Ẹ wo bí ìgbẹ́jọ́ Dele Farotimi ṣe lọ ní Ado-Ekiti lónìí

Ile-ẹjọ Majisireeti to wa niluu Ado-Ekiti ti gba beeli ajafẹtọ ọmọniyan, to tun jẹ agbẹjro, Dele Farotimi, lori ẹsun ibanilorukọjẹ ti Aarẹ Afe Babalola, fi kan an.
Lara awọn ilana ti Onidajọ Abayomi Adeosun la kalẹ fun ominira Farotimi ni pe o gbọdọ san ọgbọn miliọnu Naira, oniduro meji to jẹ ọmọluabi.
Bakan naa ni adajọ sọ pe ko gbọdọ sẹ ifọrọwanilẹnuwo kankan, bẹbẹ lo si gbọdọ yọnda iwe irinna rẹ fun ile-ẹjọ.
Adajọ ti wa a sun igbẹjọ si ọjọ kẹtala, oṣu Keji, ọdun 2025.
Ki lo gbe Dele Farotimi de ile-ẹjọ?
Ohun ti a gbọ ni pe Afe Babalola kọ iwe ẹsun alawẹ mẹtalelọgbọn tako Farotimi, ninu eyii to ti fẹsun kan an pe o ba oun lorukọ jẹ ati pẹlu erongba lati da ipaya si ọkan araalu ati lati da ilu ru.
Lẹyin naa ni ọlọpaa mu Farotmi niluu Eko, ti wọn si gbe lọ si Ekiti lati le lọ koju ẹsun mẹrindinlogun ti wọn fi kan an.
Iwe ile ẹjọ ṣafihan pe aarin Farotimi ati kọmiṣọna ọlọpaa ipinlẹ Ekiti, Samson Osun, ni ẹjọ naa wa.
Ẹsun akọkọ ti wọn fi kan Farotimi ni pe o kọ iwe kan, 'Nigeria and its Criminal Justice System', ninu eyii to ti fẹsun kan Babalola pe oun lo ba eto idajọ Naijiria jẹ lọna ati gba idajọ to n fẹ fun awọn onibara rẹ.
Iwe ẹjọ naa sọ pe afurasi ọhun mọ pe irọ ni oun to wa ninu iwe to kọ amọ o mọọmọ gbe iwe ọhun jade.
Ẹsun mii ti wọn fi kan Farotimi ni pe o kọ ohun to le ba orukọ Afe Babalola jẹ ninu iwe rẹ ọhun.
Iwe ẹsun naa ni Farotimi tapa si abala ofin 373 iwa ọdaran Naijiria ti ijiya rẹ wa ni abala 375 iwe ofin kan naa.
Ẹwẹ, ṣaaju ni Farotimi ti kọkọ ba awọn akọroyin sọrọ, nibi to ti sọ pe awọn kan n wa oun kiri lati ji oun gbe, ati pe ti ẹnikẹni ba gbagbọ pe oun ṣẹ wọn, ki irufẹ ẹni bẹẹ gba ile ẹjọ lọ nitori araalu to n tẹle ofin ni oun.
Ki lo wa ninu iwe ti Farotimi kọ?

Oríṣun àwòrán, Dele Farotimi
Inu oṣu Kọkanla, ọdun 2024 ni Farotimi gbe iwe naa, 'Nigeria and its Criminal Justice System' jade.
Ninu iwe naa lo ti sọrọ nipa ọrọ ilẹ kan to wa lagbegbe Eti Osa, niluu Eko, eyii ti awọn oṣiṣẹ Afe Babala ṣe ẹjọ rẹ ti wọn si bori.
Iwe naa tun sọ nipa awọn ẹjọ kan ti Farotimi gbagbọ pe ẹka eto idajọ Naijiria ko ṣe daadaa.
Awọn ọrọ Farotimi lagbara – Amofin Ajayi
Amofin Owoseni Ajayi, olori agbẹjọro Amofin agba Afe Babalola nigba to n sọ ababọ wọn nilẹ ẹjọ, o ni ile-ẹjọ ti fun Dele Farotimi ni beeli, pẹlu awọn alaye ohun to gbọdọ ṣe, ati awọn ohun ti ko gbọdọ ṣe titi digba ti ẹjọ yoo fi pari.
