Mo fẹ́ kí Farotimi fìdí ẹ̀sùn tó fi kàn mí múlẹ̀ - Afe Babalola

Aworan Dele Farotimi

Oríṣun àwòrán, Dele Farotimi/Facebook

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Agbaọjẹ agbẹjọro to tun jẹ oludasilẹ Afe Babalola University, ABUAD, Oloye Afe Babalola ti sọ pe ti ajafẹtọọ Dele Farotimi ba le fidi ẹsun to fi kan oun múlẹ, yoo gb'ominira lọgba ẹwọn to wa.

Ni ibẹrẹ ọsẹ yii nile ẹjọ majisreeti kan ju Farotimi sẹwọn titi ti igbejọ rẹ yoo fi tẹsiwaju lori ẹsun ibanilorukọjẹ ti Oloye Babalola fi kan an.

Ṣaaju ni Farotimi fẹsun kan agbaọjẹ agbẹjọro naa ninu iwe ti o ṣẹṣẹ kọ jade pe o gbe iwa ibajẹ wọ eto idajọ orilẹede Naijiria.

Nigba ti o n ba awọn oniroyin sọrọ niluu Ado-Ekiti, Oloye Babalola, ẹni ti adari igbimọ olupẹjọ rẹ, Ọgbẹni Owoseni Ajayi ṣoju rẹ rọ awọn ọmọ Naijiria lati wa ododo ati ọtitọ ki wọn to maa gbe lẹyin Farotimi.

"Ṣe ko yẹ ki Afe Babalola ja fún òtítọ ati òdodo lori ẹsun ti Farotimi fi kan an ni?

Ṣe Farotimi nikan lo nilo idajọ otitọ ati ododo ni?

Ti Ọgbẹni Farotimi ba le fi idi rẹ mulẹ pe otitọ ni gbogbo awọn ẹsun to fi kan Oloye Babalola ninu iwe rẹ, yoo gba ominira lọgba ẹwọn to wa.

Titi di igba yẹn, ẹ jẹ ki ile ẹjọ yanju ọrọ naa," Ọgbẹni Owoseni lo sọ bẹẹ.

Ki lo wa ninu iwe ẹsun ti wọn fi kan Farotimi?

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ohun ti a gbọ ni pe Afe Babalola kọ iwe ẹsun alawẹ mẹtalelọgbọn tako Farotimi, ninu eyii to ti fẹsun kan an pe o ba oun lorukọ jẹ ati pẹlu erongba lati da ipaya si ọkan araalu ati lati da ilu ru.

Lẹyin naa ni ọlọpaa mu Farotmi niluu Eko, ti wọn si gbe lọ si Ekiti lati le lọ koju ẹsun mẹrindinlogun ti wọn fi kan an.

Iwe ile ẹjọ ṣafihan pe aarin Farotimi ati kọmiṣọna ọlọpaa ipinlẹ Ekiti, Samson Osun, ni ẹjọ naa wa.

Ẹsun akọkọ ti wọn fi kan Farotimi ni pe o kọ iwe kan, ‘Nigeria and its Criminal Justice System’, ninu eyii to ti fẹsun kan Babalola pe oun lo ba eto idajọ Naijiria jẹ lọna ati gba idajọ to n fẹ fun awọn onibara rẹ.

Iwe ẹjọ naa sọ pe afurasi ọhun mọ pe irọ ni oun to wa ninu iwe to kọ amọ o mọọmọ gbe iwe ọhun jade.

Ẹsun mii ti wọn fi kan Farotimi ni pe o kọ ohun to le ba orukọ Afe Babalola jẹ ninu iwe rẹ ọhun.

Iwe ẹsun naa ni Farotimi tapa si abala ofin 373 iwa ọdaran Naijiria ti ijiya rẹ wa ni abala 375 iwe ofin kan naa.

Ẹwẹ, ṣaaju ni Farotimi ti kọkọ ba awọn akọroyin sọrọ, nibi to ti sọ pe awọn kan n wa oun kiri lati ji oun gbe, ati pe ti ẹnikẹni ba gbagbọ pe oun ṣẹ wọn, ki irufẹ ẹni bẹẹ gba ile ẹjọ lọ nitori araalu to n tẹle ofin ni oun.

Ki lo wa ninu iwe ti Farotimi kọ?

Inu oṣu Kọkanla, ọdun 2024 ni Farotimi gbe iwe naa, 'Nigeria and its Criminal Justice System' jade.

Ninu iwe naa lo ti sọrọ nipa ọrọ ilẹ kan to wa lagbegbe Eti Osa, niluu Eko, eyii ti awọn oṣiṣẹ Afe Babala ṣe ẹjọ rẹ ti wọn si bori.

Iwe naa tun sọ nipa awọn ẹjọ kan ti Farotimi gbagbọ pe ẹka eto idajọ Naijiria ko ṣe daadaa.