Wo bí ètò ìsìnkú Sheikh Muyideen Ajani Bello ṣe lọ nílùú Ibadan

Aworan Shiekh Muyideen Ajani Bello

Oríṣun àwòrán, Babajide Sanwo-Olu/X

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Awaye ma ku kan o si, ọrun nikan ni are mabọ, ero ti lọ biba nirọlẹ ọjọ Ẹti nibi eto isinku ilumọọka alfa to tun jẹ olukọ ẹsin Islam, Sheikh Muyideen Ajani Bello, nile rẹ lagbegbe Akobo niluu Ibadan.

Owurọ ọjọ Ẹti ni iroyin gbe e jade pe Alhaji Muyideen Bello ti jade laye.

Lati aarọ ọjọ Ẹti yii naa ni ọpọ eeyan ti bẹrẹ si n ṣe idaro agbọjẹ onimọ nipa ẹsin Islam to dagbere faye naa.

Awọn eeyan jankan jankan lo peju pesẹ sibi eto isinku Sheikh Bello nirọlẹ ọjọ Ẹti ni ile rẹ niluu Ibadan.

Lara awọn alẹnulọrọ lawujọ to wa nibi eto isinku naa ni igbakeji gomina ipinlẹ Oyo, Amofin Adebayo Lawal.

Awọn alfa nla nla naa ko gbẹyin nibi eto isinku ọhun, lara wọn ni Imaamu Agba ilẹ Ibadan, Alhaji Abdul-Ganiu Agbọtọmọ Kekere.

Gbajugbaja alfa ati onimọ nipa ẹsin Islam, Alhaji Taofeeq Akeugba Gold ko gbẹyin nibi eto isinku ọhun.

''Bi ero ṣe pọ nibi eto isinku Sheikh Bello tumọ si bi Ọlọrun ṣe kẹ ẹ''

Nigba ti o n ba BBC Yoruba sọrọ nibi eto isinku naa, Alhaji Akeugbagold ni bo ṣe yẹ ki eto naa ri lo ṣe lọ.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

''Nitori ti eeyan nla ba lọ, ko si iru eeyan ti ko ni de ibi isinku rẹ.

Koda, bi ibi ti a wa yii ko ṣe gba ẹsẹ yii jẹ ara apọnle Ọlọrun lara baba.

Bi ibi bayii sẹ tobi tobi to, ẹ maa ri wi pe ko gba awọn eeyan, ero to peju pesẹ sibi kii ṣe keremi rara.

A dupẹ fun Ọlọrun fun igbesi aye baba wa Sheikh Bello oniwaasi agbaye.

Mo gbadura wi pe ki Ọlọrun ba wa ṣe forijin fun wọn,'' Akeugbagold lo sọ bẹẹ.

Akeugbagold fikun ọrọ rẹ pe ''to ba jẹ nitori owo ni Alhaji Muyideen Bello se n se waasi ni, oun ni awọn oloselu ko ba fẹran julọ ṣugbọn oun ṣe tiẹ bi Ọlọrun ṣe ran an ni.''

Ninu ọrọ tiẹ, ọkọ lara ẹbi oloogbe, Alhaji Akinkunle Abiodun, sọ fun BBC Yoruba wi pe Shiekh Bello jẹ olootọ eeyan ati ẹni to ko ẹbi mọra.

''Ati ọmọ ẹgbọn, ati ọmọ aburo to fi dori gbogbo awọn eeyan ti kii ṣe ẹbi baba ni wọn ko mọra.

Baba kii wo o bo ya ẹnikan maa fun wọn lowo tabi nnkan, bi ọrọ ba ṣe jẹ ni baba ṣe maa n sọ ọ.

Ohun kan pataki ti a o fi maa ranti baba ni waasi ododo eyi to ti n sọnu lọ diẹ diẹ bayii lawujọ.

Baba lo waasi lati bawọn to wa ni ipo alaṣẹ wi lai bẹru ẹnikan kan tabi bẹru ohun to le tibẹ jade.