O gbọdọ fi iwe irinna rẹ silẹ, ko wa awọn meji to ni ilẹ ni Ado-Ekiti, to si sun igbẹjọ siwaju fi ọjọ kẹtala, oṣu Keji, ọdun 2025
Ohun ti mo ṣakiyesi nile-ẹjọ lonii ni, ti mo si rii pe ko dara to, ni bi awọn ọrẹ ati alatilẹyin Dele Farotimi ṣe wa n pariwo nile ẹjọ. Ile-ẹjọ kii ṣe ibi ti wọn ti n pariwo.
"Kii ṣe iru ọrọ ti wọn n pariwo le lori lo ṣẹlẹ yii. Wọn fi ẹsun kan Dele Farotimi pe o sọ awọn ọrọ ti ko yẹ si gbogbo ileeṣẹ amofin, paapaa ile-ẹjọ agba wi pe wọn gba abẹtẹlẹ, wọn si darukọ gbogbo awọn agbẹjọro wi pe wọn gba abẹtẹlẹ.
"Lara awọn to fẹsun kan ni Afe Babalola, to sọ pe niṣe ni wọn n san owo ko to di pe wọn gbe ẹjọ fun wọn. Awọn ọrọ to sọ lagbara gidi gan-an, lo jẹ ko foju ba ile-ẹjọ.
"Agbẹjọro loun funra rẹ, o si yẹ ko mọ pe bi ile-ẹjọ ba rii wi pe o jẹbi, bo tilẹ jẹ pe ko tii jẹbi bayii, o ṣeeṣe ki iṣẹ agbẹjọro to bẹrẹ lọdun 1999 bọ lọwọ ẹ, nitori pe ẹni ti wọn ba ti ju sẹwọn ko tun le ṣiṣẹ agbẹjọro mọ."
Farotimi ko paayan, bẹẹ si ni ko fa idi ya – Agbẹjọro Kembi
Amofin Adejare Kembi, ọkan lara awọn agbẹjọro Dele Farotimi sọ pe ile ẹjọ naa da ẹjọ kekere, lori boya Dele lẹtọọ lati maa gba ile wa jẹjọ rẹ, ile ẹjọ si rii wi pe o lẹtọọ lotitọ, nitori pe ko paayan, ko si fa idi ya, bẹẹ si ni ko ṣe awọn ohun to la ẹmi lọ.
"Ile-ẹjọ sọ pe ko wa miliọnu lọna ọgbọn naira, oniduro meji to ni ilẹ niluu Ado-Ekiti, ko si gbọdọ kuro ni Naijiria titi ẹjọ yoo fi pari, bẹẹ si ni ko gbọdọ sọ ohunkohun yala ninu iwe iroyin tabi ifọrọwerọ lori ẹjọ naa nigba to ba jade."
Amofin Kembi sọ pe oun ko le igbesẹ to kan ti awọn yoo tun gbe lori ẹjọ naa, nitori pe o ṣeeṣe ki awọn sọrọ si ọwọ awọn alatako.
Afenifere ko gbe lẹyin ẹnikẹni - Faloye
Akọwe ipolongo ẹgbẹ Afenifere, Ọmọọbi Justice Faloye, nigba to n ba BBC sọrọ, o ni ọkan lara awọn ọmọ ẹgbẹ naa ni, to si lawọn ko sọ pe ki Afe Babalola ma lọ sile ẹjọ, bo tilẹ jẹ pe ọna ti wọn gba gbe e ko tọna.
Faloye ni o ti le logun ọdun ti Farotimi ti n ṣiṣẹ agbẹjọro, to si ni ti ẹjọ ba wa, niṣe lo yẹ ki wọn gbe ẹjọ lọ si kootu, dipo ki wọn maa fi ọwọ agbara gbe eeyan tipatipa.
"Inu wa dun lonii wi pe a ti gba beeli naa, bo tilẹ jẹ pe owo naa pọ, ṣugbọn a fẹ ki awọn mejeeji sọ asọyepọ gẹgẹ bi ọmọluabi.
"Afenifere ko gbe lẹyin ẹnikẹni ninu wọn, bi ko ṣe pe a duro gẹgẹ bi oniduro lati jọ sọ asọyepọ. Bi wọn ṣe gbe Farotimi nikan ni Afenifere lodi si."












