Oyo ninu oṣu Kejila yii.

Ṣaaju ki iṣẹlẹ ti Anambra yii too ṣẹlẹ, iṣẹlẹ iru rẹ ti ṣẹlẹ nile ijọsin aguda ti Holy Trinity to wa ni Maitama l'Abuja, nibi ti awọn mẹwaa ti ku.

Ọjọ diẹ sẹyin naa ni ti iṣẹlẹ ilu Ibadan waye, nibi ti awọn ọmọ marundinlogoji ti ku, ti awọn mẹfa si farapa yannayanna.

Iṣẹlẹ yii lo mu ki ọpọ ọmọ Naijiria, to fi mọ olusije sipo aarẹ labẹ asia ẹgbẹ oṣelu PDP ati Labour, Atiku Abubakar ati Peter Obi sọrọ jade, ti wọn si gba awọn eeyan lamọran nipa agbekalẹ iru eto fifun awọn araalu lounjẹ bawọnyi.

Wọn tẹ èèyàn mẹ́wàá pa níbi tí wọ́n ti ń pín oúnjẹ ọ̀fẹ́ l'Abuja

O kere tan, eeyan mẹwaa ti ọmọde wa lara wọn, lo ti jade laye nigba ti awọn mii farapa yanayana lẹyin ti wọn tẹ ara wọn pa nile ijọsin Holy Trinity Catholic Church, to wa lagbegbe Maitama, niluu Abuja.

Iṣẹlẹ naa waye lasiko ti ọgọrọ ero ya bo ile ijọsin ọhun lati ṣe alabapin ninu ounjẹ ọfẹ ti wọn n pin nibẹ.

Bakan naa ni iroyin to tun tẹ wa lọwọ lati Anambra sọ pe wọn tun tẹ awọn eeyan kan pa lagbegbe Okija.

A gbọ pe owurọ ọjọ Abamẹta ni iṣẹlẹ naa waye nibi kan ti wọn ti n pin irẹsi fun awọn eeyan.

Iṣẹlẹ mejeji yii lo n waye lẹyin ọjọ mẹta ti wọn tẹ ọmọ marundinlogoji pa niluu Ibadan nibi apejọ kan ti Olori Ooni atijọ, Naomi Ogunwusi ti fẹ ṣeto ounjẹ ati ẹkọ ọfẹ fun awọn ọmọde.

Iṣẹlẹ to waye l'Abuja

Gẹgẹ bii ohun ti a gbọ, nnkan bii aago mẹfa abọ aarọ oni ni iṣelẹ ti Abuja waye, eyii to mu ẹmi eeyan mẹwaa lọ.

Mẹrin ninu awọn to farapa ti kuro nile iwosan lẹyin ti wọn gba itọju tan, nigba ti awọn to ku ṣi wa nile iwosan.

Ileeṣẹ ọlọpaa FCT, to fidi iroyin naa mulẹ ti ba awọn mọlẹbi awọn to farapa atawọn to jade laye kẹdun

Ileeṣẹ ọhun sọ ninu atẹjade kan pe oun ti paṣẹ fun gbogbo ẹlẹgbẹjẹgbẹ, ile ijọsin tabi ajọ to ba fẹ ṣeto ti ọpọ ero yoo yọju si kọkọ fi eto naa ileeṣẹ ọlọpaa leti.

O ni eyii yoo ran awọn ọlọpaa lọwọ lati dẹkun irufẹ isẹlẹ bẹẹ, paapaa lasiko pọpọṣinṣin ọdun yii.

Aarẹ Tinubu ba awọn to ku kẹdun

Ẹwẹ, Aarẹ Bola Tinubu ti wọgile gbogbo awọn eto ati ode to yẹ ko yọju si niluu Eko lẹyin iroyin iṣẹlẹ naa.

Agbẹnusọ Aarẹ, Bayo Onanuga lo fi ọrọ naa lede ninu atẹjde kan.

Aarẹ ni inu oun bajẹ pe irufẹ nnkan bayii n waye lasiko ọdun to yẹ ki awọn araalu maa ṣajọyọ.

Lẹyin naa lo ba gbogbo awọn to fara gba ninu iṣẹlẹ naa kẹdun.